Ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run Ń Lé Òkùnkùn Dà Nù!
Bíbélì fi òtítọ́ wé ìmọ́lẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé ó fi irọ́ wé òkùnkùn. (Sm. 43:3; Aísá. 5:20) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀, kò sì sí òkùnkùn kankan rárá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” (1 Jòh. 1:5) Kíyè sí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ti wá, àti pé kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú òkùnkùn tẹ̀mí. Ibo wá ni òkùnkùn tẹ̀mí ti wá? Ìjíròrò wa ní àṣálẹ́ yìí máa jẹ́ ká mọ ibi tí òkùnkùn tẹ̀mí ti wá àti bá a ṣe lè yẹra fún un. A tún máa jíròrò bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tá à ń gbádùn.
A nídìí tó pọ̀ láti yin Jèhófà tó jẹ́ ká rí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ rẹ̀. Bíi ti Ọba Dáfídì, àwa náà sọ pé: “Ìwọ ni fìtílà mi, Jèhófà, Jèhófà sì ni ó mú kí òkùnkùn mi mọ́lẹ̀.” (2 Sám. 22:29) Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ dẹra nù, níwọ̀n bí èyí ti lè mú ká pa dà sínú òkùnkùn tá a ti mú wa jáde. Nínú ayé tó ṣókùnkùn birimùbirimù nípa tẹ̀mí yìí, ẹ jẹ́ kí á jẹ́ onígboyà ká sì máa fìtara tàn bí olùtan ìmọ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká “máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.”—Éfé. 5:8.