Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
APRIL 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 17-21
“Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Darí Èrò àti Ìṣe Rẹ”
(Jeremáyà 18:1-4) Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé: 2 “Dìde, kí o sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, ibẹ̀ sì ni èmi yóò ti mú kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.” 3 Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀, ó sì ń ṣe iṣẹ́ lórí àgbá kẹ̀kẹ́ amọ̀kòkò. 4 Ọwọ́ amọ̀kòkò sì ba ohun èlò tí ó ń fi amọ̀ ṣe jẹ́, ó sì yí padà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe ohun èlò mìíràn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ̀nà ní ojú amọ̀kòkò láti ṣe.
Jọ̀wọ́ Ara Rẹ fún Mímọ Tí Jèhófà Ń Mọ Ẹ́
Ìjẹ́pàtàkì ìdí tó fi yẹ kí o ṣègbọràn tinútinú bóo bá fẹ́ jàǹfààní nínú agbára mímọni bí ẹni mọ̀kòkò tí Jèhófà ní, ni Jèhófà alára ṣàkàwé rẹ̀ kedere nígbà tí ó sọ fún wòlíì Jeremáyà láti ṣèbẹ̀wò sí ibi iṣẹ́ amọ̀kòkò kan. Jeremáyà rí i pé amọ̀kòkò náà pèrò dà nípa ohun tí òun yóò fi ohun èlò kan ṣe, nígbà tí ‘ọwọ́ amọ̀kòkò ba ohun tó fẹ́ fi í mọ jẹ́.’ Jèhófà wá sọ pé: “Èmi kò ha lè ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí sí yín, ilé Ísírẹ́lì? . . . Wò ó! Bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí ní ọwọ́ mi, ilé Ísírẹ́lì.” (Jeremáyà 18:1-6) Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn ní Ísírẹ́lì kò ju kìkì ìṣùpọ̀ amọ̀ bọrọgidi lọ́wọ́ Jèhófà, tí òun yóò ṣù rúgúdú láti fi mọ ohunkóhun tó bá wù ú?
(Jeremáyà 18:5-10) Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá pé: 6 “‘Èmi kò ha lè ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí sí yín, ilé Ísírẹ́lì?’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Wò ó! Bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí ní ọwọ́ mi, ilé Ísírẹ́lì. 7 Ní ìṣẹ́jú èyíkéyìí tí mo bá sọ̀rọ̀ lòdì sí orílẹ̀-èdè kan àti lòdì sí ìjọba kan láti fà á tu àti láti bì í wó àti láti pa á run, 8 tí orílẹ̀-èdè yẹn bá sì yí padà ní ti gidi kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀ èyí tí mo sọ̀rọ̀ lòdì sí, èmi pẹ̀lú yóò pèrò dà dájúdájú ní ti ìyọnu àjálù tí mo ti rò láti mú ṣẹ ní kíkún sórí rẹ̀. 9 Ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú èyíkéyìí tí mo bá sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè kan àti nípa ìjọba kan láti gbé e ró àti láti gbìn ín, 10 tí ó bá sì ṣe ohun tí ó burú ní ojú mi ní ti gidi nípa ṣíṣàìgbọràn sí ohùn mi, ṣe ni èmi yóò pèrò dà pẹ̀lú ní ti ohun rere tí mo sọ fún ara mi pé èmi yóò ṣe fún ire rẹ̀.’
it-2 776 ¶4
Ìrònúpìwàdà
Tí amọ̀kòkò bá ń mọ nǹkan, àmọ́ tí ‘ọwọ́ rẹ̀ ba ohun èlò tí ó ń fi amọ̀ ṣe jẹ́,’ ó lè fi amọ̀ náà mọ nǹkan míì. (Jer 18:3, 4) Jèhófà kò dà bí èèyàn tó jẹ́ amọ̀kòkò tí ‘ọwọ́ rẹ̀ lè ba ohun èlò tó fi amọ̀ ṣe jẹ́,’ kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ń fi àpèjúwe yìí sọ ọlá àṣẹ tó ní lórí àwa èèyàn, ìyẹn ni pé ohun tá a bá ṣe nígbà tí Jèhófà bá ń tọ́ wa sọ́nà ló máa pinnu bóyá ó máa fi òdodo àti àánú bá wa lò tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Fi wé Ais 45:9; Ro 9:19-21.) Torí náà, bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣe dáhùn pàdà sí ìkìlọ̀ Jèhófà ló máà pínnú bóya kó ‘pèrò dà ní ti ìyọnu àjálù tó ti rò láti mú ṣẹ ní kíkún sórí’ orílẹ̀-èdè náà tàbí, kó ‘pèrò dà ní ti ohun rere tó ti sọ fún ara rẹ̀ pé òun yóò ṣe fún ire’ àwọn èèyàn rẹ̀. (Jer 18:5-10) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà tó jẹ́ Amọ̀kòkò Tó Ga Jù Lọ náà kì í ṣàṣìṣe, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni “amọ̀,” ìyẹn ọkàn àwa èèyàn máa ń yí padà, èyí sì máa ń mú kí Jèhófà pèrò dà.
(Jeremáyà 18:11) “Nísinsìnyí, jọ̀wọ́, sọ fún àwọn ènìyàn Júdà àti fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, mo ń pilẹ̀ ìyọnu àjálù kan lòdì sí yín, mo sì ń ro èrò kan lòdì sí yín. Kí olúkúlùkù jọ̀wọ́ yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, kí ẹ sì ṣe ọ̀nà yín àti ìbálò yín ní rere.”’”
Ta Ló Ń Darí Èrò Rẹ?
Kò ṣẹlẹ̀ rí, pé kí Jèhófà lo agbára ńlá rẹ̀ láti mú kí àwọn èèyàn ṣe nǹkan tí wọn kò fẹ́ ṣe; kì í sì í ṣe òun ló lẹ̀bi àbùkù tó wà lára wọn, gẹ́gẹ́ bó ti lè rí nínú ọ̀ràn amọ̀kòkò. (Diutarónómì 32:4) Àbùkù jẹ yọ nítorí pé àwọn tí Jèhófà fẹ́ mọ lọ́nà rere kọ̀ láti tẹ̀ lé ọ̀nà tó là sílẹ̀. Ìyàtọ̀ jàn-àn-ràn jan-an-ran tó wà láàárín ìwọ àti ìṣùpọ̀ amọ̀ bọrọgidi nìyẹn. O lómìnira láti yan ọ̀nà tó wù ẹ́. Ní lílo òmìnira yìí, o lè yàn láti jọ̀wọ́ ara rẹ fún mímọ tí Jèhófà ń mọ ẹ́, tàbí kí o mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ ọ́.
