Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 26
Orin 62 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 2 ìpínrọ̀ 1 sí 6 àti àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 19 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Míkà 1-7 (10 min.)
No. 1: Míkà 3:1-12 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Wo Ni Ọlọ́run Máa Jí Dìde?—td 3A (5 min.)
No. 3: Bá A Ṣe Mọ̀ Pé Jèhófà Jẹ́ Olùgbọ́ Àdúrà—1 Jòh. 5:14 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù December. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn.
10 min: Àṣẹ́kùsílẹ̀ Wọn Dí Àìnító Kan. Àsọyé. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2012, ojú ìwé 8 àti 9.
15 min: “Túbọ̀ Sa Gbogbo Ipá Rẹ—Tọ́wọ́ Rẹ Bá Tiẹ̀ Máa Ń Dí.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí.
Orin 73 àti Àdúrà