Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 3
Orin 128 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 2 ìpínrọ̀ 7 sí 13 àti àpótí tó wà lójú ìwé 20 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Náhúmù 1–Hábákúkù 3 (10 min.)
No. 1: Hábákúkù 2:1-14 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìdánilójú Sọ Òtítọ́?—2 Tím. 1:7, 8 (5 min.)
No. 3: Ibo Ni Ọlọ́run Máa Jí Àwọn Òkú Dìde Sí?—td 3B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù December. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ December, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! October–December 2012, bí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ọ̀kan lára ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Àwọn Ìrírí Tá A Ní Nígbà Tá A Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù. Ìjíròrò tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn máa bójú tó. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n lo ìwé àṣàrò kúkúrú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ióṣù November. Ní kí àwọn akéde méjì ṣe àṣefihàn bí wọ́n ṣe lo ìwé àṣàrò kúkúrú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.
Orin 96 àti Àdúrà