Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 28
Orin 133 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 21 ìpínrọ̀ 8 sí 13, àti àpótí tó wà lójú ìwé 169 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 49-50 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 49:28-39 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Orúkọ Jèhófà Ṣe Jẹ́ “Ilé Gogoro Tí Ó Lágbára”?—Òwe 18:10 (5 min.)
No. 3: Ìgbéyàwó Gbọ́dọ̀ Ní Ọlá—td 19A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti fi ṣàṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù June.
25 min: “À Ń Rìn Ní Ọ̀nà Ìmọ́lẹ̀ Tó Túbọ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I.” Ìbéèrè àti Ìdáhùn tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ February 15, 2006, ojú ìwé 26 sí 30, ìpínrọ̀ 13 sí 20. Ní ṣókí, fi àlàyé tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí nasẹ̀ ìjíròrò náà. Lẹ́yìn náà, kó o wá béèrè àwọn ìbéèrè tó wà fún ìpínrọ̀ 13 sí 20 nínú ìwé ìròyìn náà lọ́wọ́ àwùjọ. Fi ìpínrọ̀ kejì nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí parí ìjíròrò náà. Fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n wo fídíò “Jehovah’s Witnesses—Faith in Action, Part 2: Let the Light Shine,” kí wọ́n lè túbọ̀ lóye kókó tá a jíròrò yìí.
Orin 93 àti Àdúrà