ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 April ojú ìwé 6
  • Àwọn Orin Ìjọba Ọlọ́run Máa Ń Jẹ́ Ká Nígboyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Orin Ìjọba Ọlọ́run Máa Ń Jẹ́ Ká Nígboyà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Orin Yin Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Àwọn Orin Tuntun Tí A Ó Máa Lò Nínú Ìjọsìn!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Ǹjẹ́ O Ti Múra Tán Láti Kọrin sí Jèhófà Láwọn Ìpàdé Ìjọ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 April ojú ìwé 6

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Orin Ìjọba Ọlọ́run Máa Ń Jẹ́ Ká Nígboyà

Arákùnrin Erich Frost jókòó nídìí dùrù

Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi orin yin Jèhófà nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n. (Iṣe 16:25) Bákan náà lóde òní, ńṣe ni àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Sachsenhausen lórílẹ̀-èdè Jámánì lábẹ́ ìjọba Násì àti nígbà tí wọ́n fi tipátipá kó àwọn ará wa kan lọ sígbèkùn ní Siberia. Àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé àwọn orin wa máa ń fún àwọn Kristẹni tó ń dojú kọ ìṣòro nígboyà.

Láìpẹ́, a máa ṣe ìwé orin wa tuntun náà, “Sing Out Joyfully” to Jehovah láwọn èdè púpọ̀ sí i. Tá a bá ti gba ìwé orin yìí, a lè mọ àwọn ọ̀rọ̀ orin náà sórí tá a bá ń kọ ọ́ nígbà ìjọsìn ìdílé wa. (Ef 5:19) Tí àdánwò bá dé, ẹ̀mí mímọ́ á rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà. Àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run máa ń jẹ́ kí ìrètí wa túbọ̀ dájú lọ́kàn wa. Wọ́n máa ń fún wa lókun nígbà ìṣòro. Tó bá sì jẹ́ pé inú wa ń dùn ni, àwọn ọ̀rọ̀ orin tó ń mọ́kàn yọ̀ tó wà níbẹ̀ máa ń jẹ́ ká lè máa ‘fi ayọ̀ kọrin sí Jèhófà’ torí pé inú wa ń dùn, ọkàn wa sì balẹ̀. (1Kr 15:16; Sm 33:​1-3) Ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti fi hàn pé a mọyì àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run!

WO FÍDÍÒ NÁÀ ORIN TÓ Ń RU ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ SÓKÈ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló mú kí Arákùnrin Frost ṣe orin kan fúnra rẹ̀?

  • Báwo ni orin yẹn ṣe fún àwọn arákùnrin tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen lókun?

  • Àwọn ìṣòro wo ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́, báwo sì ni àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run ṣe lè fún ọ lókun?

  • Àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run wo ló wù ẹ́ kó o mọ̀ sórí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́