Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
NOVEMBER 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÒWE 27-31
it-2 ojú ìwé 1183 ìpínrọ̀ 6
Ìyàwó
Àpèjúwe Ìyàwó Rere. Ìwé Òwe orí 31 sọ nípa obìnrin tó jẹ́ ìyàwó rere pé ó máa ń láyọ̀, ó sì máa ń ṣiṣẹ́ kára. Irú obìnrin bẹ́ẹ̀ níye lórí lójú ọkọ rẹ̀ ju iyùn lọ. Ọkọ rẹ̀ sì máa ń fọkàn tán an. Òṣìṣẹ́ kára nirú obìnrin bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́. Lára àwọn iṣẹ́ tó máa ń ṣe ni aṣọ híhun fún ìdílé rẹ̀, ó máa ń ra àwọn ohun tí wọ́n nílò nínú ilé, ó sì máa ń ṣiṣẹ́ nínú ọ̀gbà àjàrà. Ó tún máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ láti bójú tó ilé, ó máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́, ó máa ń pèsè aṣọ tó bójú mu fún ìdílé rẹ̀, kódà ó máa ń mówó wálé látara iṣẹ́ ọwọ́ tó ń ṣe. Láfikún sí i, ó máa ń múra sílẹ̀ de ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì tó ṣeé ṣe kó wáyé, ó máa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti ọ̀rọ̀ rere, ó máa ńṣe iṣẹ́ rere, ó sì ní ìbẹ̀rù Jèhófà. Èyí máa ń jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ yìn ín, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ọkọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ lórúkọ rere láwùjọ. Kò sí àní-àní pé ẹni tó bá fẹ́ irú obìnrin bẹ́ẹ̀ níyàwó ti rí ohun rere, ó sì ti rí ìfẹ́ rere gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.—Owe 18:22.