Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 28
Orin 79 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
ia orí 5 ìpínrọ̀ 14 sí 26, àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 50 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 25-28 (8 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Oṣù Yìí: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.”—Ìṣe 14:22.
15 min: Máa Gbàdúrà Fáwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Rẹ. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ ka Ìṣe 12:1-11. Sọ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé Jíjẹ́rìí, ojú ìwé 77 sí 80, ìpínrọ̀ 5 sí 12. Lẹ́yìn náà, sọ àwọn ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tó wà lórí ìkànnì jw.org, lábẹ́ apá tá a pè ní “Newsroom.” Gba àwọn ará níyànjú láti máa gbàdúrà fún àwọn ará wa kárí ayé tó ń kojú onírúurú àdánwò, kódà tó bá ṣeé ṣe ká dárúkọ wọn nínú àdúrà wa.—2 Kọ́r. 1:11; 1 Tím. 2:1, 2.
15 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
Orin 124 àti Àdúrà