ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Ikú Ábíjà (1)

      • Ásà di ọba Júdà (2-8)

      • Ásà ṣẹ́gun 1,000,000 àwọn ará Etiópíà (9-15)

2 Kíróníkà 14:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:9

2 Kíróníkà 14:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:5
  • +Ẹk 23:24
  • +1Ọb 14:22, 23; 2Ọb 18:1, 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2009, ojú ìwé 12

2 Kíróníkà 14:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 34:1, 4

2 Kíróníkà 14:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 11:5
  • +2Kr 15:15; Owe 16:7

2 Kíróníkà 14:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:2, 5
  • +Sm 127:1

2 Kíróníkà 14:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.

  • *

    Ní Héb., “wọ́n mọ bí a ṣe ń fi okùn sí ọrun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 11:1, 12; 13:3

2 Kíróníkà 14:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 16:8
  • +Joṣ 15:20, 44; 2Kr 11:5, 8

2 Kíróníkà 14:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbára lé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 14:10; 1Kr 5:20; 2Kr 32:20
  • +Ond 7:7; 1Sa 14:6
  • +2Kr 13:12; 32:7, 8
  • +1Sa 17:45; Sm 20:5; Owe 18:10
  • +Joṣ 7:9; Sm 9:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2012, ojú ìwé 8-9

2 Kíróníkà 14:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:7

2 Kíróníkà 14:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 20:1

Àwọn míì

2 Kíró. 14:12Sa 5:9
2 Kíró. 14:3Di 7:5
2 Kíró. 14:3Ẹk 23:24
2 Kíró. 14:31Ọb 14:22, 23; 2Ọb 18:1, 4
2 Kíró. 14:52Kr 34:1, 4
2 Kíró. 14:62Kr 11:5
2 Kíró. 14:62Kr 15:15; Owe 16:7
2 Kíró. 14:72Kr 32:2, 5
2 Kíró. 14:7Sm 127:1
2 Kíró. 14:82Kr 11:1, 12; 13:3
2 Kíró. 14:92Kr 16:8
2 Kíró. 14:9Joṣ 15:20, 44; 2Kr 11:5, 8
2 Kíró. 14:11Ẹk 14:10; 1Kr 5:20; 2Kr 32:20
2 Kíró. 14:11Ond 7:7; 1Sa 14:6
2 Kíró. 14:112Kr 13:12; 32:7, 8
2 Kíró. 14:111Sa 17:45; Sm 20:5; Owe 18:10
2 Kíró. 14:11Joṣ 7:9; Sm 9:19
2 Kíró. 14:12Di 28:7
2 Kíró. 14:13Jẹ 20:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 14:1-15

Kíróníkà Kejì

14 Níkẹyìn, Ábíjà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì;+ Ásà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. Nígbà ayé rẹ̀, ilẹ̀ náà ní àlàáfíà fún ọdún mẹ́wàá.

2 Ásà ṣe ohun tó dára tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. 3 Ó mú àwọn pẹpẹ àjèjì+ àti àwọn ibi gíga kúrò, ó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́,+ ó sì gé àwọn òpó òrìṣà lulẹ̀.*+ 4 Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ fún Júdà pé kí wọ́n wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, kí wọ́n sì máa pa Òfin àti àṣẹ rẹ̀ mọ́. 5 Torí náà, ó mú àwọn ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tùràrí kúrò ní gbogbo àwọn ìlú Júdà,+ ìjọba náà sì wà láìsí ìyọlẹ́nu lábẹ́ àbójútó rẹ̀. 6 Ó kọ́ àwọn ìlú olódi sí Júdà,+ nítorí pé kò sí ìyọlẹ́nu ní ilẹ̀ náà, wọn kò sì bá a jagun ní àwọn ọdún yẹn, torí Jèhófà fún un ní ìsinmi.+ 7 Ó sọ fún Júdà pé: “Ẹ jẹ́ ká kọ́ àwọn ìlú yìí, ká sì mọ ògiri àti àwọn ilé gogoro+ yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ẹnubodè* àti àwọn ọ̀pá ìdábùú. Nítorí ilẹ̀ náà ṣì wà ní ìkáwọ́ wa, torí a ti wá Jèhófà Ọlọ́run wa. A ti wá a, ó sì ti fún wa ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó yí wa ká.” Torí náà, wọ́n parí àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́.+

8 Ásà ní àwọn ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) ọkùnrin láti Júdà, apata ńlá àti aṣóró wà lọ́wọ́ wọn. Ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) jagunjagun tó lákíkanjú láti inú Bẹ́ńjámínì ló ń gbé asà,* tí wọ́n sì ní ọfà lọ́wọ́.*+

9 Lẹ́yìn náà, Síírà ará Etiópíà wá gbéjà kò wọ́n pẹ̀lú ọmọ ogun tó jẹ́ mílíọ̀nù kan (1,000,000) ọkùnrin àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) kẹ̀kẹ́ ẹṣin.+ Nígbà tó dé Máréṣà,+ 10 Ásà jáde lọ gbéjà kò ó, wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun ní Àfonífojì Séfátà ní Máréṣà. 11 Ásà wá ké pe Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+ ó ní: “Jèhófà, kò jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ bóyá àwọn tí o fẹ́ ràn lọ́wọ́ pọ̀ tàbí wọn ò lágbára. + Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé,*+ a wá ní orúkọ rẹ láti dojú kọ ọ̀pọ̀ èèyàn yìí.+ Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú borí rẹ.”+

12 Torí náà, Jèhófà ṣẹ́gun àwọn ará Etiópíà níwájú Ásà àti níwájú Júdà, àwọn ará Etiópíà sì sá lọ.+ 13 Ásà àti àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ń lé wọn lọ títí dé Gérárì,+ àwọn ará Etiópíà sì ń ṣubú títí kò fi sí ìkankan lára wọn tó wà láàyè, torí pé Jèhófà àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n kó ẹrù ogun tó pọ̀ gan-an. 14 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n kọ lu gbogbo àwọn ìlú tó yí Gérárì ká, nítorí Jèhófà ti kó jìnnìjìnnì bá wọn; wọ́n sì kó ẹrù gbogbo àwọn ìlú náà, nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà níbẹ̀ tí wọ́n lè kó. 15 Wọ́n tún kọ lu àgọ́ àwọn tó ní ẹran ọ̀sìn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ agbo ẹran àti ràkúnmí, lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́