Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
DECEMBER 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SEFANÁYÀ 1–HÁGÁÌ 2
“Ẹ Wá Jèhófà Kí Ọjọ́ Ìbínú Rẹ̀ Tó Dé”
Ẹ Wá Jèhófà Kí Ọjọ́ Ìbínú Rẹ̀ Tó Dé
5 O lè sọ pé: ‘Ìránṣẹ́ Ọlọ́run kúkú ni mí, mo ti ṣèyàsímímọ́, mo sì ti ṣèrìbọmi, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ṣé mi ò tíì ṣe gbogbo ohun tí a béèrè ni?’ Ká sòótọ́, lẹ́yìn yíya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, àwọn ohun mìíràn kù táa gbọ́dọ̀ ṣe. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ya ara rẹ̀ sí mímọ́, àmọ́ lọ́jọ́ Sefanáyà, àwọn èèyàn Júdà kò gbé ìgbé ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ tí wọ́n ṣe. Nítorí ìyẹn, orílẹ̀-èdè náà di àpatì. ‘Wíwá Jèhófà’ lónìí wé mọ́ níní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀, kí a sì dara pọ̀ mọ́ ètò rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Ó túmọ̀ sí mímọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn nǹkan, kí a sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀. A ń wá Jèhófà nípa fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ṣíṣàṣàrò lórí ohun táa kọ́, àti fífi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé wa. Bí a sì ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà nínú àdúrà àtọkànwá, táa sì ń tọ ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ fẹ́ ká máa tọ̀, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà yóò máa jinlẹ̀ sí i, ìfẹ́ yóò sì máa sún wa láti sìn ín ‘pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, àti ọkàn wa, àti okunra wa.’—Diutarónómì 6:5; Gálátíà 5:22-25; Fílípì 4:6, 7; Ìṣípayá 4:11.
6 Nǹkan kejì tó jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe, tí Sefanáyà 2:3 mẹ́nu kàn ni pé kí a “wá òdodo.” Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ló ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì kí a lè tóótun fún ìrìbọmi Kristẹni. Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo Ọlọ́run jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wa. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe dáadáa, àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti jẹ́ kí ayé yìí kó èèràn ràn wọ́n. Àwa náà mọ̀ pé kò rọrùn láti wá òdodo, nítorí pé àwọn èèyàn tí kò rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe, irọ́ pípa, àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì ló yí wa ká. Àmọ́, ìfẹ́ tó lágbára láti mú inú Jèhófà dùn lè borí ìtẹ̀sí èyíkéyìí láti wá ojú rere ayé yìí nípa fífẹ́ láti máa ṣe báyé ṣe ń ṣe. Júdà pàdánù ojú rere Ọlọ́run nítorí pé ó ń gbìyànjú láti ṣe bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká, tí wọ́n jẹ́ aláìnáání Ọlọ́run. Nítorí náà, dípò ṣíṣàfarawé ayé, ẹ jẹ́ kí á jẹ́ “aláfarawé Ọlọ́run,” ká máa mú “àkópọ̀ ìwà tuntun . . . tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin” dàgbà.—Éfésù 4:24; 5:1.
7 Kókó kẹta tí Sefanáyà orí kejì, ẹsẹ ìkẹta mẹ́nu kàn ni pé báa bá fẹ́ ká pa wá mọ́ lọ́jọ́ ìbínú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa “wá ọkàn-tútù.” Ojoojúmọ́ là ń bá àwọn ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọ̀dọ́ tí kò ní ọkàn-tútù rárá pàdé. Lójú tiwọn, ohun àbùkù ni kéèyàn jẹ́ ọlọ́kàn-tútù. Ẹni tó bá sì níwà ìtẹríba, ọ̀dẹ̀ ni wọ́n kà á sí. Wọ́n máa ń rinkinkin mọ́ nǹkan, tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, èrò tiwọn sì máa ń jọ wọ́n lójú jù. Ohun tí wọ́n bá pè ní “ẹ̀tọ́” wọn àti ìfẹ́ inú wọn ló gbọ́dọ̀ di ṣíṣe. Á mà kúkú burú o, bí àwa náà bá lọ ní irú ẹ̀mí wọ̀nyẹn! Àkókò rèé láti “wá ọkàn-tútù.” Lọ́nà wo? Nípa títẹríba fún Ọlọ́run, fífi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí rẹ̀, kí a sì máa ṣe ohun tó fẹ́.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Náhúmù, Hábákúkù àti Sefanáyà
1:8. Ó dà bíi pé àwọn kan nígbà ayé Sefanáyà “ń wọ aṣọ ilẹ̀ òkèèrè” káwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká bàa lè fẹ́ràn wọn. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ ló máa jẹ́ fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní táwọn náà bá fẹ́ máa ṣe ohun táá mú káyé fẹ́ràn wọn!
