Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù November
“Gbogbo wa là ń fẹ́ ìjọba tó dáa. Irú ìjọba wo lo rò pé ó máa yanjú àwọn ìṣòro wa? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí ìwé yìí sọ.” Fún onílé náà ní Ilé Ìṣọ́ November 1, kí ẹ sì jọ jíròrò ohun tó wà ní abẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16 àti ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ November 1
“Jọ̀wọ́ mo fẹ́ mọ èrò rẹ nípa ọ̀rọ̀ kan. Ká sọ pé o láǹfààní láti bi Ọlọ́run ní ìbéèrè kan, kí lo máa bi í ná? [Jẹ́ kó fèsì.] Bí Jésù ṣe sọ, ó dáa ká máa wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ń jẹ wá lọ́kan. [Ka Mátíù 7:7.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè mẹ́ta tó ṣe pàtàkì yìí.” Fi àwọn ìbéèrè tó wà ní ìsàlẹ̀ ojú ìwé 3 hàn án.
Ji! October–December
“Mo fẹ́ mọ èrò rẹ lórí ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ. [Ka Gálátíà 6:7.] Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tá a bá fúnrúgbìn la máa ká. Kí nìdí tó o fi rò pé ó yẹ ká jẹ́ olóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì] Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 14 nínú ìwé ìròyìn yìí sọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ olóòótọ́.”