Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
DECEMBER 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 1-5
‘Ẹ Jẹ́ Kí A Gòkè Lọ sí Òkè Ńlá Jèhófà’
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:8, 9—Ọ̀nà wo la ó gbà fi ọmọbìnrin Síónì “sílẹ̀ bí àtíbàbà inú ọgbà àjàrà, bí ahéré alóre inú àwọn pápá apálá”? Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, nígbà tí Asíríà bá gbógun wá, ńṣe ló máa dà bíi pé Jerúsálẹ́mù kò lè bọ́ lọ́wọ́ wọn rárá, á dà bí àtíbàbà inú ọgbà àjàrà kan tàbí bí ahéré kan tó lè tètè wó lulẹ̀, tó wà nínú oko apálá. Àmọ́ Jèhófà ran Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́, kò jẹ́ kó dà bíi Sódómù àti Gòmórà.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
1:18—Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà: “Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa”? Èyí kì í ṣe pé Ọlọ́run ń pe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé káwọn jọ sọ̀rọ̀ káwọn sì jọ fẹnu kò síbì kan nípa jíjùmọ̀ yanjú ọ̀ràn kan ní ìtùnbí-ìnùbí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń tọ́ka sí ni pípè tí Jèhófà onídàájọ́ òdodo ń pe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti fún wọn láǹfààní láti yí padà, kí wọ́n sì wẹ ara wọn mọ́.
it-2-E ojú ìwé 761 ìpínrọ̀ 3
Ìpadàrẹ́
Àwọn ìgbésẹ̀ téèyàn gbọ́dọ̀ gbé kó lè pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. Nígbà tó jẹ́ pé àwa èèyàn la rú òfin Ọlọ́run, tá ò sì jáwọ́, àwa ló yẹ ká wá báa ṣe máa pa dà bá Ọlọ́run rẹ́, kì í ṣe Ọlọ́run ló máa wá bó ṣe máa bá wa rẹ́. (Sm 51:1-4) Tó bá dọ̀rọ̀ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ohun tó tọ́, àwa èèyàn ò dójú ìlà ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run ò ní yí òfin rẹ̀ lórí ohun tó dáa pa dà nítorí tiwa. (Ais 55:6-11; Mal 3:6; fi wé Jak 1:17.) Torí náà, láti pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ kì í ṣe ohun téèyàn ń ná bí ẹni nájà, tàbí ká jọ máa tàtagbà ọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run débi táá fi wá ronú pé kí òun dẹ òfin lójú fún wa. (Fi wé Job 40:1, 2, 6-8; Ais 40:13, 14.) Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan tú Aísáyà 1:18 sí, “OLUWA ní, ‘Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀.’ ” (KJ; AT; JP; RS), àmọ́ èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ bọ́ sójú ẹ̀ gan-an ni: “ ‘Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ [“ká yanjú aáwọ̀,” Ro] láàárín wa,’ ni Jèhófà wí.” Àwa èèyàn la fà á tá ò fi ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, kì í ṣe Ọlọ́run ló fà á.—Fi wé Isk 18:25, 29-32.
DECEMBER 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 6-10
“Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Tó Ní Ìmúṣẹ”
Bá A Ṣe Lè Nírètí Nínú Ayé Tó Kún fún Ìpọ́njú
Ohun Tó Dájú Pé Ó Máa fún Wa Nírètí
Jésù Kristi sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’ ” (Mátíù 6:9, 10) Ìjọba ọ̀run yìí tí Jésù Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀ ni Ọlọ́run máa lò láti fi hàn pé òun, Jèhófà, ni Ọba Aláṣẹ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.—Sáàmù 2:7-12; Dáníẹ́lì 7:13, 14.
Onírúurú nǹkan tó ń kó ìpayà bá àwa ọmọ èèyàn lónìí fi hàn kedere pé a nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, pé kó bá wa dá sí ọ̀rọ̀ wa. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ aráyé! Ní báyìí, Ọlọ́run ti fi Jésù Kristi jẹ Mèsáyà Ọba, ó sì fún un láṣẹ pé kó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun, Jèhófà, ló tọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, kó sì tún ya orúkọ òun sí mímọ́. (Mátíù 28:18) Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ ayé, yóò sì mú gbogbo ohun tó ń fa ìbẹ̀rù àti àníyàn kúrò. Aísáyà 9:6 sọ àwọn ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ Alákòóso tó lè mú àwọn ohun tí ò jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ kúrò. Bí àpẹẹrẹ, ó pe Jésù ní “Baba Ayérayé,” “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn” àti “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.”
