ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kíróníkà 28
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kíróníkà

      • Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ lórí kíkọ́ tẹ́ńpìlì (1-8)

      • Ó sọ ohun tí Sólómọ́nì máa ṣe; ó fún un ní àwòrán ìkọ́lé (9-21)

1 Kíróníkà 28:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 27:1
  • +Ẹk 18:25
  • +1Kr 27:25, 29
  • +1Kr 3:1-9
  • +1Kr 11:10

1 Kíróníkà 28:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 132:3-5
  • +1Kr 22:2-4

1 Kíróníkà 28:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 17:4
  • +1Kr 22:7, 8

1 Kíróníkà 28:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 16:1, 13; 2Sa 7:8; Sm 89:20
  • +Jẹ 49:10; 1Kr 5:2; Sm 60:7
  • +Rut 4:22
  • +1Sa 13:14; 16:11, 12

1 Kíróníkà 28:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 3:1-9
  • +1Kr 22:9
  • +1Kr 17:14; 2Kr 1:8

1 Kíróníkà 28:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:13, 14

1 Kíróníkà 28:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 17:13, 14; Sm 72:8
  • +Di 12:1; 1Ọb 6:12

1 Kíróníkà 28:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 6:3

1 Kíróníkà 28:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn tó pa pọ̀.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ìmúratán.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:12
  • +1Sa 16:7; 1Kr 29:17; Owe 17:3; Ifi 2:23
  • +Di 31:21; Sm 139:2
  • +Mt 7:7; Heb 11:6; Jem 4:8
  • +Di 31:17; 2Kr 15:2; Heb 10:38

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 58

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2015, ojú ìwé 14

    11/1/2010, ojú ìwé 30

    10/15/2008, ojú ìwé 7

    2/15/2005, ojú ìwé 19

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 242-243

1 Kíróníkà 28:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gọ̀bì.”

  • *

    Tàbí “ilé ètùtù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 8:5
  • +2Kr 3:4
  • +Le 16:2; 1Ọb 6:19

1 Kíróníkà 28:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹ̀mí.”

  • *

    Tàbí “yà sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:36; 7:12
  • +1Kr 9:26; 26:20

1 Kíróníkà 28:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 24:1

1 Kíróníkà 28:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 4:7

1 Kíróníkà 28:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 4:8, 19

1 Kíróníkà 28:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:48, 50

1 Kíróníkà 28:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:48
  • +Sm 18:10
  • +Ẹk 25:20; 1Sa 4:4; 1Ọb 6:23

1 Kíróníkà 28:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:9, 40
  • +1Kr 28:11

1 Kíróníkà 28:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 31:6; Joṣ 1:6, 9; Ro 8:31
  • +Joṣ 1:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    9/2017, ojú ìwé 28-29, 32

1 Kíróníkà 28:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 24:1
  • +1Kr 24:20
  • +Ẹk 36:1, 2
  • +1Kr 22:17; 28:1

