ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Sólómọ́nì bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ (1-11)

      • Àdúrà tí Sólómọ́nì fi ṣí tẹ́ńpìlì (12-42)

2 Kíróníkà 6:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:21; 1Ọb 8:12, 13; Sm 97:2

2 Kíróníkà 6:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 132:13, 14

2 Kíróníkà 6:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:14-21

2 Kíróníkà 6:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 19

2 Kíróníkà 6:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:5, 6

2 Kíróníkà 6:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 48:1
  • +2Sa 7:8; 1Kr 28:4

2 Kíróníkà 6:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:2; 1Ọb 5:3

2 Kíróníkà 6:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọmọ rẹ, tó máa jáde láti abẹ́ rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 17:4

2 Kíróníkà 6:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 28:5; 29:23
  • +1Kr 17:11

2 Kíróníkà 6:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 40:20; 1Ọb 8:9

2 Kíróníkà 6:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:22

2 Kíróníkà 6:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbàgede.”

  • *

    Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:36
  • +1Ọb 8:54

2 Kíróníkà 6:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:9; 1Ọb 8:23-26

2 Kíróníkà 6:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:6
  • +2Sa 7:12, 13; 1Kr 22:10

2 Kíróníkà 6:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 132:12
  • +1Ọb 2:4

2 Kíróníkà 6:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:48
  • +2Kr 2:6; Ais 40:12; Iṣe 17:24
  • +1Ọb 8:27-30; Ais 66:1

2 Kíróníkà 6:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 26:2

2 Kíróníkà 6:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 6:10
  • +2Ọb 19:20; 2Kr 30:27
  • +2Kr 7:12-14; Mik 7:18

2 Kíróníkà 6:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ sì gégùn-ún fún un.” Ìyẹn, ìbúra tó ní ègún nínú gẹ́gẹ́ bí ìyà tó máa jẹ ẹni tó bá búra èké tàbí tó dalẹ̀.

  • *

    Ní Héb., “ègún.”

  • *

    Ní Héb., “ègún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:31, 32

2 Kíróníkà 6:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “olódodo.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 34:11
  • +Ais 3:10, 11; Isk 18:20

2 Kíróníkà 6:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:14, 17; Joṣ 7:8, 11; Ond 2:14
  • +Da 9:3, 19
  • +Ẹsr 9:5
  • +1Ọb 8:33, 34

2 Kíróníkà 6:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 57:15
  • +Sm 106:47

2 Kíróníkà 6:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fìyà jẹ wọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:19; Di 28:23
  • +Isk 14:13
  • +1Ọb 8:35, 36

2 Kíróníkà 6:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:20, 21; 54:13
  • +1Ọb 18:1

2 Kíróníkà 6:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tata.”

  • *

    Ní Héb., “ní ilẹ̀ àwọn ẹnubodè rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Rut 1:1; 2Ọb 6:25
  • +Le 26:14, 16; Di 28:21, 22
  • +Emọ 4:9; Hag 2:17
  • +Di 28:38; Joẹ 1:4
  • +2Kr 12:2; 32:1
  • +1Ọb 8:37-40

2 Kíróníkà 6:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 20:5, 6
  • +2Kr 33:13
  • +Owe 14:10
  • +Da 6:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2010, ojú ìwé 11

    3/15/2008, ojú ìwé 12-13

    1/1/2004, ojú ìwé 32

    4/15/1997, ojú ìwé 4

2 Kíróníkà 6:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 63:15
  • +Sm 130:4
  • +1Sa 16:7; 1Kr 28:9; Jer 11:20; 17:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2010, ojú ìwé 11

    3/15/2008, ojú ìwé 12-13

    1/1/2004, ojú ìwé 32

2 Kíróníkà 6:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ohun tó gbọ́ nípa rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:48; Rut 1:16; 2Ọb 5:15; Ais 56:6, 7; Iṣe 8:27
  • +1Ọb 8:41-43

2 Kíróníkà 6:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 22:27; 46:10

2 Kíróníkà 6:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 31:2; Joṣ 8:1; Ond 1:1, 2; 1Sa 15:3
  • +2Kr 14:11; 20:5, 6
  • +1Ọb 8:44, 45

2 Kíróníkà 6:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 37:36

2 Kíróníkà 6:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 130:3; Onw 7:20; Ro 3:23
  • +Le 26:34; 1Ọb 8:46-50; Da 9:7

2 Kíróníkà 6:37

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:40; Ẹsr 9:6; Ne 1:6; Sm 106:6; Da 9:5

2 Kíróníkà 6:38

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 7:3
  • +Di 30:1-3; Da 9:2, 3
  • +Da 6:10

2 Kíróníkà 6:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 51:36, 37

2 Kíróníkà 6:40

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “nípa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 7:15; 16:9; Sm 65:2; Ais 37:17

2 Kíróníkà 6:41

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 28:2
  • +Sm 65:4; 132:8-10

2 Kíróníkà 6:42

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “má ṣe yí ojú ẹni àmì òróró rẹ kúrò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 1:34; Sm 18:50
  • +Iṣe 13:34

Àwọn míì

2 Kíró. 6:1Ẹk 20:21; 1Ọb 8:12, 13; Sm 97:2
2 Kíró. 6:2Sm 132:13, 14
2 Kíró. 6:31Ọb 8:14-21
2 Kíró. 6:5Di 12:5, 6
2 Kíró. 6:6Sm 48:1
2 Kíró. 6:62Sa 7:8; 1Kr 28:4
2 Kíró. 6:72Sa 7:2; 1Ọb 5:3
2 Kíró. 6:91Kr 17:4
2 Kíró. 6:101Kr 28:5; 29:23
2 Kíró. 6:101Kr 17:11
2 Kíró. 6:11Ẹk 40:20; 1Ọb 8:9
2 Kíró. 6:121Ọb 8:22
2 Kíró. 6:131Ọb 6:36
2 Kíró. 6:131Ọb 8:54
2 Kíró. 6:14Di 7:9; 1Ọb 8:23-26
2 Kíró. 6:151Ọb 3:6
2 Kíró. 6:152Sa 7:12, 13; 1Kr 22:10
2 Kíró. 6:16Sm 132:12
2 Kíró. 6:161Ọb 2:4
2 Kíró. 6:18Iṣe 7:48
2 Kíró. 6:182Kr 2:6; Ais 40:12; Iṣe 17:24
2 Kíró. 6:181Ọb 8:27-30; Ais 66:1
2 Kíró. 6:20Di 26:2
2 Kíró. 6:21Da 6:10
2 Kíró. 6:212Ọb 19:20; 2Kr 30:27
2 Kíró. 6:212Kr 7:12-14; Mik 7:18
2 Kíró. 6:221Ọb 8:31, 32
2 Kíró. 6:23Job 34:11
2 Kíró. 6:23Ais 3:10, 11; Isk 18:20
2 Kíró. 6:24Le 26:14, 17; Joṣ 7:8, 11; Ond 2:14
2 Kíró. 6:24Da 9:3, 19
2 Kíró. 6:24Ẹsr 9:5
2 Kíró. 6:241Ọb 8:33, 34
2 Kíró. 6:25Ais 57:15
2 Kíró. 6:25Sm 106:47
2 Kíró. 6:26Le 26:19; Di 28:23
2 Kíró. 6:26Isk 14:13
2 Kíró. 6:261Ọb 8:35, 36
2 Kíró. 6:27Ais 30:20, 21; 54:13
2 Kíró. 6:271Ọb 18:1
2 Kíró. 6:28Rut 1:1; 2Ọb 6:25
2 Kíró. 6:28Le 26:14, 16; Di 28:21, 22
2 Kíró. 6:28Emọ 4:9; Hag 2:17
2 Kíró. 6:28Di 28:38; Joẹ 1:4
2 Kíró. 6:282Kr 12:2; 32:1
2 Kíró. 6:281Ọb 8:37-40
2 Kíró. 6:292Kr 20:5, 6
2 Kíró. 6:292Kr 33:13
2 Kíró. 6:29Owe 14:10
2 Kíró. 6:29Da 6:10
2 Kíró. 6:30Ais 63:15
2 Kíró. 6:30Sm 130:4
2 Kíró. 6:301Sa 16:7; 1Kr 28:9; Jer 11:20; 17:10
2 Kíró. 6:32Ẹk 12:48; Rut 1:16; 2Ọb 5:15; Ais 56:6, 7; Iṣe 8:27
2 Kíró. 6:321Ọb 8:41-43
2 Kíró. 6:33Sm 22:27; 46:10
2 Kíró. 6:34Nọ 31:2; Joṣ 8:1; Ond 1:1, 2; 1Sa 15:3
2 Kíró. 6:342Kr 14:11; 20:5, 6
2 Kíró. 6:341Ọb 8:44, 45
2 Kíró. 6:35Ais 37:36
2 Kíró. 6:36Sm 130:3; Onw 7:20; Ro 3:23
2 Kíró. 6:36Le 26:34; 1Ọb 8:46-50; Da 9:7
2 Kíró. 6:37Le 26:40; Ẹsr 9:6; Ne 1:6; Sm 106:6; Da 9:5
2 Kíró. 6:381Sa 7:3
2 Kíró. 6:38Di 30:1-3; Da 9:2, 3
2 Kíró. 6:38Da 6:10
2 Kíró. 6:39Jer 51:36, 37
2 Kíró. 6:402Kr 7:15; 16:9; Sm 65:2; Ais 37:17
2 Kíró. 6:411Kr 28:2
2 Kíró. 6:41Sm 65:4; 132:8-10
2 Kíró. 6:421Ọb 1:34; Sm 18:50
2 Kíró. 6:42Iṣe 13:34
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 6:1-42

