Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
MAY 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 32-34
“Àmì Tó Fi Hàn Pé Jèhófà Máa Mú Ísírẹ́lì Padà Bọ̀ Sípò”
it-1 105 ¶2
Ánátótì
Ọmọ ìlú Ánátótì ni wòlíì Jeremáyà, àmọ́ àwọn aráàlú rẹ̀ ò kà á sí pàtàkì, kódà wọn fẹ́ pa á torí pé ó ń kéde ọ̀rọ̀ òtítọ́ Jèhófà. (Jer 1:1; 11:21-23; 29:27) Torí náà, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé ìlú náà máa pa run, àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì nímùúṣẹ nígbà tí Bábílóní wá gbógun jà wọ́n. (Jer 11:21-23) Kí Jerúsálẹ́mù tó pa run, Jeremáyà lo ẹ̀tọ́ tó ní láti ra ilẹ̀ ìbátan rẹ̀ kan ní Ánátótì gẹ́gẹ́ bí àmì pé Ọlọ́run máa mú àwọn èèyàn rẹ̀ padà bọ̀ sípò. (Jer 32:7-9) Àwọn ọkùnrin méjìdínláàádóje [128] láti Ánátótì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ kúrò nígbèkùn pẹ̀lú Serubábélì, ìlú Ánátótì sì wà lára àwọn ìlú tí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kàn sí i, èyí sì mú àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà ṣẹ.—Ẹsr 2:23; Ne 7:27; 11:32.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jeremáyà
32:10-15—Kí ni ìwé àdéhùn méjì tí Jeremáyà ṣe nítorí ọjà kan ṣoṣo tó rà wà fún? Wọ́n ò fi èdìdì di ọ̀kan nínú àwọn ìwé àdéhùn méjì náà nítorí kí wọ́n lè máa yẹ̀ ẹ́ wò tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Wọ́n sì fi èdìdì di ìkejì kí wọ́n bàa lè máa fi jẹ́rìí sí ti àkọ́kọ́ nígbà tó bá gba pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Jeremáyà tẹ̀ lé ìgbésẹ̀ tó bófin mu tó sì bọ́gbọ́n mu bó tilẹ̀ jẹ́ pé onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ tó tún jẹ́ ìbátan rẹ̀ ló bá dòwò pọ̀. Àpẹẹrẹ lèyí jẹ́ fún wa lónìí.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jeremáyà
33:23, 24—“Ìdílé méjì” wo ni ẹsẹ yìí mẹ́nu kàn? Ọ̀kan ni ìdílé ọlọ́ba tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba, ìkejì sì ni ìdílé àlùfáà tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Áárónì. Báwọn ọ̀tá ṣe pa Jerúsálẹ́mù run tí wọ́n sì dáná sun tẹ́ńpìlì Jèhófà mú kó dà bíi pé Jèhófà ti kọ ìdílé méjèèjì, pé Jèhófà ò ní ní ìjọba kankan mọ́ tí yóò ṣàkóso lé ayé lórí, ó sì tún mú kó dà bíi pé Jèhófà ò ní jẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ padà máa ṣe ìjọsìn rẹ̀ mọ́.