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Hágáì àti Ìwé Sekaráyà
2:9—Àwọn ọ̀nà wo ni ‘ògo ilé ìkẹyìn fi pọ̀ ju ti àtijọ́’? Ó kéré tán, èyí jẹ́ ní ọ̀nà mẹ́ta: iye ọdún tí tẹ́ńpìlì náà fi wà, ẹni tó kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀, àtàwọn tó wá síbẹ̀ láti jọ́sìn Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́ńpìlì ológo tí Sólómọ́nì kọ́ wà fún okòó lé nírínwó [420] ọdún, ìyẹn láti ọdún 1027 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, síbẹ̀ iye ọdún tí wọ́n fi lo “ilé ìkẹyìn” lé ní okòó dín ní ẹgbẹ̀ta [580] ọdún, ìyẹn látìgbà tí wọ́n ti parí rẹ̀ lọ́dún 515 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ìgbà tó pa run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Yàtọ̀ síyẹn, Mèsáyà, ìyẹn Jésù Kristi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú “ilé ìkẹyìn” náà, àwọn tó sì wá sínú rẹ̀ láti jọ́sìn Ọlọ́run pọ̀ ju àwọn tó wá sí ilé ti “àtijọ́” lọ.—Ìṣe 2:1-11.
DECEMBER 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SEKARÁYÀ 1-8
“Di Aṣọ Ọkùnrin Tó Jẹ́ Júù Mú”
“Nísinsìnyí Ẹ Jẹ́ Ènìyàn Ọlọ́run”
14 Àwọn wòlíì ìgbàanì méjì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn á ṣe máa wọlé wá ní ọjọ́ ìkẹyìn yìí kí wọ́n lè máa sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀. Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’ Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde lọ, ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò sì jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù.” (Aísá. 2:2, 3) Lọ́nà kan náà, wòlíì Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá yóò sì wá ní ti tòótọ́ láti wá Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Jerúsálẹ́mù àti láti tu Jèhófà lójú.” Ó ṣàpèjúwe wọn pé wọ́n jẹ́ “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” tí wọ́n di aṣọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí mú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, tí wọ́n sì ń sọ pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”—Sek. 8:20-23.
Wọ́n “Ń Tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà Lẹ́yìn Ṣáá”
14 Jésù Kristi sọ pé ẹni tó bá dúró ṣinṣin ti àwọn arákùnrin òun, òun ló ṣètìlẹ́yìn fún. (Ka Mátíù 25:40.) Ọ̀nà wo làwọn tó nírètí láti jogún ayé lè gbà ṣètìlẹ́yìn fáwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi? Ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n lè gbà ṣèyẹn ni pé kí wọ́n máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14; Jòh. 14:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé ń dín kù láti ọ̀pọ̀ ọdún báyìí, ńṣe ni iye àwọn àgùntàn mìíràn ń pọ̀ sí i. Táwọn tó nírètí láti gbé láyé bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, bóyá tí wọ́n tiẹ̀ ń di oníwàásù alákòókò kíkún, ṣe ni wọ́n ń ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹni àmì òróró nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé àǹfààní tá a sì ní láti fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lónírúurú ọ̀nà.
DECEMBER 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SEKARÁYÀ 9-14
“Dúró sí ‘Àfonífojì Àwọn Òkè Ńlá’ ”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Kò Sí Ohun Ìjà Tí a Ṣe sí Yín Tí Yóò Ṣàṣeyọrí
9 Àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà jẹ́ ká mọ ìdí táwọn orílẹ̀-èdè fi lòdì sáwa Kristẹni tòótọ́. Kíyè sí ohun tí Sekaráyà 12:3 sọ, ó ní: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di òkúta ẹrù ìnira sí gbogbo ènìyàn.” Jerúsálẹ́mù wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ? “Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run” ni Sekaráyà sàsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn Ìjọba ti ọ̀run, èyí tí Ọlọ́run pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sí. (Hébérù 12:22) Díẹ̀ lára àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró yìí tí wọ́n máa bá Mèsáyà náà jọba ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn yìí àtàwọn “àgùntàn mìíràn” ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run nígbà tí àkókò ṣì wà. (Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 11:15) Ìhà wo làwọn orílẹ̀-èdè kọ sí ìpè yìí? Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ti àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ olóòótọ́ lẹ́yìn lóde òní? Láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Sekaráyà orí kejìlá túmọ̀ sí. Èyí á jẹ́ kó lè dá wa lójú pé ‘kò sí ohun ìjà’ tí wọ́n lè fi bá àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tí wọ́n ti yara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run jà tí “yóò ṣe àṣeyọrí.”
