Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ February 1
“À ń fún àwọn èèyàn tó wà lágbègbè yìí ní ìwé yìí. Ó sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe wúlò fún wa. Tiyín rèé. [Fún onílé ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì Jẹ́?] Àwọn èèyàn kan máa ń ronú bóyá ni Bíbélì ní àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tó lè ràn àwọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ àwọn. Ẹ gbọ́ ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ nípa iṣẹ́. [Ka Oníwàásù 3:13.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ayọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ wa. Màá fẹ́ kí ẹ kà á.”
Ji! January–February
Àwòrán yìí sọ ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ìmọ́tótó jẹ́. [Fi àwòrán tó wà lójú ìwé 8 hàn án.] Kó o wá bi ẹni náà pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ rò pé kí ara àti àyíká mọ́ nìkan ló fi hàn pé èèyàn mọ́ tónítóní?’ [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 2 Kọ́ríńtì 7:1.] Àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fún wa nípa ìmọ́tótó ní nínú ìmọ́tótó ara, ti ìwà, ìjọsìn àti pé kí èrò inú wa mọ́. Àwọn ìlànà yìí jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó àti pé ọ̀rọ̀ wa ṣe pàtàkì sí i gan-an. Àpilẹ̀kọ yìí á sọ àwọn àǹfààní tó wà nínú ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ìmọ́tótó.”