Ọ̀rọ̀ yìí mà gbàrònú o! Ẹ wo bó ti dára tó láti fetí sí ohùn Jèhófà dípò lílénu bebe pé, “Ẹnì kankan kò lè máa pàṣẹ ohun tí màá ṣe fún mi”! Gbogbo wa la nílò ìdarí Jèhófà. (Jòhánù 17:3) Fìwà jọ onísáàmù náà, Dáfídì, tó gbàdúrà pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.” (Sáàmù 25:4) Rántí ohun tí Ọba Sólómọ́nì sọ, pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i.” (Òwe 1:5) Ṣé wàá fetí sílẹ̀? Bóo bá fetí sílẹ̀, nígbà náà, “agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.”—Òwe 2:11.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
(Jeremáyà 17:9) Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?
Pa Ọkàn-àyà Rẹ Mọ́
13 Jeremáyà kìlọ̀ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà 17:9) Àdàkàdekè tí ọkàn-àyà ń ṣe yìí máa ń hàn nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí wí àwíjàre lẹ́yìn tá a ti ṣe ohun tí kò tọ́, tàbí tá a ń fojú pa àṣìṣe wa rẹ́, tàbí tá a ń fojú kékeré wo àléébù wa, tàbí tá a ń fọ́nnu nípa àwọn ohun tá a gbé ṣe. Ọkàn-àyà tó gbékútà tún máa ń ṣe àgàbàgebè—ìyẹn ni pé, ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ dídùn tó ń jáde lẹ́nu onítọ̀hún, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ lohun tó ń hù níwà. (Sáàmù 12:2; Òwe 23:7) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká má ṣe tan ara wa jẹ bá a ti ń ṣàyẹ̀wò ohun tó ń tinú ọkàn-àyà wa jáde!
(Jeremáyà 20:7) O ti tàn mí, Jèhófà, tí mo fi di ẹni tí a tàn. O lo okun rẹ lórí mi, o sì borí. Mo di ohun ìfirẹ́rìn-ín láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀; olúkúlùkù ènìyàn ń fi mí ṣẹ̀sín.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jeremáyà
20:7—Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ‘lo okun rẹ̀’ lórí Jeremáyà, tó sì tàn án? Bí àwọn èèyàn tí Jeremáyà ń kéde ìdájọ́ Jèhófà fún ò ṣe fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí i, ó ṣeé ṣe kó ronú pé òun ò lókun láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. Àmọ́, Jèhófà lo okun rẹ̀ láti fi mú kí Jeremáyà mú irú èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn, ó fún Jeremáyà lókun kó lè máa bá iṣẹ́ náà lọ. Báyìí ni Jèhófà ṣe tan wòlíì Jeremáyà nípa mímú kó ṣe ohun tó ronú pé òun ò ní lè ṣe.
Bíbélì Kíkà
(Jeremáyà 21:3-14) Jeremáyà sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí ẹ ó sọ fún Sedekáyà, 4 ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Kíyè sí i, èmi yóò yí ohun ìjà ogun tí ó wà ní ọwọ́ yín padà, èyí tí ẹ fi ń bá ọba Bábílónì jà, àti àwọn ará Kálídíà tí wọ́n ń sàga tì yín lẹ́yìn ògiri, ṣe ni èmi yóò kó wọn jọpọ̀ sí àárín ìlú ńlá yìí. 5 Dájúdájú, èmi fúnra mi yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ọwọ́ nínà jáde àti pẹ̀lú apá lílágbára àti pẹ̀lú ìbínú àti pẹ̀lú ìhónú àti pẹ̀lú ìkannú ńláǹlà. 6 Dájúdájú, èmi yóò kọlu àwọn olùgbé ìlú ńlá yìí, àti ènìyàn àti ẹranko. Nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ńláǹlà ni wọn yóò kú.”’ 7 “‘“Àti lẹ́yìn ìyẹn,” ni àsọjáde Jèhófà, “èmi yóò fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn náà àti àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ àjàkálẹ̀ àrùn, láti ọwọ́ idà àti láti ọwọ́ ìyàn, lé Nebukadirésárì ọba Bábílónì lọ́wọ́, àní lé àwọn ọ̀tá wọn àti lé àwọn tí ń wá ọkàn wọn lọ́wọ́, dájúdájú, òun yóò fi ojú idà kọlù wọ́n. Kì yóò káàánú wọn, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìyọ́nú hàn tàbí kí ó ṣàánú.”’ 8 “Kí o sì sọ fún àwọn ènìyàn yìí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, mo ń fi ọ̀nà ìyè àti ọ̀nà ikú síwájú yín. 9 Ẹni tí ó jókòó jẹ́ẹ́ sínú ìlú ńlá yìí yóò tipa idà àti ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn kú; ṣùgbọ́n ẹni tí ó jáde kúrò tí ó sì ṣubú ní tòótọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n ń sàga tì yín ni yóò máa wà láàyè nìṣó, dájúdájú, ọkàn rẹ̀ yóò sì jẹ́ tirẹ̀ bí ohun ìfiṣèjẹ.”’ 10 “‘“Nítorí mo ti dojú mi kọ ìlú ńlá yìí fún ìyọnu àjálù, kì í sì í ṣe fún rere,” ni àsọjáde Jèhófà. “Èmi yóò fi í lé ọba Bábílónì lọ́wọ́, dájúdájú, òun yóò sì fi iná sun ún.” 11 “‘Àti ní ti agbo ilé ọba Júdà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 12 Ilé Dáfídì, èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ní òròòwúrọ̀, máa fi ìdájọ́ òdodo dájọ́, sì dá ẹni tí a ń jà lólè nídè kúrò lọ́wọ́ oníjìbìtì, kí ìhónú mi má bàa jáde lọ gẹ́gẹ́ bí iná, kí ó sì jó ní ti gidi, tí kò ní sí ẹni tí yóò pa á nítorí ìwà búburú ìbálò yín.”’ 13 ‘Kíyè sí i, mo dojú kọ ọ́, ìwọ obìnrin olùgbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀, ìwọ àpáta ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Ní ti ẹ̀yin tí ẹ ń sọ pé: “Ta ni yóò sọ̀ kalẹ̀ láti gbéjà kò wá? Ta ni yóò sì wá sínú ibùgbé wa?” 14 Dájúdájú, èmi yóò béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ yín pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí èso ìbálò yín,’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Èmi yóò sì ti iná bọ inú igbó rẹ̀, yóò sì jẹ gbogbo ohun tí ó yí i ká run.’”
