Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 9
Orin 123 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 19 ìpínrọ̀ 1 sí 5, àti àpótí tó wà ní ojú ìwé 149 àti 150 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 22-24 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 23:15-23 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Ìwàláàyè Nínú Ayé Tuntun Kò Fi Ní Súni (5 min.)
No. 3: Ìsapá Àwọn Èèyàn Kọ́ Ló Máa Mú Ìjọba Ọlọ́run Wá—td 21D (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
15 min: Ṣé O Ti Lo Àwọn Àbá Yìí? Ìjíròrò. Sọ àsọyé lórí àwọn àbá tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn àwọn àbá tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ wọ̀nyí: “Má Ṣe Fà Sẹ́yìn” (km 10/11), “Máa Fi Ọgbọ́n Darí Àwọn Ẹ̀ṣẹ́ Rẹ,” àti “Wàásù fún ‘Ènìyàn Gbogbo’” (km 1/12). Ní kí àwùjọ sọ bí wọ́n ṣe fi àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà sílò àti àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí.
15 min: “Ohun Mẹ́ta Tó Lè Mú Kó O Túbọ̀ Jẹ́ Olùkọ́ Tó Já Fáfá.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń jíròrò ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ lójú ìwé 3 nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, pẹ̀lú onílé. Lẹ́yìn tí akéde ti ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fà yọ nínú ìwé Jóòbù 10:15 tán, ó wá kó àlàyé oníṣẹ̀ẹ́jú kan sí méjì palẹ̀ nípa ẹni tí Jóòbù jẹ́. Lẹ́yìn èyí, ní kí àwùjọ sọ ìdí tí ọ̀nà tí akéde yìí fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kò fi bójú mu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ ni gbogbo àlàyé tó ṣe nípa Jóòbù.
Orin 10 àti Àdúrà