Ẹ̀KỌ́ 5
Dídánudúró Bó Ṣe Yẹ
DÍDÁNUDÚRÓ níbi tó tọ́ ṣe kókó nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀. Yálà àsọyé là ń sọ o tàbí ẹnì kan là ń bá sọ̀rọ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká dánu dúró níbi tó ti tọ́. Láìlo ìdánudúró wọ̀nyẹn, ńṣe lọ̀rọ̀ rẹ á dà bí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ wótòwótò bí ẹyẹ ẹ̀gà dípò kó gbé èrò tó yéni kedere jáde. Lílo ìdánudúró bó ṣe yẹ á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yéni yékéyéké. O sì tún lè lò ó lọ́nà tí yóò fi mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ má ṣe gbàgbé àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ.
Báwo lo ṣe lè mọ ìgbà tó yẹ kó o dánu dúró? Báwo ló ṣe yẹ kó o máa dánu dúró pẹ́ tó?
Dánu Dúró Níbi Àmì Ìpíngbólóhùn. Àmì ìpíngbólóhùn ti di apá tó ṣe pàtàkì nínú àwọn èdè tí a máa ń kọ sílẹ̀. Ó lè fi hàn pé gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tàbí ìbéèrè kan ti parí. Àwọn èdè kan máa ń lò ó láti fi ya ọ̀rọ̀ tó jẹ́ àyọlò sọ́tọ̀. Àwọn àmì ìpíngbólóhùn kan máa ń fi bí apá kan nínú gbólóhùn ṣe jẹ́ sí ìyókù gbólóhùn náà hàn. Bí ẹnì kan bá ń dá kàwé, yóò ti fojú ara rẹ̀ rí àwọn àmì ìpíngbólóhùn ibẹ̀. Àmọ́ bí ó bá ń kàwé sétígbọ̀ọ́ àwọn ẹlòmíràn, dandan ni kí ohùn rẹ̀ gbé ìtumọ̀ àwọn àmì ìpíngbólóhùn yòówù kó wà nínú ìwé yẹn yọ. (Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, wo Ẹ̀kọ́ 1, “Kíkàwé Lọ́nà Tó Tọ́.”) Àìdánudúró nígbà tí àmì ìpíngbólóhùn bá fi hàn pé o yẹ bẹ́ẹ̀ lè mú kí àwọn olùgbọ́ má fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tó o kà tàbí kó tiẹ̀ da ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó o kà rú.
Láfikún sí àmì ìpíngbólóhùn, ọ̀nà tí a gbà gbé èrò inú gbólóhùn yọ máa ń pinnu ibi tó ti yẹ kéèyàn dánu dúró. Gbajúgbajà akọrin kan sọ nígbà kan rí pé: “Mi ò mọ dùùrù tẹ̀ ju ọ̀pọ̀ atẹdùùrù lọ. Ṣùgbọ́n bí mo ṣe máa ń dáwọ́ dúró sí láàárín ọ̀rọ̀ orin ni wọ́n fi gbà mí lọ́gàá.” Bákan náà ni ti ọ̀rọ̀ sísọ ṣe jẹ́. Dídánudúró bó ṣe yẹ yóò buyì kún ọ̀rọ̀ tó o ti múra rẹ̀ dáadáa, yóò sì jẹ́ kó nítumọ̀.