MAY 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 35-38
“Ebedi-mélékì Jẹ́ Onígboyà àti Onínúure”
it-2 1228 ¶3
Sedekáyà
Ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà kan tó fi hàn pé Sedekáyà kì í ṣe akíkanjú ọba. Nígbà táwọn ọmọ aládé sọ pé àwọn máa pa Jeremáyà torí wọ́n gbà pé ńṣe ló ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn aráàlú, ńṣe ni Sedekáyà sọ pé: “Wò ó! Ó wà ní ọwọ́ yín. Nítorí kò sí nǹkan kan rárá nínú èyí tí ọba ti lè borí yín.” Àmọ́, lẹ́yìn náà Sedekáyà gba Ebedi-mélékì láyè láti lọ yọ Jeremáyà kúrò nínú kòtò ẹlẹ́rẹ̀, ó sì sọ pé kí ó kó ọgbọ̀n ọkùnrin dání kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. Nígbà tó yá, Sedekáyà tún pe Jeremáyà, wọ́n sì jọ sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́. Ó fi dá wòlíì náà lójú pé òun kò ní pa á, bẹ́ẹ̀ ni òun kò ní fi í lé àwọn tí wọ́n fẹ́ pa á lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù àwọn Júù tó ti wà lábẹ́ àwọn ará Kálídíà ń ba Sedekáyà, torí náà kò fetí sí ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run gbẹnu Jeremáyà sọ fún un pé kó fi ara rẹ̀ sábẹ́ àwọn ọmọ aládé Bábílónì. Ohun míì tó fi hàn pé ẹ̀rù ń bà á ni pé ó ní kí Jeremáyà má ṣe sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ tí wọ́n jọ sọ fún àwọn ọmọ aládé tí wọ́n fẹ́ mọ ohun tó sẹlẹ̀.—Jer 38:1-28.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 759
Àwọn Ọmọ Rékábù
Inú Jèhófà dùn sí wọn torí pé wọn ò hùwà àfojúdi, wọ́n sì jẹ́ onígbọràn. Bí wọ́n ṣe jẹ́ onígbọràn sí bàbá wọn fi hàn pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ará Júdà tí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn. (Jer 35:12-16) Ọlọ́run wá ṣe ìlérí kan fún wọn pé: “A kì yóò ké ọkùnrin kan tí yóò máa dúró níwájú mi nígbà gbogbo kúrò lọ́dọ̀ Jónádábù ọmọkùnrin Rékábù.”—Jer 35:19.
Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Bíbá Ọlọ́run Rìn
16 Tìfẹ́tìfẹ́, Jèhófà sọ fún wa nípa ìtura tí a óò gbádùn lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà náà. (Orin Dáfídì 72:1-4, 16; Aísáyà 25:7, 8) Ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn pákáǹleke inú ìgbésí ayé nísinsìnyí nípa fífún wa ní ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe lè gbájú mọ́ àwọn ohun àkọ́múṣe wa. (Mátíù 4:4; 6:25-34) Nípasẹ̀ àwọn àkọsílẹ̀ bí ó ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ìgbà àtijọ́, Jèhófà ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. (Jeremáyà 37:21; Jákọ́bù 5:11) Ó ń ki wá láyà pẹ̀lú ìmọ̀ náà pé, láìka làásìgbò èyíkéyìí tí ó lè dé bá wa sí, ìfẹ́ tí ó ní fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin kì í yẹ̀. (Róòmù 8:35-39) Sí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó polongo pé: “Dájúdájú èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5.
17 Ní gbígba okun láti inú ìmọ̀ yí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn dípò yíyí pa dà sí ọ̀nà ayé. Ọgbọ́n èrò orí ayé kan tí ó gbajúmọ̀ láàárín àwọn òtòṣì ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ni pé mímú nǹkan ẹni tí ó ní ohun púpọ̀, kí o baà lè bọ́ ìdílé rẹ, kì í ṣe olè jíjà. Ṣùgbọ́n, àwọn tí ń rìn nípa ìgbàgbọ́ kọ irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀. Wọ́n ka ojú rere Ọlọ́run sí ohun tí ó ṣe pàtàkì ju gbogbo ohun yòó kù lọ, wọ́n sì ń wo ojú rẹ̀ láti san èrè ìwà àìlábòsí wọn fún wọn. (Òwe 30:8, 9; Kọ́ríńtì Kíní 10:13; Hébérù 13:18) Opó kan ní Íńdíà rí i pé mímúratán láti ṣiṣẹ́ àti mímọwọ́ọ́yípadà ran òun lọ́wọ́ láti gbọ́ bùkátà òun. Dípò jíjẹ́ kí ipò rẹ̀ nínú ìgbésí ayé mú un bínú, ó mọ̀ pé, bí òun bá fi Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé òun, Jèhófà yóò bù kún ìsapá òun láti rí àwọn ohun kòṣeémánìí fún ara òun àti ọmọkùnrin òun. (Mátíù 6:33, 34) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún kárí ayé fi hàn pé, láìka làásìgbò tí ó lè dojú kọ wọ́n sí, Jèhófà ni ibi ìsádi àti ibi odi agbára wọn. (Orin Dáfídì 91:2) Ìyẹn ha jẹ́ òtítọ́ nípa rẹ bí?
