September 5 Sí 11
SÁÀMÙ 119
Orin 48 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Máa Rìn Nínú Òfin Jèhófà”: (10 min.)
Sm 119:1-8—Tá a bá fẹ́ ní ojúlówó ayọ̀, a gbọ́dọ̀ máa rìn nínú òfin Ọlọ́run (w05 4/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 3 àti 4)
Sm 119:33-40—Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń fún wa ní ìgboyà láti fara da àwọn ìṣòro (w05 4/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 12)
Sm 119:41-48—Tá a bá ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí á jẹ́ ká máa fi ìgboyà wàásù (w05 4/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 13 àti 14)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Sm 119:71—Àǹfààní wo la lè rí nínú ìpọ́njú? (w06 9/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 4)
Sm 119:96—Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “èmi ti rí òpin gbogbo ìjẹ́pípé”? (w06 9/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 5)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 119:73-93
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Tí Ọmọdé Kan Bá Sọ Pé Ká Wọlé”: (5 min.) Àsọyé.
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (10 min.) Tí kò bá sí ohun tó ń fẹ́ àbójútó, ẹ jíròrò ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb16 ojú ìwé 59 sí 62)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 23 ìpínrọ̀ 15 sí 29 àti àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 204
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 13 àti Àdúrà