Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 26
Orin 15 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
ia orí 1 ìpínrọ̀ 1 sí 13 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 12-15 (8 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Oṣù Yìí: ‘Ẹ ta gbòǹgbò kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.’—Kól. 2:6, 7.
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù November. Ìjíròrò. Ṣe ìṣẹ́ yìí lọ́nà táá mú kí àwọn ará fi ìtara lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lóde ẹ̀rí. Ní ṣókí, sọ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àpilẹ̀kọ tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Àwọn Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Wa Tuntun Ṣàrà Ọ̀tọ̀!” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù April 2014. Ṣe àṣefihàn kan tó bá ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín mu.
20 min: “Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Rẹ Lójoojúmọ́?” Àsọyé. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí, jẹ́ kí àwọn ará gbọ́ ìtàn inú Bíbélì kíkà bí ẹni ṣe eré ìtàn tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Má Ṣe Rẹ̀wẹ̀sì Nígbà Tí Jèhófà Bá Tọ́ Ọ Sọ́nà!” èyí tó o wà jáde lórí ìkànnì jw.org/yo. Sọ bí ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tá a kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìlànà tá a lè máa lò nígbèésí ayé wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n máa jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà bí ẹni ṣe eré ìtàn tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo.
Orin 113 àti Àdúrà