Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 5
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 5
Orin 115 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 1 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóẹ́lì 1-3 (10 min.)
No. 1: Jóẹ́lì 2:17-27 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Fi Ohun Tó Wà Nínú Òwe 22:3 Sílò? (5 min.)
No. 3: Ǹjẹ́ Ó Burú Láti Wọ́gi Lé Ẹ̀kọ́ Èké—td 14B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Obìnrin Tó Ń Wàásù Ìhìn Rere Jẹ́ Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ńlá. (Sm. 68:11) Ìjíròrò tá a gbé ka àpótí tó wà lójú ìwé 22 nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2009. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù November. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ November, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! October–December 2012, bí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ọ̀kan lára ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
Orin 105 àti Àdúrà