Ìgbà Tí Ó Sàn Jù Ń Bẹ Níwájú
Lẹ́yìn náà, nígbà tí ọba Babiloni sàgati Jerusalemu apẹ̀yìndà, àwọn ènìyàn níláti “jẹ àkàrà nípa ìwọ̀n, àti pẹ̀lú ìtọ́jú.” (Esekieli 4:16) Ipò náà burú débi pé àwọn obìnrin kan jẹ ẹran-ara àwọn ọmọ wọn tìkara wọn. (Ẹkún Jeremiah 2:20) Síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wòlíì Jeremiah wà ní àtìmọ́lé nítorí ìwàásù rẹ̀, Jehofa rí síi pé “a . . . fún [Jeremiah] ní ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan lójoojúmọ́, láti ìta àwọn alákàrà, títí gbogbo àkàrà fi tán ní ìlú.”—Jeremáyà 37:21.
Jehofa ha gbàgbé Jeremiah nígbà tí ìpèsè àkàrà tán bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́, níti pé nígbà tí ìlú náà ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Babiloni, Jeremiah ni a fún ní ‘owó oúnjẹ àti ẹ̀bùn; a sì jọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́wọ́.’—Jeremáyà 40:5, 6; tún wo Orin Dafidi 37:25.
MAY 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 39-43
“Jèhófà Máa San Olúkúlùkù Lẹ́san Níbàámu Pẹ̀lú Iṣẹ́ Rẹ̀”
it-2 1228 ¶4
Sedekáyà
Ìparun Jerúsálẹ́mù. Níkẹ̀yìn (607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni), “Ní ọdún kọkànlá Sedekáyà, ní oṣù kẹrin, ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà,” Àwọn ọmọ ogun Bábílónì gbógun wọ ìlú Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó di alẹ́, Sedekáyà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá lọ. Àmọ́, ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Bábílónì tẹ̀ wọ́n ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Jẹ́ríkò, wọ́n sì mú Sedekáyà lọ sọ́dọ̀ Nebukadinésárì ní Ríbúlà. Ìṣojú Sedekáyà ni wọ́n ṣe pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Sedekáyà kò ju nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32] lọ nígbà yẹn, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ náà kò tíì lè dàgbà púpọ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n pa àwọn ọmọ rẹ̀ níṣojú rẹ̀, wọ́n fọ́ ojú rẹ̀, wọ́n fi ṣẹkẹ́sẹkẹ̀ bàbà dè é, wọ́n mú un lọ sí Bábílónì, ó sì kú sínú àhámọ́ níbẹ̀.—2Ọb 25:2-7; Jer 39:2-7; 44:30; 52:6-11; fi wé Jer 24:8-10; Isk 12:11-16; 21:25-27.
it-2 482
Nebusarádánì
Nebusarádánì tẹ̀ lé àsẹ Nebukadinésárì, ó dá Jeremáyà sílẹ̀, ó bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, ó ní kó sọ ohun tó fẹ́, ó sì fún un ní àwọn nǹkan tó nílò. Nebusarádánì tún ṣojú fún ọba Bábílónì láti fi Gedaláyà jẹ gómìnà lórí àwọn tó ṣẹ́ kù. (2Ọb 25:22; Jer 39:11-14; 40:1-7; 41:10) Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ìyẹn 602 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Nebusarádánì kó àwọn Júù tó kù lọ sí ìgbèkùn; ó sì jọ pé àwọn tó sá lọ sí àwọn ìlú tó wà nítòsí ló kó lọ.—Jer 52:30.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ǹjẹ́ O Máa Ń Béèrè Pé “Jèhófà Dà?”
