Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 10
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 10
Orin 50 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 16 ìpínrọ̀ 1 sí 6 (25 min)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 33-36 (10 min)
No. 1: 2 Kíróníkà 34:12-21 (ìṣẹ́jú 4 tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí La Lè Kọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Màríà, Ìyá Jésù? (5 min)
No. 3: Ìsapá Èèyàn Kọ́ Ló Máa Mú Ìjọba Ọlọ́run Wá—td 21D (5 min)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Máa Fi Ọ̀yàyà Sọ̀rọ̀ Nígbà Tó O Bá Ń Wàásù. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 118, ìpínrọ̀ 1, sí ojú ìwé 119, ìpínrọ̀ 5.
10 min: Ǹjẹ́ O Lè Ré Kọjá sí Makedóníà? (Ìṣe 16:9, 10) Ìjíròrò tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ April 15, 2009 ojú ìwé 20 sí 23. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìrírí kan, ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́ nínú ìrírí náà.
10 min: “Iṣẹ́ Tó Gbádùn Mọ́ni Jù Lọ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àkéde kan, ní kó sọ ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó ń rí bó ṣe ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sì ń tẹ̀ síwájú.
Orin 75 àti Àdúrà