Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 4
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 4
Orin 68 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 24 ìpínrọ̀ 1 sí 10 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà 2 Sámúẹ́lì 1-3 (8 min.)
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 2:24-32 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Onínú Tútù àti Onísùúrù (5 min.)
No. 3: Àwọn Ìlérí Tó Wà Nínú Bíbélì Tí Yóò Ṣẹ Láìpẹ́—igw ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 4 sí ojú 17 ìpínrọ̀ 1 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọlọgbọ́n nípa “ríra àkókò tí ó rọgbọ padà.”—Éfé. 5:15, 16.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Ẹ lè fi bá a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn lọni kún un.
5 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù July. Ìjíròrò. Sọ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé tá a máa lò. Ṣe àṣefihàn kan.
15 min: Wíwàásù ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tí A Kì Í Ṣe Déédéé—Ọ̀nà Tó Dára Láti Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Pa Dà! Alàgbà ni kó bójú tó ìjíròrò yìí. Ohun tó máa dára jù ni pé kó jẹ́ alàgbà tó ti lọ wàásù rí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Wíwàásù ní Àgbègbè Àdádó—Ọ́sirélíà. (Lọ sórí ìkànnì jw.org/yo, wo abẹ́ NÍPA WA > OHUN TÁ À Ń ṢE.)Ẹ jíròrò ipa rere tí wíwàásù ní ìpínlẹ̀ tí a kì í ṣe déédéé ní lórí ìdílé tá a rí nínú fídíò náà. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde tó ti lọ wàásù rí ní ìpínlẹ̀ tí a kì í ṣe déédéé. Ipa rere wo ló ti ní lórí ìdílé wọn, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, àti àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà? Báwo ni wọ́n ṣe ṣètò ara wọn? Tá a bá rí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé, inú àwọn alàgbà á dùn láti ràn án lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn ará mọ̀ pé wíwàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé jẹ́ ọ̀nà kan tó dára tá a lè gbà ra àkókò tí ó rọgbọ pa dà.
Orin tuntun “Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in” àti Àdúrà
Ìránnilétí: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ́kọ́ gbọ́ orin yìí lẹ́ẹ̀kan. Lẹ́yìn náà, kí àwọn ará kọ orin tuntun yìí.