Nígbà tó o bá ń múra láti kàwé sétígbọ̀ọ́ àwùjọ, o lè rí i pé á dára kí o sàmì sí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí o máa kà. Fa ẹyọ ìlà kúkúrú kan lóòró síbi ọ̀rọ̀ tí o ti fẹ́ dánu dúró ṣíún, bóyá tó o ti máa dákẹ́ si-i lásán. Fa ìlà méjì pa pọ̀ lóòró síbi tó o ti máa dánu dúró pẹ́ díẹ̀ sí i. Bó bá di pé ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ àwọn ibì kan fẹ́ ni ọ́ lára láti kà, tó ń mú kó o dánu dúró níbi tí kò yẹ, fi pẹ́ńsù fa ìlà kan láti fi kó àwọn ọ̀rọ̀ tó nira fún ọ yẹn pọ̀. Lẹ́yìn náà kí o wá ka àpólà ọ̀rọ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ọ̀pọ̀ àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tó ti ń bá ọ̀rọ̀ sísọ bọ̀ tipẹ́ máa ń ṣe bẹ́ẹ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ sísọ ojoojúmọ́, kì í sábà ṣòro fún ọ láti dánu dúró bó ṣe yẹ nítorí pé o kúkú ti mọ àwọn ohun tó o fẹ́ sọ. Àmọ́ tó bá ti dàṣà rẹ pé o máa ń dánu dúró lóòrèkóòrè, níbi tó yẹ àti níbi tí kò yẹ, ọ̀rọ̀ rẹ kò ní tani jí kò sì ní yéni dáadáa. A dámọ̀ràn bí o ṣe lè ṣàtúnṣe nínú Ẹ̀kọ́ 4, “Kí Ọ̀rọ̀ Yọ̀ Mọ́ni Lẹ́nu.”
Dánu Dúró fún Yíyí Èrò Padà. Tí o bá dánu dúró nígbà tó o fẹ́ ti orí kókó pàtàkì kan bọ́ sí òmíràn, á fún àwọn olùgbọ́ rẹ láǹfààní láti ronú, láti múra ọkàn wọn sílẹ̀, láti mọ̀ pé o fẹ́ mú ohun mìíràn sọ, èrò tó o tún máa sọ tẹ̀ lé e yóò sì túbọ̀ yé wọn kedere. Bí ó ti ṣe pàtàkì pé kí o rọra rìn bí o bá fẹ́ ṣẹ́ kọ́nà náà ló ṣe ṣe pàtàkì láti dánu dúró nígbà tó o bá ń ti orí èrò kan bọ́ sí òmíràn.
Ìdí kan tí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan fi máa ń kánjú fò láti orí èrò kan bọ́ sórí òmíràn láìdánudúró ni pé ohun tí wọ́n fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí ti pọ̀ jù. Ní ti àwọn kan, ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ wọn ojoojúmọ́ ló bá wọn débẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí gbogbo àwọn tó wà yí wọn ká pẹ̀lú ṣe ń sọ̀rọ̀ nìyẹn. Àmọ́ ìyẹn kì í jẹ́ kéèyàn lè kọ́ni lọ́nà tó múná dóko. Bí ohun tó o fẹ́ sọ bá ṣe pàtàkì, tí o kò sì fẹ́ kí àwọn tó gbọ́ ọ gbàgbé, ńṣe ni kó o kúkú fara balẹ̀ dáadáa láti mú kí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe kedere. Mọ̀ dájú pé ìdánudúró ṣe pàtàkì fún ọ̀rọ̀ tó bá máa gbin èrò tó ṣe kedere síni lọ́kàn.
Bí o bá máa lo ìlapa èrò láti fi sọ ọ̀rọ̀ rẹ, ó yẹ kí o ṣètò ọ̀rọ̀ rẹ lọ́nà tó jẹ́ pé ibi tó o ti máa dánu dúró láàárín àwọn kókó pàtàkì yóò ti hàn gbangba. Bó bá jẹ́ iṣẹ́ oníwèé kíkà ni iṣẹ́ rẹ, sàmì sí àwọn ibi tí o ti máa ti orí kókó pàtàkì kan bọ́ sí èyí tó tẹ̀ lé e.
Bí a ṣe ń dánu dúró nígbà tí a bá fẹ́ yí èrò padà sábà máa ń gùn ju bí a ṣe ń dánu dúró nítorí àmì ìpíngbólóhùn lọ, àmọ́, kò ní gùn débi pé kí ọ̀rọ̀ máa falẹ̀. Bí wọ́n bá gùn jù, ńṣe ló máa mú kó dà bíi pé o kò múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ tó bó ṣe yẹ ló jẹ́ kó o máa fọgbọ́n wá ohun tó o tún máa sọ.
