ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/15 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 10/15 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 26, 2015.

  1. Báwo ni ìtàn tó wà ní 2 Àwọn Ọba 13:18, 19 ṣe ṣàpèjúwe bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ onítara ká sì máa fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? [Sept. 7, w10 4/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 11]

  2. Ọba wo ló ń ṣàkóso ní Ísírẹ́lì nígbà tí Jónà ń sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì, kí sì ló wú wa lórí nípa Jónà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà ní 2 Àwọn Ọba 14:23-25? [Sept. 7, w09 1/1 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 4]

  3. Kí ni Áhásì ọba ṣe tó fi hàn pé kó nígbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wòlíì Aísáyà sọ, àwọn ìbéèrè wo la sì lè bi ara wa tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì? (2 Ọba 16:7) [Sept. 14, w13 11/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 5]

  4. Irú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo làwọn tó ń ta ko Jèhófà lóde òní ń lò bíi ti Rábúṣákè, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti kọ irú àwọn èrò èké bẹ́ẹ̀? (2 Ọba 18:22, 25) [Sept. 14, w10 7/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 3 àti 4]

  5. Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jòsáyà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jàǹfààní kíkún tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀? (2 Ọba 22:19, 20) [Sept. 21, w00 3/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2]

  6. Báwo làwọn awalẹ̀pìtàn ṣe fi hàn pé àwọn ọba méjèèjì tí Bíbélì mẹ́nu kàn nínú 2 Àwọn Ọba 25:27-30 wà lóòótọ́? [Sept. 28, w12 6/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 2 àti 3]

  7. Ohun mẹ́ta wo ni Jábésì béèrè lọ́wọ́ Jèhófà, ẹ̀kọ́ wo sì ni èyí kọ́ wa nípa àdúrà gbígbà? (1 Kíró. 4:9, 10) [Oct. 5, w10 10/1 ojú ìwé 23]

  8. Báwo ni àbájáde ogun tí 1 Kíróníkà 5:18-22 sọ nípa rẹ̀ ṣe lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun ká lè máa fìgboyà ja ogun tẹ̀mí náà? [Oct. 12, w05 10/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 7]

  9. Kí ló mú kí Dáfídì lóye ohun tó rọ̀ mọ́ òfin Jèhófà nípa ẹ̀jẹ̀ kó sì fi ọ̀wọ̀ hàn fún un, kí ló sì yẹ kí àpẹẹrẹ Dáfídì sún wa láti ṣe? (1 Kíró. 11:17-19) [Oct. 19, w12 11/15 ojú ìwé 6 sí 7 ìpínrọ̀ 12 sí 14]

  10. Kí ni Dáfídì kò fara balẹ̀ ṣe nígbà tó ń gbìyànjú láti gbé àpótí ẹ̀rí lọ sí Jerúsálẹ́mù, ẹ̀kọ́ pàtàkì wo lèyí sì kọ́ wa? (1 Kíró. 15:13) [Oct. 26, w03 5/1 ojú ìwé 10 sí 11 ìpínrọ̀ 11 sí 13]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́