Kíróníkà Kejì

6 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì sọ̀rọ̀, ó ní: “Jèhófà sọ pé inú ìṣúdùdù tó kàmàmà+ ni òun á máa gbé. 2 Ní báyìí, mo ti kọ́ ilé ológo kan fún ọ, ibi tó fìdí múlẹ̀ tí wàá máa gbé títí láé.”+

3 Lẹ́yìn náà, ọba yíjú pa dà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, bí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ṣe wà ní ìdúró.+ 4 Ó sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó fi ẹnu ara rẹ̀ ṣèlérí fún Dáfídì bàbá mi, tó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un ṣẹ, tó sọ pé, 5 ‘Láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn èèyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mi ò yan ìlú kankan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí màá kọ́ ilé sí fún orúkọ mi, kí ó lè máa wà níbẹ̀,+ mi ò sì yan ọkùnrin kankan láti jẹ́ aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. 6 Ṣùgbọ́n mo ti yan Jerúsálẹ́mù+ kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀, mo sì ti yan Dáfídì láti ṣe olórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’+ 7 Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Dáfídì bàbá mi pé kí ó kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 8 Àmọ́, Jèhófà sọ fún Dáfídì bàbá mi pé, ‘Ìfẹ́ ọkàn rẹ ni pé kí o kọ́ ilé fún orúkọ mi, ó sì dára bó ṣe ń wù ọ́ yìí. 9 Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ́ ló máa kọ́ ilé náà, ọmọ tí o máa bí* ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+ 10 Jèhófà ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, torí mo ti jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì,+ bí Jèhófà ti ṣèlérí.+ Mo tún kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, 11 ibẹ̀ ni mo sì gbé Àpótí tí májẹ̀mú+ Jèhófà wà nínú rẹ̀ sí, èyí tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá.”

12 Ó wá dúró níwájú pẹpẹ Jèhófà ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ síwájú.+ 13 (Sólómọ́nì ṣe pèpéle bàbà, ó sì gbé e sí àárín àgbàlá.*+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* márùn-ún, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; ó sì dúró sórí rẹ̀.) Ó kúnlẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run,+ 14 ó wá sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tó dà bí rẹ ní ọ̀run tàbí ní ayé, ò ń pa májẹ̀mú mọ́, o sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tó ń fi gbogbo ọkàn+ wọn rìn níwájú rẹ. 15 O ti mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ.+ Ẹnu rẹ lo fi ṣe ìlérí náà, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú un ṣẹ lónìí yìí.+ 16 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ, nígbà tí o sọ pé: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ níwájú mi tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí àwọn ọmọ rẹ bá ṣáà ti ń fiyè sí ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì ń rìn nínú òfin mi+ bí ìwọ náà ṣe rìn níwájú mi.’+ 17 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì ṣẹ.

18 “Àmọ́, ṣé Ọlọ́run á máa bá àwọn èèyàn gbé inú ayé ni?+ Wò ó! Àwọn ọ̀run, àní, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́;+ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ilé tí mo kọ́ yìí!+ 19 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, fiyè sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, kí o sì fetí sí igbe ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti àdúrà tó ń gbà níwájú rẹ. 20 Kí ojú rẹ wà lára ilé yìí tọ̀sántòru, lára ibi tí o sọ pé wàá fi orúkọ rẹ sí,+ láti fetí sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní ìdojúkọ ibí yìí. 21 Kí o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti ẹ̀bẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí,+ kí o gbọ́ láti ibi tí ò ń gbé, láti ọ̀run;+ kí o gbọ́, kí o sì dárí jì wọ́n.+

22 “Tí ẹnì kan bá ṣẹ ọmọnìkejì rẹ̀, tó mú kó búra,* tó sì mú kó wà lábẹ́ ìbúra* náà, tó bá wá síwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí+ nígbà tó ṣì wà lábẹ́ ìbúra* náà, 23 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o gbé ìgbésẹ̀, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kí o san ẹni burúkú lẹ́san, kí o sì jẹ́ kí ohun tó ṣe dà lé e lórí,+ kí o pe olódodo ní aláìṣẹ̀,* kí o sì san èrè òdodo rẹ̀ fún un.+