Dánu Dúró Láti Fi Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀. Ìdánudúró tí a fi ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ sábà máa ń pàfiyèsí, ìyẹn, ìdánudúró tó máa ń wà ṣáájú tàbí èyí tó máa ń wà ní kété tá a sọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tán tàbí kété tá a béèrè ìbéèrè pàtàkì kan tán. Irú ìdánudúró bẹ́ẹ̀ máa ń fún àwùjọ láǹfààní láti ronú lórí ohun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ, tàbí kó mú kí wọ́n ti máa retí ohun tí a fẹ́ sọ. Iṣẹ́ kan náà kọ́ là ń fi méjèèjì ṣe o. Yan ọ̀nà tó bá bá a mu jù lọ fún ọ láti lò nínú méjèèjì. Ṣùgbọ́n fi í sọ́kàn pé inú kìkì àwọn gbólóhùn tó bá ṣe pàtàkì nìkan ló yẹ ká ti máa lo ìdánudúró tí a fi ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn gbólóhùn wọ̀nyẹn kò ní rinlẹ̀ lọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ.
Nígbà tí Jésù ka Ìwé Mímọ́ sétígbọ̀ọ́ àwùjọ nínú sínágọ́gù ní Násárétì, ó lo ìdánudúró lọ́nà tó múná dóko. Ó kọ́kọ́ ka iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ látinú àkájọ ìwé wòlíì Aísáyà. Àmọ́ kí ó tó ṣàlàyé rẹ̀, ó ká àkájọ ìwé yẹn padà, ó dá a padà fún ẹni tó ń bójú tó o, ó sì jókòó. Lẹ́yìn náà, nígbà tí gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú sínágọ́gù ti tẹjú mọ́ ọn, ó ní: “Lónìí, ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí ní ìmúṣẹ.”—Lúùkù 4:16-21.
Dánu Dúró Nígbà Tí Ipò Nǹkan Bá Mú Kó Yẹ Bẹ́ẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìdíwọ́ lè mú kó di dandan fún ọ láti dánu dúró. Ariwo ọkọ̀ tí ń kọjá lọ tàbí ọmọ tó ń sunkún lè mú kó di dandan pé kí o dánu dúró nígbà ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú onílé kan lóde ẹ̀rí. Bí ìdíwọ́ tó wáyé níbi àpéjọ kan kò bá pọ̀ jù, bóyá o kàn lè gbóhùn sókè kí o sì máa bọ́rọ̀ rẹ lọ. Ṣùgbọ́n tí ariwo yẹn bá pọ̀ gan-an tí kò sì tún tètè dáwọ́ dúró, o gbọ́dọ̀ dánu dúró. Ìdí ni pé àwọn olùgbọ́ rẹ ò tiẹ̀ ní fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ pàápàá. Nípa bẹ́ẹ̀, dánu dúró bó ṣe yẹ, kí o lè fi mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní àwọn nǹkan tó lárinrin tó o fẹ́ sọ fún wọn.
Dánu Dúró Kí Olùgbọ́ Lè Fèsì. Lóòótọ́ o, ó lè máà sí ibi tí wọ́n ti dìídì sọ ọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ, pé kí àwùjọ dá sí i, síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì pé kí o fún àwùjọ láyè láti dáhùn ọ̀rọ̀ sínú ara wọn láìjẹ́ pé wọ́n dáhùn síta. Bí o bá béèrè ìbéèrè tó yẹ kó mú kí àwùjọ ronú ṣùgbọ́n tí o kò dánu dúró pẹ́ tó bó ṣe yẹ, àwọn ìbéèrè yẹn kò ní fi bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní bó ṣe yẹ.
