Túbọ̀ Sa Gbogbo Ipá Rẹ—Tọ́wọ́ Rẹ Bá Tiẹ̀ Máa Ń Dí
1. Kí nìdí tí kì í yá àwọn akéde kan lára láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn?
1 Kì í yá àwọn akéde kan lára láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn torí pé ọwọ́ irú àwọn akéde bẹ́ẹ̀ máa ń dí gan-an. Ríran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ máa ń gba àkókò. A nílò àkókò láti múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀, láti kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́, ká sì ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ bó ṣe lè borí àwọn ìṣòro tó fẹ́ dènà ìtẹ̀síwájú rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun fún àwọn tó wà ní ìlú Tẹsalóníkà ní ọkàn òun kí òun lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà. (1 Tẹs. 2:7, 8) Báwo la ṣe lè máa wáyè láti kọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kódà tọ́wọ́ wa bá tiẹ̀ máa ń dí?
2. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe kan bá a ṣe ń lo àkókò wa?
2 A Nílò Àkókò Láti Sin Jèhófà: Òótọ́ pàtàkì kan ni pé a nílò àkókò láti sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń lọ sí ìpàdé déédéé, a máa ń lọ sóde ẹ̀rí, a máa ń ka Bíbélì, a sì máa ń gbàdúrà. A nílò àkókò láti máa ṣe gbogbo nǹkan yìí déédéé. Bí àwọn tọkọtaya tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn ṣe máa ń wáyè láti gbọ́ tara wọn, bákan náà ló ṣe yẹ kí inú wa máa dùn láti ‘ra àkókò padà’ ká lè fi jọ́sìn Jèhófà torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Éfé. 5:15-17; 1 Jòh. 5:3) Bí Jésù ṣe sọ, iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa. (Mát. 28:19, 20) Tá a bá ń fi èyí sọ́kàn, a kò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, torí pé ojúṣe wa ni.
3. Bí a kò bá ní lè jáde òde ẹ̀rí, àwọn ètò wo la lè ṣe láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Kí la lè ṣe bí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, àìlera tàbí àwọn ìṣẹ́ míì tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run kò bá jẹ́ ká lè jáde òde ẹ̀rí tó bá a ṣe fẹ́? Àwọn akéde kan tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbélé máa ń lo tẹlifóònù tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn akéde míì tí wọ́n ní ìṣòro àìlera máa ń pe àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sílé wọn kí wọ́n lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn míì máa ń ṣètò pé kí akéde kan báwọn kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́ nígbà táwọn ò bá ráyè.
4. Àwọn ìbùkún wo la máa rí tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láyọ̀ gan-an torí pé ó lo àkókò àti okun rẹ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Ìṣe 20:35) Ó máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nígbàkigbà tó bá rántí àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ní ìlú Tẹsalóníkà. (1 Tẹs. 1:2) Tọ́wọ́ wa bá tiẹ̀ máa ń dí gan-an, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa sa gbogbo ipá wa láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èyí á jẹ́ ká túbọ̀ ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.