APRIL 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 22-24
“Ǹjẹ́ O Ní ‘Ọkàn-àyà Láti Mọ’ Jèhófà?”
(Jeremáyà 24:1-3) Jèhófà sì fi hàn mí, sì wòó! apẹ̀rẹ̀ méjì tí ọ̀pọ̀tọ́ wà nínú wọn ni a gbé kalẹ̀ níwájú tẹ́ńpìlì Jèhófà, lẹ́yìn tí Nebukadirésárì ọba Bábílónì ti mú Jekonáyà ọmọkùnrin Jèhóákímù, ọba Júdà lọ sí ìgbèkùn àti àwọn ọmọ aládé Júdà àti àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn olùkọ́ odi ààbò, láti Jerúsálẹ́mù, kí ó lè kó wọn wá sí Bábílónì. 2 Ní ti apẹ̀rẹ̀ kìíní, àwọn ọ̀pọ̀tọ́ inú rẹ̀ dára gan-an, bí ọ̀pọ̀tọ́ àkọ́pọ́n; àti ní ti apẹ̀rẹ̀ kejì, àwọn ọ̀pọ̀tọ́ inú rẹ̀ burú gan-an, tí a kò fi lè jẹ wọ́n nítorí bí wọ́n ti burú tó. 3 Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Kí ni ìwọ rí, Jeremáyà?” Nítorí náà, mo wí pé: “Àwọn ọ̀pọ̀tọ́, àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára náà dára gan-an, àwọn tí ó sì burú náà burú gan-an, tí a kò fi lè jẹ wọ́n nítorí bí wọ́n ti burú tó.”
Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti mọ Jèhófà?
2 Nígbà kan tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà nínú ọkàn àwọn èèyàn, ó fi ọkàn wọn wé èso ọ̀pọ̀tọ́. Ohun tó sọ sì lè ran àwa àtàwọn èèyàn wa lọ́wọ́. Kì í ṣe pé Jèhófà ń sọ fún àwọn èèyàn nípa bí èso ọ̀pọ̀tọ́ ṣe lè ṣe ara wọn lóore. Ńṣe ló kàn fi àkàwé náà kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Bí a ó ṣe máa jíròrò ohun tó sọ, ronú nípa ẹ̀kọ́ tí àwa Kristẹni lè rí kọ́ níbẹ̀.
(Jeremáyà 24:4-7) Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá, pé: 5 “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Bí ọ̀pọ̀tọ́ dáradára wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì fi ojú rere wo àwọn ìgbèkùn Júdà, àwọn tí èmi yóò rán lọ kúrò ní ibí yìí sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, lọ́nà rere. 6 Èmi yóò sì gbé ojú mi lé wọn lọ́nà rere, dájúdájú, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ yìí. Èmi yóò sì gbé wọn ró, èmi kì yóò sì ya wọ́n lulẹ̀; èmi yóò sì gbìn wọ́n, èmi kì yóò sì fà wọ́n tu. 7 Dájúdájú, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn-àyà láti mọ̀ mí, pé èmi ni Jèhófà; wọn yóò sì di ènìyàn mi, èmi fúnra mi yóò sì di Ọlọ́run wọn, nítorí wọn yóò fi gbogbo ọkàn-àyà wọn padà sọ́dọ̀ mi.
Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti mọ Jèhófà?
4 Kí ni Jèhófà sọ nípa àwọn èèyàn rere tó wà ní Júdà? Ó sọ pé: “Èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn-àyà láti mọ̀ mí, pé èmi ni Jèhófà; wọn yóò sì di ènìyàn mi.” (Jer. 24:7) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yìí mú wa lọ́kàn le torí ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run fẹ́ ká ní ‘ọkàn-àyà láti mọ’ òun, ìyẹn ni pé ká jẹ́ ẹni tó ń fẹ́ láti mọ Ọlọ́run, kó sì wù wá láti wà lára àwọn èèyàn rẹ̀. Báwo la ṣe lè jẹ́ irú èèyàn bẹ́ẹ̀? Àwọn ohun tá a máa ṣe rèé ká tó lè jẹ́ irú èèyàn bẹ́ẹ̀. Ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká ronú pìwà dà, ká yí pa dà, ká ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ká sì ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 3:19) Ṣé o ti ṣe àwọn ohun tá a kà sílẹ̀ yìí? Tó bá sì jẹ́ pé o ti ń lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé, ǹjẹ́ ò ń fojú sọ́nà láti ṣe èyí tó kù tó ò tíì ṣe lára àwọn ohun tá a kà sílẹ̀ yẹn?
(Jeremáyà 24:8-10) “‘Àti bí ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú tí a kò lè jẹ nítorí bí wọ́n ti burú tó, èyí ní ti tòótọ́ ni ohun tí Jèhófà wí: “Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn àṣẹ́kù Jerúsálẹ́mù tí wọ́n ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ yìí àti àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì- 9 dájúdájú, èmi yóò fi wọ́n fún ìmìtìtì pẹ̀lú, fún ìyọnu àjálù, ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé, fún ẹ̀gàn àti fún ọ̀rọ̀ òwe, fún ìṣáátá àti fún ìfiré, ní gbogbo ibi tí èmi yóò fọ́n wọn ká sí. 10 Dájúdájú, èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, títí wọn yóò fi wá sí òpin wọn kúrò ní ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn àti àwọn baba ńlá wọn.”’”
Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti mọ Jèhófà?
