Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní March àti April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! May àti June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
◼ Ọ̀sẹ̀ April 6 la máa sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2015. Àkòrí àsọyé náà ni “Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ìdílé Máa Láyọ̀ Títí Láé.” Kí àwọn ìjọ tó bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká tàbí àpéjọ àyíká ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé wọn ní ọ̀sẹ̀ tó bá tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àsọyé yìí ṣáájú April 6.
◼ Ọjọ́ Friday, April 3, 2015 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Tó bá jẹ́ ọjọ́ Friday ni ìjọ yín máa ń ṣèpàdé, kí ẹ ṣe é ní ọjọ́ míì tí àyè bá máa wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yín lọ́sẹ̀ yẹn. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó di dandan kẹ́ ẹ fagi lé Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, kí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fi àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó bá kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n kún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn míì lóṣù yẹn.