Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 28, 2015. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
Ṣé lóòótọ́ ni Dáfídì dá àwọn tó mú lóǹdè lóró, gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn kan sọ pé 1 Kíróníkà 20:3 túmọ̀ sí? [Nov. 2, w05 2/15 ojú ìwé 27]
Kí ló jẹ́ kí Dáfídì fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn, kí ló sì máa jẹ́ kí àwa náà ṣe bíi tirẹ̀? (1 Kíró. 22:5) [Nov. 9, w05 10/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 7]
Kí ni Dáfídì ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún Sólómọ́nì pé: “Mọ Ọlọ́run baba rẹ”? (1 Kíró. 28:9) [Nov. 16, w10 11/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3 àti 7]
Kí ni àdúrà tí Sólómọ́nì gbà tó wà ní 2 Kíróníkà 1:10 jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ tá a bá ronú lórí ohun tí à ń sọ nínú àdúrà wa sí Jèhófà? (2 Kíró. 1:11, 12) [Nov. 23, w05 12/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 6]
Ní ìbámu pẹ̀lú 2 Kíróníkà 6:29, 30, ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ni Jèhófà lè ṣe, báwo la sì ṣe lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún un nínú àdúrà? (Sm. 55:22) [Nov. 30, w10 12/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 7]
Orí kí ni àdúrà tí Ásà gbà pé kí òun ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ níye dá lé, kí ló sì yẹ kó dá wa lójú nípa ogun tẹ̀mí tí à ń jà? (2 Kíró. 14:11) [Dec. 7, w12 8/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1]
Báwo ni ọwọ́ tí Jèhófà fi mú ọ̀rọ̀ Jèhóṣáfátì Ọba nígbà tó ṣe àwọn àṣìṣe kan ṣe mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ojú wo ló sì yẹ ká máa fi wo àwọn ẹlòmíì? (2 Kíró. 19:3) [Dec. 14, w03 7/1 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 13; cl ojú ìwé 245 ìpínrọ̀ 12]
Kí nìdí tó fi yẹ ká “mú ìdúró [wa]” ká sì “dúró jẹ́ẹ́,” lóde òní, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? (2 Kíró. 20:17) [Dec. 21, w05 12/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 2; w03 6/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 15 àti 16]
Ọ̀rọ̀ pàtàkì tó yẹ ká ronú lé lórí wo la rí nínú 2 Kíróníkà 21:20 tó ní í ṣe pẹ̀lú ikú Jèhórámù? [Dec. 21, w98 11/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 4]
Ní ìbámu pẹ̀lú 2 Kíróníkà 26:5, àpẹẹrẹ rere ta ni ọ̀dọ́kùnrin náà, Ùsáyà tẹ̀ lé, báwo làwọn ọ̀dọ́ lóde òní ṣe lè jàǹfààní lára àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn tí wọ́n wà nínú ìjọ? [Dec. 28, w07 12/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 2 àti 4]