Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́ Dáadáa
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tó lè dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ ọkàn wọn, èyí sì gba pé kí wọ́n mọ̀ ju àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ. (Héb. 5:12–6:1) Àmọ́, ó gba ìsapá láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Èyí gba pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà máa rí bí àwọn ohun tuntun tó kọ́ ṣe tan mọ́ èyí tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, kó sì fòye mọ bó ṣe lè fi ẹ̀kọ́ náà sílò ní ìgbésí ayé rẹ̀. (Òwe 2:1-6) Tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá mọ bí wọ́n ṣe lè ṣe ìwádìí, èyí á jẹ́ kí wọ́n lè fi àwọn ìtẹ̀jáde wa dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá ní látinú Bíbélì. Bí wọ́n bá ń sapá gidigidi láti fi àwọn ohun tí wọ́n kọ́ sílò, wọ́n á lè kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ń dojú kọ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni.—Lúùkù 6:47, 48.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti kẹ́kọ̀ọ́ ìsọ̀rí kan tàbí òrí kan nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yín, ní kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ ṣe àkópọ̀ ohun tó kọ́ ní ṣókí. Tí o kò bá ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè ṣe àkópọ̀ ohun tó o kà nínú Bíbélì tàbí nínú Ilé Ìṣọ́ ní ṣókí, èyí á jẹ́ kó o sunwọ̀n sí i nínú bó o ṣe lè lóye ohun tó o kà.