Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? A ṣì máa fún yín ní ìsọfúnni nípa bá a ṣe máa pín ìwé pẹlẹbẹ yìí kárí ayé. Kí ẹ lo àwọn ìwé pẹlẹbẹ yìí ní àfikún sí ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà: Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! àti Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí àwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà.
◼ Ọ̀sẹ̀ April 25, 2011 la máa sọ àkànṣe àsọyé tó wà fún sáà Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2011. A máa ṣe ìfilọ̀ àkòrí àsọyé náà tó bá yá. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé náà ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àsọyé yìí ṣáájú ọ̀sẹ̀ April 25.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ March 14, 2011, ìwé “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run la máa bẹ̀rẹ̀ sí í lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Kí àwọn ìjọ tí kò bá ní in lọ́wọ́ béèrè fún un nígbà tí wọ́n bá fẹ́ béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.