Iṣẹ́ Tó Gbádùn Mọ́ni Jù Lọ
1. Iṣẹ́ ìwòsàn tẹ̀mí wo là ń ṣe lákòókò tá a wà yìí?
1 Ayọ̀ ńláǹlà kúnnú àwọn tó fojú ara wọn rí ìwòsàn nípa tara tó wáyé ní ọ̀rúndún kìíní. (Lúùkù 5:24-26) Lóde òní, inú wa ń dùn bá a ṣe ń mú àwọn èèyàn lára dá nípa tẹ̀mí. (Ìṣí. 22:1, 2, 17) Orí wa máa ń wú bá a ṣe ń ka ìrírí nípa bí Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà sí rere. Ohun míì tó tún ń fún wa láyọ̀ bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí ni dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú.
2. Àwọn nǹkan wo ló lè fún wa láyọ̀ bá a ṣe ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?
2 Kí ni orúkọ Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi fàyè gba ìjìyà? Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé? Bá a ṣe ń sọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn fún àwọn èèyàn máa ń fún wa láyọ̀, àmọ́ ohun tó máa ń jẹ́ kí ayọ̀ wa túbọ̀ kún ni bá a ṣe ń rí i tí ojú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń tàn yanran bí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Òwe 15:23; Lúùkù 24:32) Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo orúkọ Jèhófà, kó ṣàtúnṣe ìmúra àti ìrísí rẹ̀, kó jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò tọ́, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún àwọn ẹlòmíì. Bó bá tẹ̀ síwájú tó sì ṣèrìbọmi, á wá di alábàáṣiṣẹ́ àti arákùnrin tàbí arábìnrin wa. Ìdùnnú wa ló máa jẹ́ bí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí.—1 Tẹs. 2:19, 20.
3. Àwọn ìgbésẹ̀ tó wúlò wo la lè gbé tá a bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Ǹjẹ́ Ìwọ Náà Lè Lọ́wọ́ Nínú Rẹ̀? Tó o bá fẹ́ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni yìí, bẹ́ Jèhófà pé kó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lẹ́yìn náà kó o ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tó o bá gbà. (1 Jòh. 5:14) Máa wàásù níbi tó o bá ti lè rí àwọn èèyàn àti nígbà tó o bá lè rí wọn. Máa gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbàkigbà tí àyè rẹ̀ bá ṣí sílẹ̀. (Oníw. 11:6) Tó o bá pàdé ẹni tó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó o sì gbin irúgbìn òtítọ́ sínú rẹ̀, pa dà lọ láti lọ bomi rin ín.—1 Kọ́r. 3:6-9.
4. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fi ọ̀rọ̀ bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn falẹ̀?
4 Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ló ṣì wà tí ebi ń pa, tí òǹgbẹ òdodo sì ń gbẹ. Tá ló máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n ṣaláìní nípa tẹ̀mí fún wọn nípasẹ̀ kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (Mát. 5:3, 6) Ẹ jẹ́ ká yọ̀ǹda ara wa tinútinú ká lè parí iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn kí àkókò ìkórè tó kọjá lọ.—Aísá. 6:8.