Ìwọ wo orúkọ fífanimọ́ra tí ẹsẹ Bíbélì yìí fún Jésù, ìyẹn “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” ó ní agbára àti àṣẹ láti fún àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé lọ́lá ẹbọ tó fẹ̀mí ara rẹ̀ rú. Kì í ṣe pé ó lágbára rẹ̀ nìkan ni, ó tún jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn onígbọràn máa bọ́ nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé téèyàn jogún látọ̀dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́. (Mátíù 20:28; Róòmù 5:12; 6:23) Kristi tún máa lo àṣẹ tí Ọlọ́run fún un láti jí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kú dìde.—Jòhánù 11:25, 26.
Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun jẹ́ “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn.” Ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní àti òye àrà ọ̀tọ̀ tó ní nípa ẹ̀dá èèyàn jẹ́ kó mọ bó ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro téèyàn máa ń ní. “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn” náà ló ṣì jẹ́ látìgbà tí Ọlọ́run ti gbé e gorí ìtẹ́ lọ́run, òun sì ni Jèhófà ń lò ní pàtàkì láti bá aráyé sọ̀rọ̀. Àwọn ìtọ́ni Jésù tó wà nínú Bíbélì kún fún ọgbọ́n, kò sì lábùkù kankan. Tó o bá mọ àwọn ìtọ́ni wọ̀nyí tó o sì gbà pé wọ́n wúlò, o ò ní wà láìní ìrètí, wàá sì bọ́ nínú ìbẹ̀rùbojo.
Aísáyà 9:6 tún sọ pé Jésù jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Ipò yìí ni Kristi yóò ti lo agbára rẹ̀ láìpẹ́ láti mú gbogbo kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ láwùjọ kúrò, ì báà jẹ́ èyí tí ètò ìṣèlú tàbí ètò ọrọ̀ ajé ń fà. Ọ̀nà wo ló máa gbà ṣèyẹn? Yóò ṣe èyí nípa mímú kí ìjọba kan ṣoṣo tó jẹ́ ti àlàáfíà, ìyẹn Ìjọba Mèsáyà, máa ṣàkóso gbogbo aráyé.—Dáníẹ́lì 2:44.
Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso ayé, àlàáfíà yóò wà kárí ayé títí láé. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú? Aísáyà 11:9 sọ ọ́, ó ní: “Wọn [ìyẹn àwọn tí yóò wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run] kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátá yóò ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, gbogbo wọn ni yóò sì máa ṣègbọràn sí i. Ǹjẹ́ èyí kò múnú rẹ dùn? Tó bá múnú rẹ dùn, má ṣe jáfara láti ní “ìmọ̀ Jèhófà” tó ṣeyebíye.
Ó lè ní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run, èyí tó ń mú kéèyàn nígbàgbọ́ tó sì ń fúnni níyè tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní àti nípa àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì pé òun máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Nítorí náà, a rọ̀ ọ́ pé kó o tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn ládùúgbò rẹ lọ́fẹ̀ẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù, wàá sì ní ìrètí tòótọ́ nínú ayé tí ìṣòro kúnnú rẹ̀ yìí.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
7:3, 4—Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo Áhásì Ọba tó jẹ́ ẹni burúkú? Àwọn Ọba ilẹ̀ Síríà àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ti gbìmọ̀ pọ̀ láti mú Áhásì Ọba kúrò lórí oyè kí wọ́n sì fi ẹni tí wọ́n á lè máa darí bó ṣe wù wọ́n rọ́pò rẹ̀, ìyẹn ọmọkùnrin Tábéélì, tí kì í ṣe àtọmọdọ́mọ Dáfídì. Ètekéte Èṣù yìí yóò ṣèdíwọ́ fún májẹ̀mú Ìjọba tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá. Kí ohunkóhun má bàa ṣẹlẹ̀ sí ìran tí “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” yóò ti wá ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Áhásì.—Aísáyà 9:6.
it-1-E ojú ìwé 1219 ìpínrọ̀ 5 àti 6
Aísáyà
Kí wọ́n tó lóyún ọmọkùnrin mí ì tí Aísáyà bí ni wọ́n ti sọ orúkọ táá máa jẹ́, wọ́n sì kọ orúkọ ọmọ náà sára wàláà kan níṣojú àwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́, kí wọ́n lè jẹ́rìí sí i. Wọ́n gbà láti ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí títí dìgbà tí wọ́n máa fi bí ọmọ náà, ìgbà yẹn làwọn ẹlẹ́rìí náà máa tó lè wá jẹ́rìí sí ohun tí wòlí ì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọmọ náà, kí wọ́n lè fi hàn pé òótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ náà. Orúkọ tí Ọlọ́run ní kí wọ́n sọ ọmọ náà ni Maheri-ṣalali-háṣí-básì, tó túmọ̀ sí “Tètè, Ohun Ìfiṣèjẹ Rẹpẹtẹ! Ó Yára Kánkán Láti Piyẹ́ Ohun Púpọ̀; tàbí, Tètè Kó Ohun Ìfiṣèjẹ Rẹpẹtẹ, Ó Yára Kánkán Láti Piyẹ́ Ohun Púpọ̀.” Wọ́n ti sọ pé kí ọmọ yìí tó lè pe, “Baba mi!’ àti ‘Ìyá mi!” jáde lẹ́nu, gbogbo ìhàlẹ̀ àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí ìlú Síríà àti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti Ísírẹ́lì ń ṣe sí ìlú Júdà máa ti dópin.—Ais 8:1-4.
Àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé ìtura máa tó dé bá ìlú Júdà; bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn torí àwọn Ásíríà wá dá sí ọ̀rọ̀ náà nípa dídojú ìjà kọ Résínì ọba Síríà àti Pékà ọba Ísírẹ́lì tó wá láti kógun ja àwọn ará Júdà. Àwọn Asíríà gba ilẹ̀ Damásíkù, nígbà tó yá, lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni wọ́n pa ìjọba Ísírẹ́lì run, wọ́n sì fi wọ́n ṣèjẹ gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ orúkọ ọmọ náà. (2Ọb 16:5-9; 17:1-6) Àmọ́, dípò tí Áhásì ọba ì bá fi gbẹ́kẹ̀ lẹ́ Jèhófà, ńṣe ló lọ́ fún ọba Asíríà ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kó lè gbèjà rẹ̀, kó sì bá àwọn Síríà àti Ísírẹ́lì jagun. Fún ohun tó ṣe yìí, Jèhófà jẹ́ kí àwọn Asíríà di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ fún àwọn Júdà, wọ́n sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn títí dé Jerúsálẹ́mù alára, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ṣe kìlọ̀ tẹ́lẹ̀.—Ais 7:17-20.
DECEMBER 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 11-16
“Ilẹ̀ Ayé Yóò Kún fún Ìmọ̀ Jèhófà”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
11:1, 10—Báwo ni Jésù Kristi ṣe lè jẹ́ ‘ẹ̀ka igi kan tó yọ láti ara kùkùté Jésè’ síbẹ̀ kó tún jẹ́ “gbòǹgbò Jésè”? (Róòmù 15:12) “Láti ara kùkùté Jésè” ni Jésù ti wá. Ó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jésè nípasẹ̀ Dáfídì tó jẹ́ ọmọ Jésè. (Mátíù 1:1-6; Lúùkù 3:23-32) Àmọ́ o, lẹ́yìn tí Jésù di ọba, ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ yí padà. Nítorí pé Ọlọ́run ti fún Jésù ní agbára àti àṣẹ láti fún àwọn tó bá ṣègbọràn ní ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé, ó wá tipa bẹ́ẹ̀ di “Baba Ayérayé” fún wọn. (Aísáyà 9:6) Nítorí náà, òun tún ni “gbòǹgbò” àwọn baba ńlá rẹ̀, títí kan Jésè.
w06 12/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 10
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
13:17—Ọ̀nà wo làwọn ará Mídíà kò fi ka fàdákà sí ohunkóhun tí wọ́n kò sì ní inú dídùn sí wúrà? Ògo táwọn ará Mídíà àtàwọn ará Páṣíà máa ń rí nígbà tí wọ́n bá ṣẹ́gun ṣe pàtàkì lójú wọn ju ẹrù tí wọ́n ń rí kó lójú ogun lọ. Ohun tí Kírúsì ṣe nígbà táwọn ìgbèkùn Júdà ń padà sí ilẹ̀ wọn fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó dá àwọn ohun èlò wúrà àti ti fàdákà tí Nebukadinésárì kó nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà padà fún wọn.
DECEMBER 26–JANUARY 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 17-23
“Àṣẹ Máa Ń Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹni Tó Bá Ń Ṣi Agbára Lò”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kejì
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
36:2, 3, 22. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbaṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ Ṣébínà, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ kó máa ṣe akọ̀wé fún ẹni tí wọ́n fi rọ́pò rẹ̀ láàfin. (Aísáyà 22:15, 19) Tí wọ́n bá gba ẹrù iṣẹ́ lọ́wọ́ wa nínú ètò Jèhófà nítorí ìdí kan, ṣé kò yẹ ká máa sin Ọlọ́run nìṣó ní ipò yòówù tó bá fi wá sí?
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
21:1—Àgbègbè wo ni Bíbélì pè ní “aginjù òkun”? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Bábílónì kò sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun rárá, Bíbélì pè é ní “aginjù òkun.” Ìdí ni pé ọdọọdún ni omi odò Yúfírétì àti Tígírísì máa ń kún bo àgbègbè náà, èyí sì máa ń fa àbàtà tó lọ salalu bí “òkun.”