Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 21
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 21
Orin 90 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
ia orí 5 ìpínrọ̀ 1 sí 13 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 20-24 (8 min.)
No. 1: 2 Kíróníkà 20:13-20 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tá A Fi Ń Rìn Nípa Ìgbàgbọ́ Tí A Kò sì Rìn Nípa Ohun Tí A Rí—2 Kọ́r. 5:7 (5 min.)
No. 3: Kí Nìdí Tí Ìjọba Ọlọ́run Fi Máa Ṣe Àwọn Tó Bá Ń Gbàdúrà Tọkàntọkàn Pé Kó Dé Láǹfààní?—wp14 10/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Oṣù Yìí: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.”—Ìṣe 14:22.
5 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé.
10 min: Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. A gbé e ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2015, ojú ìwé 14 àti 15.
15 min: Ẹ Jẹ́ Oníṣọ̀ọ́ra Bí Ejò, Síbẹ̀ Kí Ẹ Jẹ́ Ọlọ́rùn-Mímọ́ Bí Àdàbà. (Mát. 10:16) Ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Ọdọọdún 2015, ojú ìwé 72, ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 73 àti ojú ìwé 111 sí 116. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 137 àti Àdúrà