May 14-20
Máàkù 9-10
Orin 22 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìran Tó Ń Fún Ìgbàgbọ́ Lókun”: (10 min.)
Mk 9:1—Jésù ṣèlérí pé àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì òun máa rí ìran nípa ogo tí òun máa ní nínú Ìjọba náà (w05 1/15 12 ¶9-10)
Mk 9:2-6—Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù rí Jésù tí Ọlọ́run yí pa dà di ológo, ó ń bá “Èlíjà” àti “Mósè” sọ̀rọ̀ (w05 1/15 12 ¶11)
Mk 9:7—Ohùn Jèhófà gangan tó dún jẹ́rìí sí i pé Ọmọ òun ni Jésù (“ohùn kan” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 9:7, nwtsty)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mk 10:6-9—Ìlànà wo nípa ìgbéyàwó ni Jésù tẹnu mọ́? (w08 2/15 30 ¶8)
Mk 10:17, 18—Kí nìdí tí Jésù fi sọ fún ọkùnrin kan pé kó má pe òun ní “Olùkọ́ Rere”? (“Olùkọ́ Rere,” “Kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 10:17, 18, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mk 9:1-13
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w04 5/15 30-31—Àkòrí: Kí Ni Ìtúmọ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Jésù Sọ Tó Wà ní Máàkù 10:25?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ohun Tí Ọlọ́rùn Ti So Pọ̀ . . . ”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Ìfẹ́ àti Ọ̀wọ̀ Ń Mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 7 ¶20-28
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 66 àti Àdúrà