Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 4
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 4
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 1-4
No. 1: 1 Kíróníkà 1:1-27
No. 2: Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà (1 Pét. 3:10-12)
No. 3: Àmúlùmálà Ìgbàgbọ́ Kì Í Ṣe Ọ̀nà Ọlọ́run (td 5A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Ìdí Tá A Fi Ń Ròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Wa. Akọ̀wé ìjọ ni kó sọ àsọyé yìí. A gbé e ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 88, ìpínrọ̀ 2, sí ojú ìwé 90, ìpínrọ̀ 1.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn, Ẹ Máa Kọ́ Wọn. (Mát. 28:19, 20) Ìjíròrò tá a gbé ka àpilẹ̀kọ náà, “Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-Èdè Bòlífíà,” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 2009, ojú ìwé 10 sí 11. Lẹ́yìn tó o bá jíròrò àpilẹ̀kọ náà, ní kí àwọn ará sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.