Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 12
Orin 66 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 1 ìpínrọ̀ 8 sí 14 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ámósì 1-9 (10 min.)
No. 1: Ámósì 3:1-15 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìgbà Tí Inú Ọlọ́run Máa Ń Dùn Téèyàn Bá Yí Ẹ̀sìn Tó Ń Ṣe Pa Dà—td 14D (5 min.)
No. 3: Àwọn Àǹfààní Wo La Máa Jẹ Tá A Bá Lóyè Ohun Tó Wà Ní Sáàmù 51:17? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bí Ẹnì Kan Bá Sọ Pé, ‘Ẹ Kò Gba Jésù Gbọ́.’ Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí táwọn kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa fi máa ń sọ bẹ́ẹ̀? Ìbéèrè wo la lè bi wọ́n tó máa jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn? Èwo nínú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ni wọ́n máa fẹ́ gbọ́? Àwọn kókó wo la lè fi dá wọn lóhùn ní orí 4 nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni? Gba àwọn ará níyànjú láti ka ìdí tá a fi ṣe ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fún ẹni tó bá sọ pé a kò gba Jésù gbọ́, bó ṣe wà ní ojú ìwé 2 nínú Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn kan.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ka Máàkù 1:16-20. Kẹ́ ẹ sì jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè wúlò fún wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
10 min: “Máa Rí Ohun Rere Nínú Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 98 àti Àdúrà