Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ April 1
“À ń fún àwọn èèyàn tó wà ládùúgbò yín ní ìwé yìí. [Fún onílé ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì Jẹ́? Kó o sì bi í ní àwọn ìbéèrè tó wà níwájú rẹ̀. Fi ohun tí Bíbélì sọ ní 2 Tímótì 3:16 hàn án, kó o sì ní kó wá àyè láti kà á.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé Bíbélì dáhùn irú àwọn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ń tẹ́ni lọ́rùn. [Fi àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ nínú Ilé Ìṣọ́ náà hàn án.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bí o ṣe lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú Bíbélì rẹ.”
Ji! March–April
“A wá ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ yín torí pé ìrora àti ìyà tó kún inú ayé ti kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ àwa èèyàn tàbí pé ọ̀rọ̀ wa ò tiẹ̀ jẹ ẹ́ lógún rárá. Ṣé o rò pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ wá? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ pé Ọlọ́run kì í dán ẹnikẹ́ni wò. [Ka Jákọ́bù 1:13.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìjìyà àti ohun tí Ọlọ́run máa ṣe nípa rẹ̀.”