Àpótí Ìbéèrè
◼ Ìgbà Wo Ló Yẹ Kó O Dá Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan Dúró?
Tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ kò bá tẹ̀ síwájú mọ́ nípa tẹ̀mí, o lè fọgbọ́n dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ dúró. (Mát. 10:11) Gbé àwọn kókó yìí yẹ̀wò: Ǹjẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń pa àdéhùn tẹ́ ẹ ṣe fún ìkẹ́kọ̀ọ́ mọ́ déédéé? Ǹjẹ́ ó máa ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ń wá sí àwọn ìpàdé kan? Ǹjẹ́ ó máa ń sọ ohun tó ń kọ́ fún àwọn ẹlòmíì? Ǹjẹ́ ó ń ṣe àyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì? Ó yẹ kó o gbé ọjọ́ orí ẹni náà àti ibi tí òye rẹ̀ mọ yẹ̀wò, máa rántí pé ìtẹ̀síwájú kálukú máa ń yàtọ̀ síra. Bákan náà, tó o bá dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà dúró, ṣe é lọ́nà tó fi máa ṣeé ṣe fún ẹni náà láti tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pa dà lọ́jọ́ iwájú.—1 Tím. 2:4.