10 Sekaráyà orí kejìlá ẹsẹ kẹta sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè yóò “fara bó yánnayànna.” Báwo lèyí ṣe ṣẹlẹ̀? Àṣẹ Ọlọ́run ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Ọwọ́ pàtàkì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere yìí torí pé ojúṣe wa ni. Àmọ́, kíkéde tá à ń kéde Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé jẹ́ “òkúta ẹrù ìnira” fáwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n ń gbìyànjú láti gbé òkúta yìí kúrò lọ́nà nípa ṣíṣèdíwọ́ fáwọn tó ń wàásù Ìjọba náà. Báwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń ṣèdíwọ́ yìí, wọ́n ti “fara bó yánnayànna.” Kódà, orúkọ wọn ti dèyí tó bà jẹ́ nítorí pé ńṣe ni gbogbo ètekéte wọn máa ń dà lé àwọn fúnra wọn lórí. Àwọn orílẹ̀-èdè kò lè pa àwọn tí ń fi òtítọ́ inú jọ́sìn Jèhófà lẹ́nu mọ́ nítorí àwọn olùjọsìn Jèhófà mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa kéde “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” ti Ìjọba Ọlọ́run kí ètò àwọn nǹkan yìí tó dópin. (Ìṣípayá 14:6) Nígbà tí ọkùnrin kan tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà rí bí wọn ṣe ń hùwà ìkà sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ó sọ fáwọn tó ń hùwà ìkà náà pé: ‘Ẹ kàn ń dara yín láàmù lásán ni pẹ̀lú bẹ́ ẹ ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn aráabí yìí. Wọn ò ní ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn láéláé. Ńṣe ni wọ́n á máa pọ̀ sí i ṣáá.’
Kò Sí Ohun Ìjà Tí a Ṣe sí Yín Tí Yóò Ṣàṣeyọrí
13 Ka Sekaráyà 12:7, 8. Ní Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, àwọn èèyàn máa ń lo àgọ́ dáadáa, pàápàá àwọn darandaran àtàwọn àgbẹ̀. Àwọn wọ̀nyí á sì nílò ààbò gan-an táwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá bá wá gbógun ja ìlú Jerúsálẹ́mù, nítorí pé àwọn ni wọ́n á kọ́kọ́ kàn. Ohun tí gbólóhùn náà “àgọ́ Júdà” túmọ̀ sí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ni pé, pápá gbalasa ni àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró wà lóde òní, kì í ṣe inú àwọn ìlú ńlá olódi. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń fi ìgboyà gbèjà àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Mèsáyà náà. “Àgọ́ Júdà” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun máa “kọ́kọ́” gbà là, torí pé àwọn ni Sátánì dìídì dojú ìjà kọ.
DECEMBER 25-31
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁLÁKÌ 1-4
“Ṣé Ìgbéyàwó Rẹ Ń Múnu Jèhófà Dùn?”
Jèhófà Kórìíra Ìwà Àdàkàdekè
19 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Málákì fi hàn pé àwọn ọkọ kan wà tí wọn kò ṣe àdàkàdekè sí àwọn aya wọn. Àwọn wọ̀nyí ‘ní èyí tí ó ṣẹ́ kù lára ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.’ (Ẹsẹ ìkẹẹ̀ẹ́dógún) Inú wa dùn pé irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ń ‘fi ọlá fún àwọn aya wọn’ kún inú ìjọ Ọlọ́run lóde òní. (1 Pétérù 3:7) Àwọn ọkọ wọ̀nyí kì í fìyà jẹ àwọn aya wọn. Wọ́n kórìíra àṣà ìbálòpọ̀ tí ń tẹ́ni lógo. Wọn kì í tàbùkù sí àwọn aya wọn nípa bíbá àwọn obìnrin mìíràn tage tàbí nípa wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn olóòótọ́ aya Kristẹni tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run àtàwọn òfin rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ètò àjọ Jèhófà. Irú àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ mọ ohun tí Ọlọ́run kórìíra. Wọ́n ń ronú, wọ́n sì ń gbégbèésẹ̀ tó fi hàn pé àwọn náà kórìíra nǹkan bẹ́ẹ̀. Máa fara wé wọn, máa “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso,” wàá sì rí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ gbà lọ́pọ̀ yanturu.—Ìṣe 5:29.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Málákì
1:10. Inú Jèhófà ò dùn sáwọn ẹbọ táwọn àlùfáà jẹgúdújẹrá yìí ń rú. Àwọn àlùfáà yìí máa ń gba owó fún iṣẹ́ tó kéré gan-an, bíi kí wọ́n ti ilẹ̀kùn tàbí kí wọ́n ṣáná sí ẹbọ orí pẹpẹ. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kó jẹ́ ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan tá a ní fún Ọlọ́run àti fún àwọn èèyàn ló ń sún wa jọ́sìn Ọlọ́run, tó sì ń mú ká máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, kó má sì ṣe jẹ́ nítorí owó!—Mátíù 22:37-39; 2 Kọ́ríńtì 11:7.