3 Ní ọdún 617 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù tó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà ń ṣe ohun tí Jèhófà kò fẹ́. Torí náà, Ọlọ́run fi ìran kan han Jeremáyà nípa ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí wọn. Nínú ìran náà, Jeremáyà rí apẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀tọ́ méjì, èyí tó dúró fún àwùjọ àwọn èèyàn méjì. Àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ kìíní “dára gan-an,” àmọ́ àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ kejì “burú gan-an.” (Ka Jeremáyà 24:1-3.) Àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tó burú yẹn dúró fún Sedekáyà Ọba àti àwọn míì bíi tiẹ̀ tí Nebukadinésárì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ máa tó wá gbéjà kò. Àmọ́, àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n dà bí àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tó dára. Lára wọn ni Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n ti wà ní Bábílónì nígbà yẹn, àtàwọn Júù tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn nígbà tó yá. Lára àwọn Júù tí wọ́n kó lọ sígbèkùn yìí sì máa tó pa dà wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá tún tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ kọ́.—Jer. 24:8-10; 25:11, 12; 29:10.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
(Jeremáyà 22:30) Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ẹ kọ ọ́ sílẹ̀ pé ọkùnrin yìí jẹ́ aláìbímọ, bí abarapá ọkùnrin tí kì yóò ní àṣeyọrí sí rere kankan ní ọjọ́ ayé rẹ̀; nítorí nínú àwọn ọmọ rẹ̀, ọ̀kankan kì yóò ní àṣeyọrí sí rere kankan, ní jíjókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì àti ní ṣíṣàkóso ní Júdà.’”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jeremáyà
22:30—Ǹjẹ́ àṣẹ yìí fagi lé ẹ̀tọ́ tí Jésù Kristi ní láti gorí ìtẹ́ Dáfídì? (Mátíù 1:1, 11) Rárá o, kò fagi lé e. Àwọn àtọmọdọ́mọ Jèhóákínì lòfin náà dè. Kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí yóò ‘jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì ní Júdà.’ Ní ti Jésù, ọ̀run ni ìtẹ́ rẹ̀ wà, ibẹ̀ ni yóò sì ti máa ṣàkóso, kì í ṣe láti ilẹ̀ Júdà.
(Jeremáyà 23:33) “Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá sì béèrè lọ́wọ́ rẹ, pé, ‘Kí ni ẹrù ìnira Jèhófà?’ ìwọ yóò sì sọ fún wọn pé, ‘“Ẹ̀yin ni- ẹrù ìnira mà ni yín o! Dájúdájú, èmi yóò sì pa yín tì,” ni àsọjáde Jèhófà.’
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jeremáyà
23:33—Kí ni “ẹrù ìnira Jèhófà” tí ibí yìí ń sọ? Nígbà tí Jeremáyà kéde ìdájọ́ alágbára nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, ẹrù ìnira ló jẹ́ fáwọn èèyàn olóríkunkun tí wọ́n wà lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Àwọn pẹ̀lú sì jẹ́ ẹrù ìnira fún Jèhófà débi pé Jèhófà kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Bákan náà, ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa ìparun àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ ẹrù ìnira fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, àwọn tí wọn ò sì kọbi ara sí ọ̀rọ̀ yìí náà jẹ́ ẹrù ìnira ńlá fún Ọlọ́run.
Bíbélì Kíkà
(Jeremáyà 23:25-36) “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn wòlíì tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi wí, pé, ‘Mo ti lá àlá! Mo ti lá àlá!’ 26 Báwo ni yóò ti wà pẹ́ tó ní ọkàn-àyà àwọn wòlíì tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, tí wọ́n sì jẹ́ wòlíì àgálámàṣà ọkàn-àyà wọn? 27 Wọ́n ń ronú mímú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi nípasẹ̀ àwọn àlá wọn tí ẹnì kìíní wọn ń rọ́ fún ẹnì kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ti gbàgbé orúkọ mi nípasẹ̀ Báálì. 28 Wòlíì tí ó bá lá àlá, jẹ́ kí ó rọ́ àlá náà; ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó ní ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ̀rọ̀ mi jáde ní òtítọ́.” “Kí ni èérún pòròpórò ní í ṣe pẹ̀lú ọkà?” ni àsọjáde Jèhófà. 29 “Ọ̀rọ̀ mi kò ha dà bí iná,” ni àsọjáde Jèhófà, “àti bí ọmọ owú tí ń fọ́ àpáta gàǹgà túútúú?” 30 “Nítorí náà, kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì,” ni àsọjáde Jèhófà, “àwọn tí ń jí ọ̀rọ̀ mi gbé lọ, olúkúlùkù láti ọ̀dọ̀ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.” 31 “Kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì,” ni àsọjáde Jèhófà, “àwọn tí ń lo ahọ́n wọn kí wọ́n lè sọ jáde pé, ‘Àsọjáde kan!’ ” 32 “Kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì tí ń lá àlá èké,” ni àsọjáde Jèhófà, “tí ń rọ́ wọn, tí wọ́n sì ń mú kí àwọn ènìyàn mi rìn gbéregbère nítorí èké wọn àti nítorí ìṣògo wọn.” “Ṣùgbọ́n èmi fúnra mi kò rán wọn tàbí pàṣẹ fún wọn. Nítorí náà, wọn kì yóò ṣe àwọn ènìyàn yìí láǹfààní kankan,” ni àsọjáde Jèhófà. 33 “Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá sì béèrè lọ́wọ́ rẹ, pé, ‘Kí ni ẹrù ìnira Jèhófà?’ ìwọ yóò sì sọ fún wọn pé, ‘“Ẹ̀yin ni- ẹrù ìnira mà ni yín o! Dájúdájú, èmi yóò sì pa yín tì,” ni àsọjáde Jèhófà.’ 34 Ní ti wòlíì tàbí àlùfáà tàbí àwọn ènìyàn tí ó bá sọ pé, ‘Ẹrù ìnira Jèhófà!’ Ṣe ni èmi yóò yí àfiyèsí sórí ọkùnrin yẹn pẹ̀lú àti sórí agbo ilé rẹ̀. 35 Èyí ni ohun tí olúkúlùkù yín ń sọ fún ọmọnìkejì rẹ̀ àti olúkúlùkù fún arákùnrin rẹ̀, ‘Kí ni ohun tí Jèhófà fi dáhùn? Kí sì ni ohun tí Jèhófà sọ?’ 36 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe mẹ́nu kan ẹrù ìnira Jèhófà mọ́, nítorí ohun tí ẹrù ìnira náà dà fún olúkúlùkù ni ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ẹ sì ti yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run wa, padà.
APRIL 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 25-28
“Jẹ́ Onígboyà Bíi Jeremáyà”
(Jeremáyà 26:2-6) “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Dúró nínú àgbàlá ilé Jèhófà, kí o sì sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ìlú ńlá Júdà tí ń wọlé láti tẹrí ba ní ilé Jèhófà, gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò pa láṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn. Má ṣe mú ọ̀rọ̀ kankan kúrò. 3 Bóyá wọn yóò fetí sílẹ̀ kí olúkúlùkù wọn sì padà ní ọ̀nà búburú rẹ̀, dájúdájú, èmi yóò sì pèrò dà ní ti ìyọnu àjálù tí mo ń rò láti mú ṣẹ ní kíkún sórí wọn nítorí búburú ìbálò wọn. 4 Kí o sì wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Bí ẹ kò bá ní fetí sí mi nípa rírìn nínú òfin mi tí mo ti fi síwájú yín, 5 nípa fífetí sí ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, tí mo ń rán sí yín, àní tí mo ń dìde ní kùtùkùtù, tí mo sì ń rán wọn, àwọn tí ẹ kò fetí sí, 6 Ṣe ni èmi, ẹ̀wẹ̀, yóò ṣe ilé yìí bí èyí tí ó wà ní Ṣílò, èmi yóò sì ṣe ìlú ńlá yìí ní ìfiré sí gbogbo orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé.’”’”
Jeremáyà Kò Jáwọ́ Nínú Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
Jèhófà ní kí Jeremáyà kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé ìlú Jerúsálẹ́mù máa pa run tí wọ́n bá kọ̀ láti yí pa dà kúrò nínú ìwà búburú wọn. Nígbà tí Jeremáyà jíṣẹ́ yìí fún àwọn èèyàn náà, wọ́n bínú, wọ́n sì wí pé: “Ìdájọ́ ikú tọ́ sí ọkùnrin yìí.” Àmọ́ Jeremáyà rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n “ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà.” Lẹ́yìn náà, ó ní: ‘Kí ẹ mọ̀ dájú pé, bí ẹ bá fi ikú pa mí, ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ni ẹ mú wá sórí ara yín nítorí lóòótọ́ ni Jèhófà rán mi sí yín.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tó wá ṣẹlẹ̀?—
(Jeremáyà 26:8, 9) Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Jeremáyà parí sísọ gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ó sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà gbá a mú, wọ́n wí pé: “Dájúdájú, ìwọ yóò kú. 9 Èé ṣe tí o fi sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà, pé, ‘Bí èyí tí ó wà ní Ṣílò ni ilé yìí yóò dà, ìlú ńlá yìí gan-an yóò sì pa run di ahoro tí kò fi ní sí olùgbé’?” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń péjọ pọ̀ yí Jeremáyà ká ní ilé Jèhófà.
(Jeremáyà 26:12, 13) Látàrí ìyẹn, Jeremáyà sọ fún gbogbo ọmọ aládé àti fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Jèhófà ni ó rán mi láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ilé yìí àti nípa ìlú ńlá yìí, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́. 13 Wàyí o, ẹ ṣe ọ̀nà yín àti ìbálò yín ní rere, ẹ sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà yóò sì pèrò dà ní ti ìyọnu àjálù tí ó ti sọ lòdì sí yín.
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ọlọ́run Ní “Apá Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọjọ́”
13 Kí làwọn aṣáájú ìsìn ṣe lórí ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ pẹ̀lú gbogbo bí ipò ọ̀rọ̀ ìjọsìn àti ti ìṣèlú ṣe wà ní Júdà nígbà yẹn? Ohun tí wòlíì Jeremáyà alára sọ ni pé: “Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà gbá [mi] mú, wọ́n wí pé: ‘Dájúdájú, ìwọ yóò kú.’” Bẹ́ẹ̀ ni o, ṣe ni wọ́n gbaná jẹ, tí wọ́n ní: “Ìdájọ́ ikú tọ́ sí ọkùnrin yìí.” (Ka Jeremáyà 26:8-11.) Àmọ́ ṣá, àwọn ọ̀tá Jeremáyà kò rí i pa o. Jèhófà wà lẹ́yìn wòlíì rẹ̀ yìí gbágbáágbá láti gbà á sílẹ̀. Jeremáyà alára kò jẹ́ kí ojú àwọn alátakò rẹ̀ tó korò lágbárí wọn tàbí pípọ̀ tí wọ́n pọ̀ dẹ́rù ba òun. Má ṣe jẹ́ kí àwọn alátakò dẹ́rù ba ìwọ náà.
(Jeremáyà 26:16) Nígbà náà ni àwọn ọmọ aládé àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sọ fún àwọn àlùfáà àti fún àwọn wòlíì pé: “Ìdájọ́ ikú kò tọ́ sí ọkùnrin yìí, nítorí ó bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.”
(Jeremáyà 26:24) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọwọ́ Áhíkámù ọmọkùnrin Ṣáfánì ni ó wà pẹ̀lú Jeremáyà, kí a má bàa fi í lé àwọn ènìyàn náà lọ́wọ́ láti ṣe ikú pa á.
Jeremáyà Kò Jáwọ́ Nínú Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
Bíbélì sọ pé: “Nígbà náà ni àwọn ọmọ aládé àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sọ fún àwọn àlùfáà àti fún àwọn wòlíì pé: ‘Ìdájọ́ ikú kò tọ́ sí ọkùnrin yìí, nítorí ó bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.’” Torí náà, Jèhófà dáàbò bo Jeremáyà nígbà tí kò jẹ́ kí ìbẹ̀rù mú kó jáwọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Jẹ́ ká wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Úríjà tóun náà jẹ́ wòlíì Jèhófà, ó ṣe ohun tó yàtọ̀ gedegbe sí èyí tí Jeremáyà ṣe.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
(Jeremáyà 27:2, 3) “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi, ‘Ṣe àwọn ọ̀já àti àwọn ọ̀pá àjàgà fún ara rẹ, kí o sì fi wọ́n sí ọrùn rẹ. 3 Kí o sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọba Édómù àti sí ọba Móábù àti sí ọba àwọn ọmọ Ámónì àti sí ọba Tírè àti sí ọba Sídónì nípa ọwọ́ àwọn ońṣẹ́ tí ń bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà ọba Júdà.
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ọlọ́run Ní “Apá Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọjọ́”
21 Ẹ̀rí fi hàn pé lápá ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Sedekáyà, àwọn ọba Édómù, Móábù, Ámónì, Tírè àti Sídónì rán oníṣẹ́ wá sí Jerúsálẹ́mù. Bóyá ńṣe ni wọ́n fẹ́ kí Sedekáyà dara pọ̀ mọ́ àwọn kí wọ́n lè jọ bá Nebukadinésárì jà. Àmọ́ Jeremáyà rọ Sedekáyà pé kó máa sin ilẹ̀ Bábílónì. Èyí náà ló jẹ́ kí Jeremáyà fún àwọn ońṣẹ́ ọba tó wá sí Jerúsálẹ́mù ní ọ̀pá àjàgà láti fi sọ fún àwọn orílẹ̀-èdè yẹn pé káwọn náà sin àwọn ará Bábílónì. (Jer. 27:1-3, 14) Àwọn èèyàn kò fẹ́ ohun tí Jeremáyà ń sọ pé kí wọ́n ṣe yìí. Hananáyà sì tún dá kún báwọn èèyàn ò ṣe fojúure wo ìhìn tí Jeremáyà agbọ̀rọ̀sọ Ọlọ́run ń jẹ́ fún wọn. Hananáyà yìí ni wòlíì èké tó ń sọ fáwọn èèyàn pé Ọlọ́run rán òun láti sọ fún wọn pé òun yóò ṣẹ́ àjàgà àwọn ará Bábílónì. Àmọ́, Jèhófà gbẹnu Jeremáyà sọ pé kí ọdún kan tó pé, Hananáyà yóò kú, ó sì kú lóòótọ́.—Jer. 28:1-3, 16, 17.
(Jeremáyà 28:11) Hananáyà sì ń bá a lọ láti sọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Báyìí gan-an ni èmi yóò ṣẹ́ àjàgà Nebukadinésárì ọba Bábílónì láàárín ọdún méjì gbáko sí i kúrò ní ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè.’” Jeremáyà wòlíì sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.
“Èmi Kò Lè Dákẹ́”
11 Àmọ́ ṣá, ẹ má ṣe jẹ́ ká rò pé agbawèrèmẹ́sìn ni Jeremáyà o. Ó máa ń lo làákàyè táwọn alátakò bá dojú kọ ọ́. Ó máa ń mọ ìgbà tó yẹ kó fi wọ́n sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín òun àti Hananáyà. Wòlíì èké yẹn ta ko àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ní gbangba, Jeremáyà wá tọ́ ọ sọ́nà, ó sì sọ ohun téèyàn fi ń dá wòlíì tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. Ni Hananáyà bá fipá gba àjàgà igi kan tí Jeremáyà gbé sí ọrùn tó fi ń ṣàpèjúwe bí àjàgà Bábílónì ṣe máa wà lọ́rùn àwọn èèyàn, ó sì ṣẹ́ ẹ. Kí ni Jeremáyà wá ṣe níwọ̀n bí kò ti mọ ohun tí Hananáyà máa tún fẹ́ ṣe lẹ́yìn ìyẹn? Bíbélì sọ pé: “Jeremáyà wòlíì sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.” Ṣe ni Jeremáyà kúrò níbẹ̀ o. Nígbà tó yá, Jèhófà ní kó pa dà lọ bá Hananáyà, kó sì sọ ohun tí òun máa ṣe, ìyẹn ni pé Bábílónì yóò kó àwọn Júù nígbèkùn àti pé ikú yóò pa Hananáyà.—Jer. 28:1-17.
12 Àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí fi hàn kedere pé, bá a ṣe ń lo ìgboyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, a tún gbọ́dọ̀ máa lo làákàyè. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé nínú ilé kan, ẹnì kan kọ̀ láti gba àlàyé inú Bíbélì tá à ń ṣe, tó dà á sí ìbínú, bóyá tó tiẹ̀ fẹ́ sọ ọ́ dìjà, ńṣe ni ká rọra fibẹ̀ sílẹ̀ wọ́ọ́rọ́wọ́, ká kọjá sí ilé míì. Kò sídìí láti máa bá ẹnikẹ́ni fa ọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run rárá o. Tá a bá “kó ara [wa] ní ìjánu lábẹ́ ibi,” ìyẹn lè jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ran onítọ̀hún lọ́wọ́ nígbà míì tó wọ̀.—Ka 2 Tímótì 2:23-25; Òwe 17:14.
Bíbélì Kíkà
(Jeremáyà 27:12-22) Sedekáyà ọba Júdà pàápàá ni mo bá sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, pé: “Mú ọrùn rẹ wá sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, kí o sì sin òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀, kí o sì máa wà láàyè. 13 Èé ṣe tí ìwọ fúnra rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò fi kú nípasẹ̀ idà, nípasẹ̀ ìyàn àti nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jèhófà sọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò sin ọba Bábílónì? 14 Má sì fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ń sọ fún yín pé, ‘Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì,’ nítorí èké ni wọ́n ń sọ ní àsọtẹ́lẹ̀ fún yín. 15 “‘Nítorí èmi kò rán wọn,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘ṣùgbọ́n wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi, kí èmi lè fọ́n yín ká, ẹ óò sì ṣègbé, ẹ̀yin àti àwọn wòlíì tí ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.’” 16 Àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí ni mo bá sọ̀rọ̀, pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yín tí ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín, pé: “Wò ó! Àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà ni a óò kó padà láti Bábílónì ní àìpẹ́ sí ìsinsìnyí!” Nítorí èké ni wọ́n ń sọ ní àsọtẹ́lẹ̀ fún yín. 17 Ẹ má fetí sí wọn. Ẹ sin ọba Bábílónì kí ẹ sì máa wà láàyè. Èé ṣe tí ìlú ńlá yìí yóò fi di ibi ìparundahoro? 18 Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí ọ̀rọ̀ Jèhófà sì wà pẹ̀lú wọn, kí wọ́n jọ̀wọ́ fi taratara bẹ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, kí àwọn nǹkan èlò tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ ní ilé Jèhófà àti ní ilé ọba Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù má ṣe wá sí Bábílónì.’ 19 “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí nípa àwọn ọwọ̀n àti nípa òkun àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti nípa ìyókù nǹkan èlò tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ nínú ìlú ńlá yìí, 20 tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kò kó nígbà tí ó mú Jekonáyà ọmọkùnrin Jèhóákímù, ọba Júdà, lọ ní ìgbèkùn, láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọ̀tọ̀kùlú Júdà àti Jerúsálẹ́mù; 21 nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí nípa àwọn nǹkan èlò tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ ní ilé Jèhófà àti ní ilé ọba Júdà àti Jerúsálẹ́mù, 22 ‘“Bábílónì ni a óò kó wọn wá, ibẹ̀ sì ni wọn yóò máa wà nìṣó títí di ọjọ́ tí èmi yóò yí àfiyèsí mi sí wọn,” ni àsọjáde Jèhófà. “Dájúdájú, èmi yóò mú wọn gòkè wá, èmi yóò sì mú wọn padà bọ̀ sí ibí yìí.”’”
APRIL 24-30
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 29-31
“Jèhófà Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Májẹ̀mú Tuntun”
(Jeremáyà 31:31) “Wòó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun.
it-1 524 ¶3-4
Májẹ̀mú
Májẹ̀mú Tuntun. Jèhófà gbẹnu wòlíì Jeremáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa májẹ̀mú tùntun ní ọgọ́rùn-ún ọdún keje ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sọ pé májẹ̀mú yìí máa yàtọ̀ sí májẹ̀mú Òfin, èyí tí Ísírẹ́lì kò tẹ̀ lé. (Jer 31:31-34) Ní Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tó dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ó bá wọn dá májẹ̀mú tuntun ó sì sọ pé ikú òun ló máa fìdí májẹ̀mú náà múlẹ̀. (Lk 22:20) Nígbà tó pé àádọ́ta [50] ọjọ́ tó jíǹde àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá tó ti wà pẹ̀lú Baba rẹ̀ lọ́run, ó tú ẹ̀mí mímọ́, èyí tí ò gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, dà sórí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n pé jọ sí yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù.—Iṣe 2:1-4, 17, 33; 2Kọ 3:6, 8, 9; Heb 2:3, 4.
Àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun náà ni Jèhófà àti “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn tí a fi ẹ̀mí bí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi; àwọn ni wọn para pọ̀ di ìjọ tàbi ara rẹ̀. (Heb 8:10; 12:22-24; Ga 6:15, 16; 3:26-28; Ro 2:28, 29) Ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi tó ta sílẹ̀ (ìyẹn ìgbà tó kú) ló mú kí májẹ̀mú tuntun lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ìyẹn ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó níye lórí tó fún Jèhófà nígba tó pa dà sí ọ̀run. (Mt 26:28) Torí náà, tí Ọlọ́run bá yan ẹnì kan láti lọ sí ọ̀rún (Heb 3:1), ńṣe ni Ọlọ́run mu ẹni náà wọnú májẹ̀mú Rẹ̀, èyí tí ìràpadà Jésù mú kó ṣeé ṣe. (Sm 50:5; Heb 9:14, 15, 26) Jésù Kristi ni Alárinà májẹ̀mú tuntun, (Heb 8:6; 9:15) òun sì tún ni olórí Irú-Ọmọ Ábúráhámù náà. (Ga 3:16) Torí pé Jésù ni alárinà májẹ̀mú tuntun náà, bó ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó wà nínú májẹ̀mú náà jì wọ́n ló ń sọ wọ́n di ọ̀kan pàtàkì irú-ọmọ Ábúráhámù (Heb 2:16; Ga 3:29). Lẹ́yìn náà, Jèhófà wá pè wọ́n ní olódodo.—Ro 5:1, 2; 8:33; Heb 10:16, 17.
(Jeremáyà 31:32, 33) Kì í ṣe èyí tí ó rí bí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo di ọwọ́ wọn mú láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ‘májẹ̀mú mi èyí tí àwọn fúnra wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ni ọkọ olówó orí wọn,’ ni àsọjáde Jèhófà.” 33 “Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì,” ni àsọjáde Jèhófà. “Ṣe ni èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.”
Wàá Jàǹfààní Májẹ̀mú Tuntun
11 Ṣé wàá tún fẹ́ mọ àwọn nǹkan míì tí májẹ̀mú tuntun fi yàtọ̀ sí májẹ̀mú ti Òfin Mósè? Ohun kan pàtàkì tó fi yàtọ̀ ni ibi tí wọ́n kọ ọ́ sí. (Ka Jeremáyà 31:33.) Orí wàláà òkúta ni wọ́n kọ Òfin Mẹ́wàá ti májẹ̀mú Òfin sí, ó sì dàwátì nígbà tó yá. Ṣùgbọ́n ní ti májẹ̀mú tuntun, inú ọkàn àwọn èèyàn ni Jeremáyà sọ pé wọ́n máa kọ òfin rẹ̀ sí, yóò sì wà títí gbére. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n kópa nínú májẹ̀mú tuntun mọyì òfin yìí gan-an ni. Àwọn “àgùntàn mìíràn” tó ń retí pé wọ́n máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé, tí wọn kò kópa nínú májẹ̀mú tuntun náà ní tààràtà ńkọ́? (Jòh. 10:16) Inú àwọn náà dùn sí òfin Ọlọ́run. Ńṣe ni tiwọn dà bíi tàwọn àtìpó tó ń gbé nílẹ̀ Ísírẹ́lì, tó jẹ́ pé wọ́n fara mọ́ Òfin Mósè, tí wọ́n sì ń jàǹfààní rẹ̀.—Léf. 24:22; Núm. 15:15.
12 Kí lo máa sọ tí wọ́n bá bi ọ́ pé, ‘Kí ni òfin yìí tí wọ́n kọ sínú ọkàn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?’ Òfin yìí kan náà ni Bíbélì pè ní “òfin Kristi.” Àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí tó kópa nínú májẹ̀mú tuntun ni Ọlọ́run kọ́kọ́ fún ní òfin yẹn. (Gál. 6:2; Róòmù 2:28, 29) A lè fi ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ṣàkópọ̀ “òfin Kristi,” òun sì ni, ìfẹ́. (Mát. 22:36-39) Báwo ló ṣe ń di pé wọ́n kọ òfin yìí sínú ọkàn àwọn ẹni àmì òróró? Àwọn nǹkan pàtàkì táwọn ẹni àmì òróró máa ń ṣe tí òfin yìí á fi dèyí tí wọ́n kọ sínú ọkàn wọn ni pé, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ń gbàdúrà sí Jèhófà. Nítorí náà, nǹkan méjèèjì yìí, tó jẹ́ apá kan ìjọsìn tòótọ́, ṣe pàtàkì gan-an nígbèésí ayé gbogbo Kristẹni tòótọ́, títí kan àwọn tí kò kópa nínú májẹ̀mú tuntun, àmọ́ tí wọ́n fẹ́ jàǹfààní nínú rẹ̀.
(Jeremáyà 31:34) “Olúkúlùkù wọn kì yóò sì tún máa kọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, àti olúkúlùkù wọn arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Jèhófà!’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ nínú wọn àní dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn,” ni àsọjáde Jèhófà. “Nítorí èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.”
Wàá Jàǹfààní Májẹ̀mú Tuntun
18 Nítorí náà, májẹ̀mú tuntun jẹ́ ká mọ apá kan pàtàkì nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lò, yálà àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú yẹn ni o tàbí àwọn tí wọ́n nírètí pé àwọn máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé tí Jèhófà bá ti lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, ibi tọ́rọ̀ náà parí sí pátápátá nìyẹn. Nítorí náà, gbogbo wa la lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe nínú májẹ̀mú tuntun. Wá bi ara rẹ ní ìbéèrè yìí, ‘Ǹjẹ́ mo máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, kí n má sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti sọ pé mo dárí rẹ̀ ji àwọn èèyàn?’ (Mát. 6:14, 15) Bí èyí ṣe kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké ló kan ẹ̀ṣẹ̀ ńlá bíi kí ọkọ tàbí aya Kristẹni kan ṣe panṣágà. Tí ẹni tí aya rẹ̀ tàbí ọkọ rẹ̀ ṣe panṣágà bá pinnu láti dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà, ǹjẹ́ ohun tó tọ́ kọ́ ni pé kó má ṣe ‘rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́’? Lóòótọ́ kì í ṣe nǹkan tó rọrùn láti ju ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn ṣẹ̀ wá sẹ́yìn, ká sì gbàgbé rẹ̀, àmọ́ ìyẹn jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
(Jeremáyà 29:4) “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí fún gbogbo ìgbèkùn, àwọn tí mo ti mú kí ó lọ ní ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù sí Bábílónì,
(Jeremáyà 29:7) Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ wá àlàáfíà ìlú ńlá tí mo mú kí a kó yín lọ ní ìgbèkùn, ẹ sì gbàdúrà nítorí rẹ̀ sí Jèhófà, nítorí nínú àlàáfíà rẹ̀, àlàáfíà yóò wà fún ẹ̀yin fúnra yín.
Ọlọrun àti Kesari
5 Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Jehofa mí sí wòlíì olùṣòtítọ́ náà, Jeremiah, láti sọ fún àwọn Júù tí ń bẹ ní ìgbèkùn, pé kí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ àwọn olùṣàkóso nígbà tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni, àní kí wọ́n tilẹ̀ gbàdúrà fún àlàáfíà ìlú náà. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí wọn, ó kọ̀wé pé: “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israeli, wí fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn lọ, . . . Kí ẹ . . . máa wá àlàáfíà ìlú náà, níbi tí èmí ti mú kí a kó yín lọ ní ìgbèkùn, ẹ sì máa gbàdúrà sí Oluwa fún un: nítorí nínú àlàáfíà rẹ̀ ni ẹ̀yin óò ní àlàáfíà.” (Jeremáyà 29:4, 7) Gbogbo ìgbà ni àwọn ènìyàn Jehofa ní ìdí láti “máa wá àlàáfíà” fún ara wọn àti orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé, kí wọ́n baà lè ní òmìnira láti jọ́sìn Jehofa.—1 Peteru 3:11.
(Jeremáyà 29:10) “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní ìbámu pẹ̀lú lílo àádọ́rin ọdún pé ní Bábílónì, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí yín, dájúdájú, èmi yóò fìdí ọ̀rọ̀ rere mi múlẹ̀ fún yín, láti mú yín padà wá sí ibí yìí.’
Bíbélì Kíkà
(Jeremáyà 31:31-40) “Wòó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun; 32 kì í ṣe èyí tí ó rí bí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo di ọwọ́ wọn mú láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ‘májẹ̀mú mi èyí tí àwọn fúnra wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ni ọkọ olówó orí wọn,’ ni àsọjáde Jèhófà.” 33 “Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì,” ni àsọjáde Jèhófà. “Ṣe ni èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.” 34 “Olúkúlùkù wọn kì yóò sì tún máa kọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, àti olúkúlùkù wọn arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Jèhófà!’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ nínú wọn àní dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn,” ni àsọjáde Jèhófà. “Nítorí èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.” 35 Èyí ni ohun tí Jèhófà, Olùfúnni ní oòrùn fún ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fún ìmọ́lẹ̀ ní òru, Ẹni tí ń ru òkun sókè kí ìgbì rẹ̀ lè di aláriwo líle, Ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, wí: 36 “‘Bí a bá lè mú àwọn ìlànà wọ̀nyí kúrò níwájú mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àwọn tí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú lè ṣíwọ́ jíjẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi nígbà gbogbo.’” 37 Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “‘Bí a bá lè díwọ̀n ọ̀run lókè, tí a sì lè wá ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀ kàn, èmi fúnra mi pẹ̀lú lè kọ gbogbo irú-ọmọ Ísírẹ́lì pátá ní tìtorí gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe,’ ni àsọjáde Jèhófà.” 38 “Wòó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “ìlú ńlá náà ni a ó sì kọ́ fún Jèhófà láti Ilé Gogoro Hánánélì dé Ẹnubodè Igun. 39 Síbẹ̀, okùn ìwọ̀n yóò jáde lọ tààrà ní ti gidi sí òkè kékeré Gárébù dájúdájú, yóò sì lọ yí ká dé Góà. 40 Àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ àwọn òkú àti ti eérú ọlọ́ràá, àti gbogbo ilẹ̀ onípele títẹ́jú títí dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì, títí lọ dé igun Ẹnubodè Ẹṣin, síha yíyọ oòrùn, yóò jẹ́ ohun mímọ́ lójú Jèhófà. A kì yóò fàá tu, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ya á lulẹ̀ mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”