24 “Tí ọ̀tá bá ṣẹ́gun àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n sì pa dà wá, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga,+ tí wọ́n gbàdúrà,+ tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ nínú ilé yìí pé kí o ṣojú rere sí àwọn,+ 25 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run,+ kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jì wọ́n, kí o sì mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ tí o fún àwọn àti àwọn baba ńlá wọn.+

26 “Nígbà tí ọ̀run bá sé pa, tí òjò kò sì rọ̀  + torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga, tí wọ́n sì yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé o rẹ̀ wọ́n wálẹ̀,*+ 27 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, ìyẹn àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé wàá tọ́ wọn sí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa rìn;+ kí o sì rọ̀jò+ sórí ilẹ̀ rẹ tí o fún àwọn èèyàn rẹ láti jogún.

28 “Bí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ náà+ tàbí tí àjàkálẹ̀ àrùn+ bá jà, tí ooru tó ń jó ewéko gbẹ tàbí èbíbu+ bá wà, tí ọ̀wọ́ eéṣú tàbí ọ̀yánnú eéṣú*+ bá wà tàbí tí àwọn ọ̀tá wọn bá dó tì wọ́n ní ìlú èyíkéyìí ní ilẹ̀ náà*+ tàbí tí ìyọnu èyíkéyìí tàbí àrùn bá wáyé,+ 29 àdúrà+ èyíkéyìí tí ì báà jẹ́, ìbéèrè fún ojú rere+ èyíkéyìí tí ẹnikẹ́ni bá béèrè tàbí èyí tí gbogbo àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì bá béèrè (nítorí pé kálukú ló mọ ìṣòro rẹ̀ àti ìrora rẹ̀),+ tí wọ́n bá tẹ́ ọwọ́ wọn sí apá ibi tí ilé yìí wà,+ 30 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé,+ kí o sì dárí jì wọ́n;+ kí o san èrè fún kálukú gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ̀, nítorí pé o mọ ọkàn rẹ̀ (ìwọ nìkan lo mọ ọkàn èèyàn),+ 31 kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi gbé lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wa.

32 “Bákan náà, ní ti àjèjì tí kì í ṣe ara àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, àmọ́ tó wá láti ilẹ̀ tó jìnnà nítorí orúkọ ńlá rẹ*+ àti ọwọ́ agbára rẹ pẹ̀lú apá rẹ tó nà jáde, tí ó sì wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ilé yìí,+ 33 nígbà náà, kí o fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé, kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ,+ kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe, kí wọ́n sì mọ̀ pé a ti fi orúkọ rẹ pe ilé tí mo kọ́ yìí.

34 “Tí àwọn èèyàn rẹ bá lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà lójú ogun bí o ṣe rán wọn,+ tí wọ́n sì gbàdúrà + sí ọ ní ìdojúkọ ìlú tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+ 35 nígbà náà, kí o gbọ́ àdúrà wọn láti ọ̀run àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn.+

36 “Tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí kò sí èèyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀),+ tí inú rẹ ru sí wọn, tí o fi wọ́n sílẹ̀ fún ọ̀tá, tí àwọn tó mú wọn sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ kan, bóyá èyí tó jìnnà tàbí èyí tó wà nítòsí,+ 37 tí wọ́n bá ro inú ara wọn wò ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o ṣojú rere sí àwọn ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ ẹrú, tí wọ́n sọ pé, ‘A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣàṣìṣe; a ti ṣe ohun búburú,’+ 38 tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn+ wọn àti gbogbo ara* wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣe ẹrú,+ ìyẹn ibi tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà ní ìdojúkọ ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn àti ìlú tí o yàn+ àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ, 39 nígbà náà, láti ibi tí ò ń gbé ní ọ̀run, kí o gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn,+ kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn, kí o dárí ji àwọn èèyàn rẹ tó ṣẹ̀ ọ́.

40 “Ní báyìí, ìwọ Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, ṣí ojú rẹ, kí o sì tẹ́tí sí àdúrà tí a bá gbà ní* ibí yìí.+ 41 Torí náà, dìde, Jèhófà Ọlọ́run, wá síbi ìsinmi rẹ,+ ìwọ àti Àpótí agbára rẹ. Jèhófà Ọlọ́run, fi aṣọ ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ, sì jẹ́ kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yọ̀ nínú ohun rere.+ 42 Jèhófà Ọlọ́run, má ṣe kọ ẹni àmì òróró rẹ sílẹ̀.*+ Rántí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́