10 Ẹ̀yìn ìgbà tí wọ́n ti pa Jerúsálẹ́mù run táwọn ọmọ ogun Bábílónì sì kó àwọn Júù lọ sígbèkùn ni Jóhánánì gbára dì láti kó àwọn Júù bíi mélòó kan tó ṣẹ́ kù ní Júdà lọ sí Íjíbítì. Gbogbo ètò ti tò lórí bí wọ́n á ṣe rin ìrìn náà, àmọ́ kí wọ́n tó lọ wọ́n sọ pé kí Jeremáyà gbàdúrà fún àwọn kó sì béèrè ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ ṣá, ohun tí wọ́n fẹ́ kọ́ ni Jèhófà fi dá wọn lóhùn, síbẹ̀ wọ́n ranrí mọ́ ohun tí wọ́n ti dáwọ́ lé náà. (Jeremáyà 41:16–43:7) Nínú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, ǹjẹ́ o ti rí àwọn ẹ̀kọ́ tó lè ṣe ọ́ láǹfààní táá sì jẹ́ kó o rí Jèhófà nígbà tó o bá wá a?
it-1 463 ¶4
Ìṣírò àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀
Ní ọdún kẹsàn-án ìṣàkóso Sedekáyà ni wọ́n wá gbógun àjàkẹ́yìn ja ìlú Jerusálẹ́mù, ìyẹn ọdún 609 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìlú náà sì pa run ní ọdún kọkànlá ìṣàkóso Sedekáyà, ìyẹn ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Èyí sì jẹ́ ọdún kọkàndínlógún ìṣàkóso Nebukadinésárì (tá a bá ṣírò rẹ̀ láti ọdún 625 ṣáájú Sànmánì Kristẹni tó gorí ìtẹ́). (2Ọb 25:1-8) Ní oṣù karùn-ún ọdún yẹn, (oṣù Ábì, tó bọ́ sí àárín oṣù July àti August) wọ́n dáná sun ìlú náà, wọ́n wó àwọn ògiri rẹ̀, wọ́n sì kó èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn náà lọ sí ìgbèkùn. Àmọ́, kìkì “àwọn kan lára àwọn enìyàn rírẹlẹ̀ ilẹ̀ náà” ló ṣẹ́ kù síbẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n pa Gedaláyà tí Nebukadinésárì yàn sípò. Àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù náà sì sá lọ sí ìlú Íjíbítì, bí wọ́n ṣe pa ilẹ̀ Júdà run pátápátá nìyẹn. (2Ọb 25:9-12, 22-26) Èyí sì ṣẹlẹ̀ ní oṣù keje, ìyẹn Étánímù (tàbí Tíṣírì, tó bọ́ sí àárín oṣù September àti October). Torí náà, á jẹ́ pé àádọ́rin ọdún náà bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí oṣù October 1, ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì parí ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Oṣù keje ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni àwọn Júù kan kọ́kọ́ pa dà láti ìgbèkùn sí ilẹ̀ Júdà, ìyẹn sì jẹ́ àádọ́rin ọdún [70] lẹ́yìn tí ilẹ̀ náà ti di ahoro pátápátá.—2Kr 36:21-23; Ẹsr 3:1.
MAY 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 44-48
“Má Ṣe ‘Wá Àwọn Ohun Ńláńlá fún Ara Rẹ’ ”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 430
Kémóṣì
Nígbà tí wòlíì Jeremáyà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àjálù tó ń bọ̀ lórí ìlú Móábù, ó sọ pé wọ́n á kó olórí àwọn òrìṣà wọn tó ń jẹ́ Kémóṣì àtàwọn àlùfáà rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn. Ojú máa ti àwọn ará Móábù torí pé òrìṣà wọn o ní lè gbà wọ́n là, bí ojú ṣe ti ẹ̀yà mẹ́wàá ijọba Ísírẹ́lì nítorí Bẹ́tẹ́lì; ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé àwọn èèyàn ibẹ̀ ń lọ́wọ́ sí ìjọsìn ère ọmọ màlúù.—Jer 48:7, 13, 46.
it-2 422 ¶2
Móábù
Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Móábù pátá ló ṣẹ láìku síbì kan. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni kò ti sí àwọn tá à ń pè ní ará Móábù mọ́. (Jer 48:42) Lónìí, àwọn ìlú bíi Nébò, Héṣíbónì, Áróérì, Bẹti-gámúlì, àti Baali-Méónì, tó jẹ́ àwọn ìlú tó wà ní ilẹ̀ Móàbù ti di àwókù lásán-làsàn. Kò tiẹ̀ sẹ́ni tó mọ ibi táwọn ìlú tó kù wà.
