“Ìdí Tí Mo Fi Wá Síbí Ni Pé . . . ”
Tí àwọn èèyàn bá ṣí ilẹ̀kùn wọn tí wọ́n sì rí wa, wọ́n lè bi wá pé ta ni wá, kí sì nìdí tá a fi wá? Báwo la ṣe lè nasẹ̀ ọ̀rọ̀ wa lọ́nà tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀? Lẹ́yìn táwọn akéde kan bá ti kí onílé dáadáa tán, wọ́n máa ń sọ “ìdí” tí àwọn fi wá sọ́dọ̀ rẹ̀ fún un. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé: “Ìdí tá a fi wá síbi ni pé a kíyè sí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìwà ọ̀daràn kò jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀. Ǹjẹ́ o rò pé . . . ” tàbí kí wọ́n sọ pé,“Ìdí tí mo fi wá síbí ni pé mò ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.” Tó bá jẹ́ pé gbàrà tó o dé ọ̀dọ̀ onílé lo ti jẹ́ kó mọ ìdí tó o fi wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó fẹ́ gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ.