Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Rẹ Lójoojúmọ́?
Tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, a ó máa “ta gbòǹgbò,” a ó sì máa “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Kól. 2:6, 7) Àmọ́, kí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó lè nípa lórí ìgbésí ayé wa, a gbọ́dọ̀ máa kà á, kí á sì máa fi ìlànà inú rẹ̀ sílò. (Héb. 4:12; Ják. 1:22-25) Jóṣúà 1:8 sọ ọ̀nà mẹ́ta tó gbéṣẹ́ tí a lè gbà ka ìwé Mímọ́: (1) Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní ọ̀sán àti ní òru.” (2) Máa fi “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” kà á, èyí gba pé kó o máa pọkàn pọ̀ tí o bá ń kà á, kó o máa fojú inú yàwòrán bí ohun tí ò ń kà ṣe wáyé àti onírúurú ipò tó yí i ká. (3) Tí a bá ń fi “gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀” sílò, èyí á mú kí ‘ọ̀nà wa yọrí sí rere’ a ó sì máa “hùwà ọgbọ́n” nínú àwọn ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́.