Àwọn míì

1 Kíró. 28:11Kr 27:1
1 Kíró. 28:1Ẹk 18:25
1 Kíró. 28:11Kr 27:25, 29
1 Kíró. 28:11Kr 3:1-9
1 Kíró. 28:11Kr 11:10
1 Kíró. 28:2Sm 132:3-5
1 Kíró. 28:21Kr 22:2-4
1 Kíró. 28:31Kr 17:4
1 Kíró. 28:31Kr 22:7, 8
1 Kíró. 28:41Sa 16:1, 13; 2Sa 7:8; Sm 89:20
1 Kíró. 28:4Jẹ 49:10; 1Kr 5:2; Sm 60:7
1 Kíró. 28:4Rut 4:22
1 Kíró. 28:41Sa 13:14; 16:11, 12
1 Kíró. 28:51Kr 3:1-9
1 Kíró. 28:51Kr 22:9
1 Kíró. 28:51Kr 17:14; 2Kr 1:8
1 Kíró. 28:62Sa 7:13, 14
1 Kíró. 28:71Kr 17:13, 14; Sm 72:8
1 Kíró. 28:7Di 12:1; 1Ọb 6:12
1 Kíró. 28:8Di 6:3
1 Kíró. 28:9Di 10:12
1 Kíró. 28:91Sa 16:7; 1Kr 29:17; Owe 17:3; Ifi 2:23
1 Kíró. 28:9Di 31:21; Sm 139:2
1 Kíró. 28:9Mt 7:7; Heb 11:6; Jem 4:8
1 Kíró. 28:9Di 31:17; 2Kr 15:2; Heb 10:38
1 Kíró. 28:11Heb 8:5
1 Kíró. 28:112Kr 3:4
1 Kíró. 28:11Le 16:2; 1Ọb 6:19
1 Kíró. 28:121Ọb 6:36; 7:12
1 Kíró. 28:121Kr 9:26; 26:20
1 Kíró. 28:131Kr 24:1
1 Kíró. 28:152Kr 4:7
1 Kíró. 28:162Kr 4:8, 19
1 Kíró. 28:171Ọb 7:48, 50
1 Kíró. 28:181Ọb 7:48
1 Kíró. 28:18Sm 18:10
1 Kíró. 28:18Ẹk 25:20; 1Sa 4:4; 1Ọb 6:23
1 Kíró. 28:19Ẹk 25:9, 40
1 Kíró. 28:191Kr 28:11
1 Kíró. 28:20Di 31:6; Joṣ 1:6, 9; Ro 8:31
1 Kíró. 28:20Joṣ 1:5
1 Kíró. 28:211Kr 24:1
1 Kíró. 28:211Kr 24:20
1 Kíró. 28:21Ẹk 36:1, 2
1 Kíró. 28:211Kr 22:17; 28:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kíróníkà 28:1-21

Kíróníkà Kìíní

28 Nígbà náà, Dáfídì kó gbogbo ìjòyè Ísírẹ́lì jọ sí Jerúsálẹ́mù, àwọn ni: àwọn ìjòyè ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn olórí àwọn àwùjọ+ tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ àwọn olórí tó ń bójú tó gbogbo ohun ìní àti àwọn ẹran ọ̀sìn ọba+ àti ti àwọn ọmọ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn ọkùnrin tó jẹ́ akíkanjú àti ọ̀jáfáfá.+ 2 Ìgbà náà ni Ọba Dáfídì dìde dúró, ó sì sọ pé:

“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin arákùnrin mi àti ẹ̀yin èèyàn mi. Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi láti kọ́ ilé tó máa jẹ́ ibi ìsinmi fún àpótí májẹ̀mú Jèhófà, tí á sì jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ fún Ọlọ́run wa,+ mo sì ti ṣètò sílẹ̀ láti kọ́ ọ.+ 3 Àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún mi pé, ‘O ò ní kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ nítorí ọkùnrin ogun ni ọ́, o sì ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.’+ 4 Síbẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì yàn mí nínú gbogbo ilé bàbá mi láti di ọba lórí Ísírẹ́lì títí láé,+ nítorí ó yan Júdà ṣe aṣáájú,+ nínú gbogbo ilé Júdà, ó yan ilé bàbá mi,+ nínú gbogbo ọmọ bàbá mi, èmi ni ó fọwọ́ sí, láti fi mí jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ 5 Nínú gbogbo àwọn ọmọ mi, torí àwọn ọmọ tí Jèhófà fún mi pọ̀,+ ó yan Sólómọ́nì+ ọmọ mi láti jókòó sórí ìtẹ́ ìjọba Jèhófà lórí Ísírẹ́lì.+

6 “Ó sọ fún mi pé, ‘Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa kọ́ ilé mi àti àwọn àgbàlá mi, nítorí mo ti yàn án ṣe ọmọ mi, màá sì di bàbá rẹ̀.+ 7 Màá fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí láé+ tó bá pinnu láti máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìdájọ́+ mi mọ́, bí ó ti ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́.’ 8 Torí náà, mò ń sọ fún yín lójú gbogbo Ísírẹ́lì, ìyẹn ìjọ Jèhófà àti ní etí Ọlọ́run wa pé: Ẹ rí i pé ẹ mọ gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ilẹ̀ dáradára+ náà lè di tiyín, kí ẹ sì lè fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún tó máa wà títí láé fún àwọn ọmọ yín.