Ó dájú pé kì í ṣe ìgbà téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle nìkan ló ṣe pàtàkì pé kí èèyàn máa dánu dúró nínú ọ̀rọ̀, ó ṣe pàtàkì nígbà tí a bá ń wàásù fúnni pẹ̀lú. Ó dà bíi pé sísọ̀rọ̀ lọ gbuurugbu láìdánudúró ti mọ́ àwọn kan lára. Bí ìyẹn bá jẹ́ ìṣòro rẹ, sapá gidigidi láti fi dídánudúró nínú ọ̀rọ̀ sísọ kọ́ra. Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn á túbọ̀ sunwọ̀n sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá lè túbọ̀ kọ́ni lọ́nà tó já fáfá lóde ẹ̀rí. Ìdánudúró ni pé kéèyàn dákẹ́ ọ̀rọ̀ fúngbà kúkúrú, bẹ́ẹ̀ òótọ́ ọ̀rọ̀ táwọn kan sọ ni pé, dídákẹ́ fúngbà díẹ̀ máa ń jẹ́ kí èèyàn ráyè sinmẹ̀dọ̀, ó ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹni rinlẹ̀, ó ń pàfiyèsí ẹni, ó sì ń jẹ́ kí etí sinmi.
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ojoojúmọ́, ńṣe làwọn èèyàn jọ máa ń sọ èrò ọkàn wọn fún ara wọn. Bí o bá ń fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn, tí o sì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n sọ, àwọn náà á fẹ́ gbọ́ tìrẹ pẹ̀lú. Èyí ń béèrè pé kí o dánu dúró pẹ́ tó, kí wọ́n lè rí àyè ṣàlàyé ara wọn.
Lóde ẹ̀rí, iṣẹ́ ìwàásù wa sábà máa ń wọni lọ́kàn dáadáa tí a bá sọ ọ́ di ìfọ̀rọ̀wérọ̀. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí rí i pé, tí àwọn àti onílé bá ti kíra tán, ó máa ń dára láti sọ kókó tí àwọn fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí kí wọ́n sì béèrè ìbéèrè kan. Wọ́n á dánu dúró kí onílé lè fèsì, wọ́n á sì wá fi hàn pé àwọn gbọ́ ohun tí onílé wí. Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà, wọn lè fọ̀rọ̀ lọ onílé lọ́pọ̀ ìgbà kí ó lè sọ sí ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n mọ̀ pé ó túbọ̀ máa ń rọrùn láti ranni lọ́wọ́ nígbà tí àwọn bá mọ ohun tí onítọ̀hún ń rò nípa kókó tí àwọn ń sọ̀rọ̀ lé lórí.—Òwe 20:5.
Lóòótọ́ o, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa dáhùn sí ọ̀rọ̀ wa lọ́nà tó tẹni lọ́rùn. Ṣùgbọ́n ìyẹn kò sọ pé kí Jésù máà dánu dúró pẹ́ kí àwọn èèyàn lè ráyè sọ̀rọ̀ tiwọn, títí kan àwọn alátakò rẹ̀ pàápàá. (Máàkù 3:1-5) Bí a bá fún ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ láyè láti sọ̀rọ̀, ó máa ń mú kí onítọ̀hún ronú, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ sọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn rẹ̀. Ní tòótọ́, ọ̀kan nínú ète iṣẹ́ ìwàásù wa ni láti sọ àwọn kókó pàtàkì inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí àwọn èèyàn ní láti ṣèpinnu lé lórí, ní ọ̀nà tí yóò ta ọkàn wọn jí, kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́.—Héb. 4:12.
Dídánudúró bó ṣe yẹ lóde ẹ̀rí dà bí iṣẹ́ ọnà kan. Bí a bá lo ìdánudúró bó ṣe yẹ, ó máa ń mú kí ohun tí à ń sọ túbọ̀ yéni kedere, kó má sì ṣeé gbàgbé.