ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 1 ojú ìwé 83-ojú ìwé 85 ìpínrọ̀ 3
  • Kíkàwé Lọ́nà Tó Tọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkàwé Lọ́nà Tó Tọ́
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Dídánudúró Bó Ṣe Yẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Bíbélì Kíkà—Ó Lérè, Ó Sì Gbádùn Mọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 1 ojú ìwé 83-ojú ìwé 85 ìpínrọ̀ 3

Ẹ̀KỌ́ 1

Kíkàwé Lọ́nà Tó Tọ́

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o máa ka ọ̀rọ̀ inú ìwé sókè bó ṣe wà níbẹ̀ gẹ́lẹ́. Kí o má fo ọ̀rọ̀, kí o má pe ọ̀rọ̀ láàbọ̀, kí o má sì ṣi ọ̀rọ̀ pè. Kí o pe ọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́. Kí o ṣàkíyèsí àmì ìpíngbólóhùn, àmì orí ọ̀rọ̀ àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Ìdí ni pé apá pàtàkì nínú mímú kí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ Bíbélì di mímọ̀ wé mọ́ fífarabalẹ̀ kàwé, kéèyàn sì kà á bí ó ṣe tọ́.

ÌWÉ MÍMỌ́ sọ pé ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run pé kí gbogbo onírúurú èèyàn “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Nípa bẹ́ẹ̀, bí a bá ń ka Bíbélì sókè, ó yẹ kí bí a ṣe fẹ́ fi ìmọ̀ tó péye kọ́ni hàn nínú ọ̀nà tí a gbà ń kà á.

Tèwe tàgbà ló ṣe pàtàkì fún pé kó mọ bí a ṣe ń ka Bíbélì àtàwọn ìwé mìíràn tó ṣàlàyé Bíbélì, sókè. Bí a ṣe jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ti di ojúṣe wa pé ká mú ìmọ̀ Jèhófà àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ àwọn ẹlòmíràn lọ. Ìyẹn sì sábà máa ń gba pé ká kàwé sétígbọ̀ọ́ ẹnì kan tàbí àwùjọ kékeré kan. A tún máa ń kàwé láàárín agbo ìdílé pẹ̀lú. Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àǹfààní wà fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin lọ́mọdé lágbà láti gba ìmọ̀ràn nípa bí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kàwé sókè ṣe lè túbọ̀ sunwọ̀n sí i.

Ọwọ́ pàtàkì ló yẹ ká fi mú kíka Bíbélì ní gbangba, ì báà jẹ́ ẹyọ ẹnì kan là ń kà á fún tàbí à ń kà á fún ìjọ. Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì. Àti pé, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Héb. 4:12) Ìmọ̀ iyebíye tí a kò lè rí níbòmíràn rárá ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó lè múni mọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà kí ó sì sọni di ẹni tí àárín òun àti Ọlọ́run dán mọ́rán, àti ẹni tó mọ bí a ṣe lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Ó ṣàlàyé ọ̀nà tó ń sinni lọ sí ìyè ayérayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Nítorí náà, ńṣe ló yẹ ká máa lépa ọ̀nà tá a lè máa gbà ka Bíbélì lọ́nà tó dán mọ́ràn jù lọ.—Sm. 119:140; Jer. 26:2.

Bí A Ṣe Lè Kàwé Lọ́nà Tó Tọ́. Oríṣiríṣi nǹkan ló wé mọ́ kíkàwé lọ́nà tó mọ́yán lórí, àmọ́ mímọ ìwé kà lọ́nà tó tọ́ ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Ìyẹn ni pé kéèyàn rí i pé òun ka ọ̀rọ̀ inú ìwé jáde gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ síbẹ̀. Kó rí i pé òun ò fo ọ̀rọ̀, òun ò pe ọ̀rọ̀ láàbọ̀, òun ò sì fi ọ̀rọ̀ kan pe òmíràn nítorí pé wọ́n jọra.

Láti lè ka ọ̀rọ̀ inú ìwé bó ṣe tọ́, o ní láti kọ́kọ́ lóye ohun tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ yẹn ṣàlàyé. Ìyẹn yóò gba fífarabalẹ̀ múra sílẹ̀. Láìpẹ́, bí o ṣe ń dẹni tó mọ bí a ṣe ń fojú kó ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ kà lẹ́ẹ̀kan pa pọ̀, kí o sì kà á lọ́nà tó bá èrò tí a ti ń bá bọ̀ mu, ìwé kíkà rẹ á máa túbọ̀ dán mọ́rán sí i.

