À Ń Rìn Ní Ọ̀nà Ìmọ́lẹ̀ Tó Túbọ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
Jèhófà ni Orísun ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí. (Sm. 43:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé wà nínú òkùnkùn biribiri, Ọlọ́run tòótọ́ ò yéé tan ìmọ́lẹ̀ sórí àwa èèyàn rẹ̀. Kí ni àbájáde èyí? Bíbélì dáhùn pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” (Òwe 4:18) Ìmọ́lẹ̀ tí Jèhófà ń pèsè tó túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i ń mú kí ọ̀nà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń tọ̀ ṣe kedere sí i. Ó ń mú kí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètò àwọn nǹkan dára sí i, ó ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ síwájú sí i, ó sì ń jẹ́ kí ìwà wọn dára sí i. Ẹ jẹ́ ká jíròrò bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe jóòótọ́ sí, bí a ó ti máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn àwa olùjọsìn Jèhófà tòde òní.
Láìsí àní-àní, inú òkùnkùn biribiri làwọn èèyàn tó wà nínú ayé wà. Bí Jèhófà ṣe ń tànmọ́lẹ̀ sórí àwa èèyàn rẹ̀, ńṣe ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín wa àtàwọn èèyàn ayé ń pọ̀ sí i. Àǹfààní wo ni ìmọ́lẹ̀ yìí ń ṣe fún wa ná? Òótọ́ ni pé bá a bá tanná síbi tí kòtò wà nínú òkùnkùn, ìyẹn ò ní kí kòtò náà kúrò, bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń jẹ́ ká rí àwọn ìdẹkùn, àmọ́ kì í mú àwọn ìdẹkùn náà kúrò. Ńṣe ló ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti yàgò fún wọn ká lè máa rìn ní ọ̀nà ìmọ́lẹ̀ tó túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé à ń fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà, “gẹ́gẹ́ bí fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn.”—2 Pét. 1:19.