May 8-14
Jeremáyà 35-38
Orin 33 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ebedi-mélékì Jẹ́ Onígboyà àti Onínúure”: (10 min.)
Jer 38:4-6—Ìbẹ̀rù èèyàn mú Sedekáyà, ó sì fọwọ́ sí i pé kí àwọn alátakò ju Jeremáyà sínú kòtò ẹlẹ́rẹ̀ kó lè kú síbẹ̀ (it-2 1228 ¶3)
Jer 38:7-10—Ebedi-mélékì lo ìgboyà, ó sì gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ láti ran Jeremáyà lọ́wọ́ (w12 5/1 31 ¶2-3)
Jer 38:11-13—Ebedi-mélékì jẹ́ onínúure (w12 5/1 31 ¶4)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jer 35:19—Kí nìdí tí Jèhófà fi bù kún àwọn ọmọ Rékábù? (it-2 759)
Jer 37:21—Báwo ni Jèhófà ṣe bójú tó Jeremáyà, báwo nìyẹn ṣe lè fún wa níṣìírí nígbà ìṣòro? (w98 1/15 18 ¶16-17; w95 8/1 5 ¶5-6)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jer 36:27–37:2
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn wp17.3—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn wp17.3—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) jl ẹ̀kọ́ 26
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa”: (15 min.) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá wo fídíò náà Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa, tẹ́ ẹ sì ti dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹni tó ń ṣojú ìjọ yín nínú ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba. (Tí ìjọ yín ò bá ní ẹni tó ń ṣojú fún yín, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Tó bá jẹ́ pé ìjọ yín nìkan ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹni tó ń bójú tó àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba.) Àwọn àtúnṣe wo lẹ ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba láìpẹ́ yìí, kí lẹ sì tún ń gbèrò láti ṣe? Tí ẹnì kan bá mọ bá a ṣe ń tún nǹkan ṣe tàbí tó bá fẹ́ máa ran àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lọ́wọ́ kó lè mọ bá a ṣe ń tún nǹkan ṣe, kí ni ẹni náà máa ṣe? Báwo ni tọmọdé tàgbà wa ṣe lè máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba, láìka ipò yòówù ká wà?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 12 ¶9-15, àwọn àpótí “Bí Ìtẹ̀síwájú Ṣe Bá Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Ṣe Iṣẹ́ Àbójútó” àti “Bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Jẹ Mọ́ Ìjọba Ọlọ́run”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 125 àti Àdúrà