Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 12
Orin 135 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 31 ìpínrọ̀ 21 sí 23, àti àpótí tó wà lójú ìwé 319 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 5-7 (8 min.)
No. 1: 1 Kíróníkà 6:48-60 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ta Ló Máa Mú Kí Àlàáfíà Jọba Lórí Ilẹ̀ Ayé?—wp13 6/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Ìwé Mímọ́ Fi Kìlọ̀ Pé Ká Má Ṣe Di “Olódodo Àṣelékè”—Oníw. 7:16 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Oṣù Yìí: ‘Ẹ ta gbòǹgbò kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.’—Kól. 2:6, 7.
10 min: ‘Ẹ Ta Gbòǹgbò Kí Ẹ sì Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Nínú Ìgbàgbọ́.’ Àsọyé tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. Kí ló túmọ̀ sí láti “ta gbòǹgbò” kí á sì “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́,” báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? (Wo Ilé Ìṣọ́ October 15, 2009, ojú ìwé 26 sí 28.) Ka Kólósè 2:6, 7; Hébérù 6:1 àti Júúdà 20, 21, kó o sì sọ bí a ṣe lè fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sílò. Sọ díẹ̀ lára àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn oṣù yìí, kó o sì jíròrò bí wọ́n ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí.
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́ Dáadáa.” Ìjíròrò. Ṣe àṣefihàn bí Akéde kan tó nírìírí dáadáa ṣe ń ṣàlàyé fún ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó ṣe lè fi Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower dáhùn ìbéèrè.
Orin 116 àti Àdúrà