Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November àti December: Ẹ lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tẹ́ ẹ bá ní lọ́wọ́. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ẹ fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án, kí ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. January: Ẹ lo ọ̀kan lára àwọn ìwé olójú ewé méjì-lé-lọ́gbọ̀n yìí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé tàbí Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! Kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà ìpadàbẹ̀wò, ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa túbọ̀ wúlò dáadáa fún onílé lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà.