MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìfẹ́ Ni A Fi Ń Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀—Kọ Ìmọtara-Ẹni-Nìkan àti Ìbínú Sílẹ̀
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Jésù sọ pé ìfẹ́ la máa fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀. (Jo 13:34, 35) Tá a bá fẹ́ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn, àfi ká máa wá bí nǹkan ṣe máa dáa fún wọn, ká sì máa mú sùúrù fún wọn.—1Ko 13:5.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Tí ẹnì kan bá ṣe nǹkan tó dùn ẹ́ tàbí tó sọ̀rọ̀ tó múnú bí ẹ, ní sùúrù, ro ohun tó fà á àti ohun tó ṣe é ṣe kó tẹ̀yìn rẹ̀ yọ tó o bá ṣe ohun tó wà lọ́kàn rẹ.—Owe 19:11
Rántí pé aláìpé ni gbogbo wa, nígbà míì a máa ń ṣe ohun tá a máa kábàámọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn
Tètè yanjú èdèkòyédè
Báwo ni Láńre ṣe gba ọ̀rọ̀ tí Tọ̀míwá sọ sódì?
Báwo ni sùúrù ṣe ran Tọ̀míwá lọ́wọ́ láti má ṣe gbaná jẹ?
Báwo ni ọ̀rọ̀ tútù tí Tọ̀míwá sọ ṣe paná wàhálà tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀?
Àǹfààní wo la máa ṣe ìjọ tá ò bá gbaná jẹ tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá?