ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 11-18
Ta Ló Lè Jẹ́ Àlejò Nínú Àgọ́ Jèhófà?
Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ẹni náà jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Àti pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ó sì ń ṣègbọràn sí i. Sáàmù ìkẹẹ̀dógún [15] sọ àwọn ohun tí Jèhófà ń wò lára ẹnì kan kó tó lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.
ÀLEJÒ JÈHÓFÀ GBỌ́DỌ̀ . . .
jẹ́ oníwà títọ́
máa sọ òtítọ́, kódà látinú ọkàn rẹ̀
máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bíi tiẹ̀
máa ṣe ohun tó sọ, kódà tó bá tiẹ̀ nira láti ṣe bẹ́ẹ̀
máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́ láì máa retí ohunkóhun pa dà
ÀLEJÒ JÈHÓFÀ KÒ GBỌ́DỌ̀ . . .
jẹ́ olófòófó tàbí afọ̀rọ̀ èké bani jẹ́
máa ṣe ohun tí kò dáa sí aládùúgbò rẹ̀
máa kó àwọn ará nífà
bá àwọn tí kò sin Jèhófà tàbí tí wọ́n ń ṣe àìgbọràn sí i kẹ́gbẹ́
gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