Àmì ìpíngbólóhùn àti àmì orí ọ̀rọ̀ àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀ jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì gan-an nínú èdè tí ó ṣeé kọ sílẹ̀. Àmì ìpíngbólóhùn lè sọ ibi tí a ó tí dánu dúró díẹ̀, bí ìdánudúró yẹn ṣe yẹ kó gùn tó, àti ibi tó yẹ ká ti yí ohùn padà. Nínú àwọn èdè kan, bí èèyàn kò bá yí ohùn padà níbi tí àmì ìpíngbólóhùn ti fi hàn pé ó yẹ bẹ́ẹ̀, ó lè mú kí ọ̀rọ̀ tó jẹ́ ìbéèrè dún bíi gbólóhùn kan ṣákálá, tàbí kó tiẹ̀ kúkú yí ìtumọ̀ rẹ̀ padà. Àmọ́, nígbà mìíràn, ó kàn lè jẹ́ òfin ẹ̀hun èdè ló jẹ́ ká fi àmì ìpíngbólóhùn sí àwọn ibì kan nínú ọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ló jẹ́ pé èèyàn ò lè kà lọ́nà tó tọ́ láìjẹ́ pé ó fẹ̀sọ̀ kíyè sí àmì orí ọ̀rọ̀ àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀, ì báà jẹ́ èyí tí wọ́n ti fi sí ọ̀rọ̀ inú ìwé tàbí èyí tí ọ̀rọ̀ tí ìwé ń bá bọ̀ fi hàn pé ó yẹ ká lò. Àmì wọ̀nyí máa ń nípa lórí bí a ṣe máa pe ọ̀rọ̀ tá a fi wọ́n sí. Rí i dájú pé o mọ ìlò àmì ìpíngbólóhùn, àmì orí ọ̀rọ̀ àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀ ti èdè rẹ dunjú. Èyí ni yóò jẹ́ kó o lè kàwé lọ́nà tó nítumọ̀. Rántí pé kì í ṣe pé kí o kàn ṣáà ti pe ọ̀rọ̀ sókè ni ohun tí ò ń lépa, bí kò ṣe pé o fẹ́ gbé èrò òǹkọ̀wé yọ.

Láti lè dẹni tó ń kàwé lọ́nà tó tọ́, o ní láti máa fi ìwé kíkà dánra wò. Kọ́kọ́ ka ìpínrọ̀ kan ṣoṣo, kí o sì kà á léraléra títí yóò fi yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu láìsí pé ò ń kọsẹ̀ rárá. Lẹ́yìn náà, kọjá sí ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e. Níkẹyìn, gbìyànjú láti ka ojú ewé mélòó kan láìfo ọ̀rọ̀ kankan, láìtún ọ̀rọ̀ pè, láìṣi ọ̀rọ̀ kankan pè. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe gbogbo ìyẹn tán, wá sọ pé kí ẹnì kan tẹ́tí sí bí o ṣe ń kàwé, kí ó sì sọ àwọn àṣìṣe rẹ fún ọ.

Ní àwọn apá ibì kan láyé, ìṣòro ojú àti àìní iná tó mọ́lẹ̀ tó kì í jẹ́ kí àwọn èèyàn lè kàwé geerege. Bí a bá lè bójú tó ìṣòro wọ̀nyí bó ṣe yẹ, ó dájú pé á jẹ́ kí ìwé kíkà wa túbọ̀ já gaara.

Bí àkókò ti ń lọ, àwọn arákùnrin tó bá mọ ìwé kà dáadáa lè dẹni tó ń kàwé fún àwùjọ ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ṣùgbọ́n béèyàn yóò bá ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe tọ́ níbẹ̀, ohun tí yóò ṣe ju pé kó kàn ṣáà ti mọ bí a ṣe ń pe ọ̀rọ̀ inú ìwé sókè lọ́nà tó tọ́. Kí o tó di ògbóṣáṣá òǹkàwé fún àwùjọ nínú ìjọ, o ní láti kọ́kọ́ dẹni tó ti ń dá kàwé lọ́nà tó dán mọ́rán ná. Èyí wé mọ́ mímọ̀ pé ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan nínú gbólóhùn ló ní ipa tó ń kó. O kò lè fo àwọn kan lára wọn kí o wá ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye ohun tí gbólóhùn yẹn ń sọ. Bí o bá ń ṣi ọ̀rọ̀ kà, kódà nígbà tó o bá ń dá kàwé, ìtumọ̀ gbólóhùn yẹn kò ní ṣe kedere. Èèyàn lè ṣi ọ̀rọ̀ kà bí kò bá kíyè sí àwọn àmì òrí ọ̀rọ̀ àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀ tàbí kó ṣàkíyèsí inú gbólóhùn tí a ti lò ó. Ṣakitiyan láti lóye ohun tí ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan túmọ̀ sí láàárín àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí a ti lò ó. Tún ṣàkíyèsí bí àmì ìpíngbólóhùn ṣe nípa lórí ìtumọ̀ gbólóhùn yẹn. Rántí pé àpapọ̀ ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ló sábà máa ń gbé èrò yọ. Ṣàkíyèsí nǹkan wọ̀nyí, kí ó fi lè jẹ́ pé nígbà tó o bá ń kàwé sókè, ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ni wàá máa kà, ìyẹn àwọn àpólà ọ̀rọ̀ àti awẹ́ gbólóhùn, dípò kíka ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan lásán. Ohun pàtàkì àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ kó o lè gbin ìmọ̀ pípéye sí àwọn èèyàn lọ́kàn tó o bá ń kàwé fún àwùjọ ni pé kí ìwọ fúnra rẹ lóye ohun tó ò ń kà yékéyéké.