MAY 29–JUNE 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 49-50
“Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Ó sì Ń Fìyà Jẹ Àwọn Agbéraga”
it-1 54
Ọ̀tá
Nígbà táwọn èèyàn Ọlọ́run di aláìṣòótọ́, ó gba àwọn ọ̀tá wọn láyè láti kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn, kí wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. (Sm 89:42; Ida 1:5, 7, 10, 17; 2:17; 4:12) Àmọ́, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kò yé àwọn ọ̀tá wọn, ńṣe ni wọ́n gbà pé àwọn òrìṣà àwọn ló ń jẹ́ kí àwọn ṣẹ́gun, tí wọ́n á sì máa yin àwọn òrìṣà náà, láìmọ̀ pé wọ́n ṣì máa jìyà ohun tí wọ́n fojú àwọn àwọn èèyàn Jèhófà rí. (Di 32:27; Jer 50:7) Èyí wá mú kí Jèhófà fìyà jẹ àwọn agbéraga tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀ yìí (Ais 1:24; 26:11; 59:18; Na 1:2); ó sì ṣe èyí nítorí orúkọ mímọ́ rẹ̀.—Ais 64:2; Isk 36:21-24.
Ìwé Kan Tí Ó Wá Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
20 Aísáyà ti kú kí Bábílónì tó di ahoro. Ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, Bábílónì di kìkì “ìtòjọpelemọ òkúta” nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Jeremáyà 51:37) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Jerome, tí ó jẹ́ Hébérù (tí a bí ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa), sọ, nígbà tí ó fi máa di ọjọ́ rẹ̀, Bábílónì ti di ibi ìṣọdẹ nínú èyí tí “àwọn ẹranko onírúurú” ti ń jẹ̀, ó sì wà ní ahoro títí di òní olónìí. Ìmúbọ̀sípò yòówù tí a bá ṣe sí Bábílónì láti sọ ọ́ di ibi àṣèbẹ̀wòsí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ lè sún àwọn ènìyàn láti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, “àtọmọdọ́mọ àti ìran àtẹ̀lé” Bábílónì ti pòórá títí láé.—Aísáyà 14:22.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 94 ¶6
Àwọn Ọmọ Ámónì
Ó jọ pé lẹ́yìn tí Tigilati-pílésà Kẹta àti ọ̀kan lára àwọn tó jọba lẹ́yìn rẹ̀ lé àwọn àrá àríwá ìṣàkóso ilẹ̀ Ísírẹ́lì kúrò nílùú (2Ọb 15:29; 17:6), àwọn ọmọ Ámónì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Gádì, wọ́n gbógun ti Jẹ́fútà, àmọ́ wọn ò lè ṣẹ́gun rẹ̀. (Fi wé Sm 83:4-8.) Torí náà, Jèhófà gbẹnu wòlíì Jeremáyà sọ pé ègbé ni fún àwọn ọmọ ámónì fún bí wọ́n ṣe gbẹ́sẹ̀ lé ogún àwọn ará Gádì àti pé ìparun ń bọ̀ lórí Ámónì àti Málíkámù tàbí Mílíkómù òrìṣà wọn. (Jer 49:1-5) Àwọn ọmọ Ámónì tún rán àwọn onísùnmọ̀mí láti halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà nígbà tí Ọba Jèhóákímù fi wà lórí oyè, ìyẹn sì jẹ́ nígbà tí ìjọba Júdà ń parí lọ.—2Ọb 24:2, 3.