ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 November ojú ìwé 31
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Déédéé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Déédéé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
    Jí!—2012
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Túbọ̀ Sa Gbogbo Ipá Rẹ—Tọ́wọ́ Rẹ Bá Tiẹ̀ Máa Ń Dí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Fún Gbogbo Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 November ojú ìwé 31
Arábìnrin kan ń lo kọ̀ǹpútà àti Bíbélì láti dá kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń kọ ohun tó kọ́ sínú ìwé kan. Ó ń lo àtẹ “Àwọn Agbára Ayé Tí Dáníẹ́lì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Wọn” ní Àfikún B9 nínú “Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.”

Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Déédéé

ṢÉ Ó máa ń nira fún ẹ láti dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, kó o sì máa gbádùn ẹ̀? Nígbà míì, ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa. Àmọ́ ronú nípa àwọn nǹkan míì tá a máa ń ṣe déédéé, bí àpẹẹrẹ, a máa ń wẹ̀ déédéé. Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá kéèyàn tó wẹ̀. Ṣùgbọ́n tá a bá wẹ̀ tán, ara wa máa ń balẹ̀! Bó ṣe máa ń rí nìyẹn téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó dà bí kéèyàn ‘fi omi wẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ (Éfé. 5:26) Wo àwọn àbá tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́:

  • Ní ètò tí wàá máa tẹ̀ lé. Kéèyàn máa dá kẹ́kọ̀ọ́ wà lára “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe. (Fílí. 1:10) Torí náà, o ò ṣe lẹ ètò tó o ṣe mọ́ ilẹ̀kùn fìríìjì tàbí pátákó kan níbi tí wàá ti tètè máa rí i. O sì lè lo àláàmù orí fóònù ẹ kó o lè rántí pé àkókò tó o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ti fẹ́ tó.

  • Ṣe ohun tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn. Ṣé o máa ń lè pọkàn pọ̀ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ fún àkókò tó gùn, àbí ohun tó máa ń rọ̀ ẹ́ lọ́rùn ni kó o máa fi àkókò díẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ tó yàtọ̀ síra? Ìwọ lo mọ èyí tó dáa jù fún ẹ. Torí náà, èyí tó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn ni kó o ṣe. Tí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ bá tó, tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ò wá wù ẹ́ ṣe, o ò ṣe pinnu pé o ò ní pẹ́, kó o kàn lo ìṣẹ́jú mẹ́wàá? Tó o bá lo àkókò díẹ̀, wàá gbádùn ẹ̀, wàá rí nǹkan kọ́, ìyẹn sì sàn ju kó o má kẹ́kọ̀ọ́ rárá. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ, o lè wá rí i pé ò ń gbádùn ẹ̀, kó o sì pinnu pé wàá lò kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá tó o fẹ́ lò tẹ́lẹ̀.—Fílí. 2:13.

  • Yan ohun tó o máa kọ́ kó o tó bẹ̀rẹ̀. Kì í ṣe ìgbà tó o jókòó láti kẹ́kọ̀ọ́ ló yẹ kó o yan ohun tó o máa kọ́, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní lè ‘lo àkókò ẹ lọ́nà tó dára jù lọ.’ (Éfé. 5:16) O lè yan àwọn àpilẹ̀kọ kan tó o fẹ́ràn tàbí àwọn àkòrí kan tó wù ẹ́ kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀. Tó o bá ní ìbéèrè, kọ ọ́ sílẹ̀. Tó o bá sì parí ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, o lè fi àwọn nǹkan míì tó o rí kún ohun tó o máa kẹ́kọ̀ọ́ nígbà míì.

  • Ṣe àyípadà tó bá yẹ. Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o yí ètò tó o ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ pa dà, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè yí àkókò tó o máa lò tàbí àwọn àkòrí tó o yàn pa dà. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, kì í ṣe ìgbà tó o kẹ́kọ̀ọ́, bí àkókò tó o fi kẹ́kọ̀ọ́ ṣe gùn tó tàbí ohun tó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀.

Ká sòótọ́, a máa jàǹfààní tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àá máa ṣèpinnu tó dáa láyé wa, ìgbàgbọ́ wa á sì túbọ̀ lágbára.—Jóṣ. 1:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́