Kristẹni tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ alàgbà ni ẹni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba.” (1 Tím. 4:13) Dájúdájú gbogbo wa ló yẹ kó túbọ̀ máa ṣe dáadáa sí i nínú ìwé kíkà.

ÀMÌ TÍ A FI Ń PÍN GBÓLÓHÙN

Àmì ìdánudúró pátápátá (.) ó ń fi hàn pé ká dánu dúró pátápátá.

Àmì ìdánudúró díẹ̀ (,) ó sábà máa ń fi hàn pé kéèyàn dánu dúró díẹ̀ láàárín gbólóhùn nítorí ọ̀rọ̀ ṣì wà níwájú.

Àmì òǹkà ọ̀rọ̀ (;) ó jẹ́ àmì pé kéèyàn dánu dúró pẹ́ díẹ̀ ju ti àmì ìdánudúró díẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n a kó ní dúró pẹ́ tó ti àmí ìdánudúró pátápátá.

Àmì òǹkà gbólóhùn (:) a máa ń lò ó láti fi hàn pé a fẹ́ to àwọn àpẹẹrẹ nǹkan sílẹ̀ tàbí pé a fẹ́ fa ọ̀rọ̀ yọ; èèyàn ní láti dánu dúró díẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní dín ohùn kù.

Àmì ìyanu (!) ó máa ń hàn nínú ohùn pé nǹkan yani lẹ́nu gidigidi.

Àmì ìbéèrè (?) ó sábà máa ń gba pé kéèyàn ṣe bí ẹní gbóhùn sókè tábì kó yí ohùn padà níparí gbólóhùn yẹn.

Àmì àyọlò (“ “ tàbí ‘ ‘) ó lè fi hàn pé kéèyàn dánu dúró díẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ọ̀rọ̀ tí a bá fi yà sọ́tọ̀ (ìdánudúró díẹ̀ ṣíún ni o, tó bá wà láàárín ọ̀rọ̀; àmọ́ tó bá wà ní ìparí ọ̀rọ̀, a óò túbọ̀ dánu dúró pẹ́ díẹ̀).

Dáàṣì (—), nígbà tí a bá lò ó láti fi ya ọ̀rọ̀ sọ́tọ̀, ó sábà máa ń gba pé kéèyàn yí ohùn padà díẹ̀ tàbí kó yí ìwọ̀n ìyára kàwé rẹ̀ padà.

Àkámọ́ kọdọrọ ( ) àti àmì àkámọ́ onígun [ ] lè ya ọ̀rọ̀ kan sọ́tọ̀, ńṣe la sì máa ń rẹ ohùn sílẹ̀ díẹ̀ láti ka ọ̀rọ̀ yẹn. A kì í sábà ka àwọn ìtọ́ka kan tó bá wà nínú àwọn àkámọ́ kọrọdọ, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni kò sídìí láti yí ohùn padà tí a bá ń ka ọ̀rọ̀ inú àkámọ́ onígun tá a bá fi parí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ inú ìwé tí à ń kà.

BÍ O ṢE LÈ DẸNI TÓ Ń KÀWÉ LỌ́NÀ TÍTỌ́

  • Máa fi ìwé kíkà dánra wò! Kà á lemọ́lemọ́! Kà á nígbà gbogbo! Kó o sì rí i pé ò ń kà á sókè.

  • Sọ pé kí ẹnì kan tẹ́tí sí bó o ṣe ń kà á kó sì sọ àwọn àṣìṣe rẹ fún ọ.

  • Nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, fi kọ́ra láti máa fara balẹ̀ kàwé.

  • Dípò tí wàá fi máa ka ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, kọ́ bí o ṣe lè máa ka ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà.

ÌDÁNRAWÒ: Tó o bá ti fúnra rẹ múra sílẹ̀ dáadáa tán, ní kí ọ̀rẹ́ rẹ kan tàbí ẹnì kan látinú ìdílé rẹ ṣí Bíbélì tirẹ̀ kó máa fojú bá ọ lọ bó o ṣe ń ka àwọn ibì kan nínú Mátíù orí karùn-ún sí ìkeje. Ní kó dá ọ dúró nígbàkigbà tó o bá ti (1) fo ọ̀rọ̀ kan, (2) tó ò bá pe ọ̀rọ̀ kan dáadáa tàbí tó o gbé wọn fúnra wọn, tàbí (3) tó o bá ṣi ọ̀rọ̀ pè nítorí àìwo àmì orí ọ̀rọ̀ tàbí ọmọ ìdí ọ̀rọ̀, tàbí nítorí àìtẹ̀lé àmì tó fi yẹ kó o dánu dúró bó ṣe yẹ tàbí àmì tó fi yẹ kó o yí ohùn padà. Yóò dára kó o ṣe èyí fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá ó kéré tán, lẹ́ẹ̀mejì tàbí ẹ̀ẹ̀mẹ́ta.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́