Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 27, 2011. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ May 2 sí June 27, 2011, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.
1. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ohun tí Jèhófà sọ pé kí Jóòbù gbàdúrà fún àwọn tó ṣẹ Jóòbù? (Jóòbù 42:8) [w98 8/15 ojú ìwé 30, ìpínrọ̀ 5]
2. Kí ni “ẹbọ òdodo” tí àwọn Kristẹni ń rú lóde òní? (Sm. 4:5) [w06 5/15 ojú ìwé 18, ìpínrọ̀ 9]
3. Báwo ni kíndìnrín Dáfídì ṣe tọ́ ọ sọ́nà? (Sm. 16:7) [w04 12/1 ojú ìwé 14, ìpínrọ̀ 9]
4. Báwo ló ṣe jẹ́ pé “àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run”? (Sm. 19:1) [w04 10/1 ojú ìwé 10, ìpínrọ̀ 8]
5. Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 27:14 ṣe sọ, báwo ni ìrètí àti ìgboyà ṣe bára tan? [w06 10/1 ojú ìwé 26 sí 27, ìpínrọ̀ 3, 6]
6. Báwo lohun tó wà ní Sáàmù 37:21 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa? [w88 8/15 ojú ìwé 17, ìpínrọ̀ 8]
7. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára ọmọ Léfì kan tó wà ní ìgbèkùn tó bá dọ̀rọ̀ fífi ìmọrírì hàn? (Sm. 42:1-3) [w06 6/1 ojú ìwé 9, ìpínrọ̀ 3]
8. Kí ló lè jẹ́ ká dẹni tó nífẹ̀ẹ́ òdodo ká sì kórìíra ìwà burúkú? (Sm. 45:7) [cf orí 6, ìpínrọ̀ 8 sí 10]
9. “Ẹ̀mí ìmúratán” ta ni Dáfídì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ti òun lẹ́yìn? (Sm. 51:12) [w06 6/1 ojú ìwé 9, ìpínrọ̀ 10]
10. Báwo la ṣe lè dà bí igi ólífì nínú ilé Ọlọ́run? (Sm. 52:8) [w00 5/15 ojú ìwé 29, ìpínrọ̀ 6]