9 “Ìwọ Sólómọ́nì ọmọ mi, mọ Ọlọ́run bàbá rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn*+ àti inú dídùn* sìn ín, nítorí gbogbo ọkàn ni Jèhófà ń wá,+ ó sì ń fi òye mọ gbogbo èrò àti ìfẹ́ ọkàn.+ Tí o bá wá a, á jẹ́ kí o rí òun,+ àmọ́ tí o bá fi í sílẹ̀, á kọ̀ ẹ́ sílẹ̀ títí láé.+ 10 Ní báyìí, wò ó, Jèhófà ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé kan tó máa jẹ́ ibi mímọ́. Jẹ́ onígboyà kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.”

11 Lẹ́yìn náà, Dáfídì fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ní àwòrán ìkọ́lé+ ti ibi àbáwọlé*+ àti ti àwọn ilé rẹ̀, àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí, àwọn yàrá orí òrùlé, àwọn yàrá inú àti ti ilé ìbòrí ìpẹ̀tù.*+ 12 Ó fún un ní àwòrán ìkọ́lé gbogbo ohun tí a fi hàn án nípa ìmísí* nípa àwọn àgbàlá+ ilé Jèhófà, ti gbogbo àwọn yàrá ìjẹun tó yí i ká, ti àwọn ibi ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti ti àwọn ibi ìṣúra tí wọ́n ń kó àwọn ohun tí a sọ di* mímọ́+ sí; 13 bákan náà, ó sọ fún un nípa àwọn àwùjọ àwọn àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì, gbogbo iṣẹ́ tó jẹ́ iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà àti gbogbo nǹkan tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà; 14 ó tún fún un ní ìwọ̀n wúrà, wúrà gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n á fi ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn, ìwọ̀n gbogbo nǹkan èlò fàdákà àti gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n á fi ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn; 15 bákan náà, ó fún un ní ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà+ àti àwọn fìtílà wúrà wọn, ìwọ̀n oríṣiríṣi ọ̀pá fìtílà àti àwọn fìtílà wọn àti ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà fàdákà, ti ọ̀pá fìtílà kọ̀ọ̀kan àti àwọn fìtílà rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n; 16 ó tún fún un ní ìwọ̀n wúrà àwọn tábìlì búrẹ́dì onípele,*+ ti tábìlì kọ̀ọ̀kan àti fàdákà tí wọ́n á fi ṣe àwọn tábìlì fàdákà, 17 ó fún un ní ìwọ̀n àwọn àmúga, àwọn abọ́, àwọn ṣágo ògidì wúrà àti ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn abọ́ kéékèèké wúrà+ àti ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan abọ́ kéékèèké fàdákà. 18 Ó tún fún un ní ìwọ̀n wúrà tí a yọ́ mọ́ fún pẹpẹ tùràrí+ àti fún àwòrán kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ ìyẹn, àwọn kérúbù+ wúrà tí wọ́n na ìyẹ́ apá wọn bo orí àpótí májẹ̀mú Jèhófà. 19 Dáfídì sọ pé: “Ọwọ́ Jèhófà wà pẹ̀lú mi, ó sì fún mi ní ìjìnlẹ̀ òye kí n lè kọ+ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àwòrán ìkọ́lé+ náà sílẹ̀.”

20 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Má bẹ̀rù, má sì jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ.+ Kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀,+ àmọ́ ó máa wà pẹ̀lú rẹ títí gbogbo iṣẹ́ tó jẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà á fi parí. 21 Àwùjọ àwọn àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì+ nìyí fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́. O ní àwọn òṣìṣẹ́ tó ti múra tán, tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀jáfáfá láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí,+ o tún ní àwọn ìjòyè+ àti gbogbo àwọn èèyàn tó máa ṣe gbogbo ohun tí o bá ní kí wọ́n ṣe.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́