ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 September ojú ìwé 3
  • “Máa Rìn Nínú Òfin Jèhófà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Máa Rìn Nínú Òfin Jèhófà”
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tànmọ́lẹ̀ Sí Òpópónà Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Báwo Lo Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • “Mo Mà Nífẹ̀ẹ́ Òfin Rẹ O!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 September ojú ìwé 3

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 119

“Máa Rìn Nínú Òfin Jèhófà”

Ohun tó túmọ̀ sí láti máa rìn nínú òfin Jèhófà ni pé, ká máa fi tinútinú tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Bíi ti onísáàmù náà, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn míì tó ṣègbọràn sí òfin Jèhófà, tí wọ́n sì gbára lé e.

Onísáàmù náà ń fi ọ̀pá rìn

Tá a bá fẹ́ ní ojúlówó ayọ̀, a gbọ́dọ̀ máa rìn nínú òfin Ọlọ́run

119:1-8

Jóṣúà ń ka àkájọ ìwé

Jóṣúà fi hàn pé òun gbára lé ìtọ́ni Jèhófà pátápátá. Ó mọ̀ pé tí òun bá fẹ́ ṣàṣeyọrí kí òun sì tún láyọ̀, òun gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn òun

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń fún wa ní ìgboyà láti fara da àwọn ìṣòro

119:33-40

Jeremáyà ń gbàdúrà

Jeremáyà ní ìgboyà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà ìṣòro. Kò kó àwọn nǹkan tara jọ, ó sì lo ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀

Tá a bá ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí á jẹ́ ká máa fi ìgboyà wàásù

119:41-48

Pọ́ọ̀lù ń wàásù fún Gómìnà Fẹ́lí ìsì

Pọ́ọ̀lù kì í bẹ̀rù láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni. Ó dá a lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́ nígbà tó fìgboyà wàásù fún Gómìnà Fẹ́líìsì

Onísáàmù náà ń fi ọ̀pá rìn

Àwọn ibo ni mo ti lè fìgboyà wàásù fún àwọn ẹlòmíì?

  • Nílé ìwé

  • Níbi iṣẹ́

  • Nínú ìdílé

  • Níbòmíì

Bí wọ́n ṣe máa ń to ọ̀rọ̀ ewì tàbí álífábẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ṣe kọ Sáàmù 119. Ó lè jẹ́ torí kéèyàn lè tètè máa rántí ni. Ìsọ̀rí méjìlélógún [22] ni sáàmù náà ní, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ní ẹsẹ mẹ́jọ nínú. Lẹ́tà álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù kan náà ló bẹ̀rẹ̀ àwọn ẹsẹ tó wà nínú ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé lẹ́tà méjìlélógún [22] ni álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù ní, ẹsẹ 176 ni sáàmù yìí ní, èyí ló sì mú kó jẹ́ sáàmù tó gùn jù lọ nínú Bíbélì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́