ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 21 ojú ìwé 150-ojú ìwé 152 ìpínrọ̀ 5
  • Fífi Ìtẹnumọ́ Yíyẹ Ka Ìwé Mímọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìtẹnumọ́ Yíyẹ Ka Ìwé Mímọ́
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Títẹnumọ́ Ọ̀rọ̀ Bó Ṣe Yẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Lílo Ìwé Mímọ́ Bí Ó Ti Yẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Títẹnumọ́ Àwọn Kókó Pàtàkì
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Fúnni Níṣìírí Láti Lo Bíbélì
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 21 ojú ìwé 150-ojú ìwé 152 ìpínrọ̀ 5

Ẹ̀KỌ́ 21

Fífi Ìtẹnumọ́ Yíyẹ Ka Ìwé Mímọ́

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn tó ń pe àfiyèsí sí ohun tó ò ń ṣàlàyé. Kí o kàwé bó ṣe yẹ lọ́nà tó fi bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára hàn.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Títẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ máa ń jẹ́ kí òye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kà yéni kedere.

NÍGBÀ tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ète Ọlọ́run, yálà nínú ilé ni o, tàbí látorí pèpéle, ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ kó o gbé ọ̀rọ̀ rẹ kà. Èyí sábà máa ń wé mọ́ kíka ẹsẹ Bíbélì, ó sì yẹ kí a kà á dáadáa.

Ìtẹnumọ́ Yíyẹ Wé Mọ́ Fífi Bí Ọ̀rọ̀ Ṣe Rí Lára Hàn. Ńṣe ni kí o ka Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára hàn. Gbé àwọn àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Tó o bá ń ka Sáàmù 37:11 sókè, ó yẹ kí ohùn rẹ dún lọ́nà tó fi hàn pé tayọ̀tayọ̀ lo fi ń retí àlàáfíà tí ẹsẹ yẹn ṣèlérí. Tó o bá ń ka Ìṣípayá 21:4, tó sọ̀rọ̀ nípa bí ìjìyà àti ikú yóò ṣe dópin, ó yẹ kí ohùn rẹ gbé ìmọrírì àtinúwá yọ nítorí ìtura ńláǹlà tí àsọtẹ́lẹ̀ ibẹ̀ ń sọ. Ohùn kánjúkánjú ló yẹ kí o fi ka Ìṣípayá 18:2, 4, 5, tó ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n jáde kúrò nínú “Bábílónì Ńlá” tí ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lọ́rùn. Àmọ́ ṣá, ńṣe ló yẹ kí o fi bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára hàn látọkànwá, kí o má sì ṣe é láṣejù. Ẹsẹ náà fúnra rẹ̀ àti bí o ṣe fẹ́ lò ó ló máa pinnu bí o ṣe máa fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára hàn tó nígbà tí o bá ń kà á.

Tẹnu Mọ́ Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Yẹ. Bó bá jẹ́ apá kan ẹsẹ Bíbélì kan lo kàn fẹ́ ṣàlàyé, apá yẹn ló yẹ kó o tẹnu mọ́ nígbà tó o bá ń ka ẹsẹ náà. Fún àpẹẹrẹ, tó o bá ń ka Mátíù 6:33, o ò ní tẹnu mọ́ “òdodo Rẹ̀” tàbí “gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí” bó bá jẹ́ pé ohun tí “wíwá ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́” túmọ̀ sí lo fẹ́ ṣàlàyé.

Bóyá o ń ronú láti ka Mátíù 28:19 nínú ọ̀rọ̀ kan tó o ní nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Àwọn ọ̀rọ̀ wo lo máa tẹnu mọ́? Bó bá jẹ́ pé ńṣe lo fẹ́ rọ àwọn ará láti jẹ́ aláápọn nínú bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, tẹnu mọ́ “máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.” Àmọ́, bó bá jẹ́ ojúṣe Kristẹni láti wàásù òtítọ́ Bíbélì fún àwọn àjèjì tó ṣí wá sílùú lo fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí, tàbí kẹ̀, bóyá o fẹ́ fún àwọn akéde kan níṣìírí láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, o lè tẹnu mọ́ “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.”

Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan dáhùn ìbéèrè tàbí ká fi ti kókó kan táwọn kan kà sí àríyànjiyàn lẹ́yìn. Bó bá jẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ yẹn la tẹnu mọ́ lọ́nà kan náà, àwùjọ lè máà rí bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọ̀hún ṣe tan mọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀. Kókó náà lè yé ọ, ṣùgbọ́n ó lè máà yé wọn.

Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń ka Sáàmù 83:18 nínú Bíbélì kan tó ní orúkọ Ọlọ́run nínú, bó bá jẹ́ gbólóhùn náà “Ẹni Gíga Jù Lọ” nìkan lo tẹnu mọ́, onílé lè máà rí òtítọ́ náà tí ìwọ rí kedere pé Ọlọ́run ní orúkọ tirẹ̀. Orúkọ náà “Jèhófà” ló yẹ kó o tẹnu mọ́. Ṣùgbọ́n o, tó o bá ń fi ẹsẹ kan náà ṣàlàyé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà, gbólóhùn náà “Ẹni Gíga Jù Lọ” ló yẹ kó o dìídì tẹnu mọ́. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, tó o bá ń lo Jákọ́bù 2:24 láti fi hàn pé ó ṣe pàtàkì láti fi iṣẹ́ kún ìgbàgbọ́, tó o sì wá lọ ń tẹnu mọ́ “polongo . . . ní olódodo” dípò títẹnumọ́ “àwọn iṣẹ́,” èyí lè dojú ọ̀rọ̀ rú lọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ.

Àpẹẹrẹ mìíràn tó lè ràn wá lọ́wọ́ wà nínú Róòmù 15:7-13. Èyí jẹ́ apá kan lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ kan tí àwọn Kèfèrí àtàwọn Júù àbínibí jọ wà. Àlàyé tí àpọ́sítélì náà ń ṣe níbí ni pé, kì í ṣe kìkì àwọn Júù tó dádọ̀dọ́ nìkan ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Kristi ṣe ṣàǹfààní fún, ó tún ṣe àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè láǹfààní pẹ̀lú, kí “àwọn orílẹ̀-èdè bàa lè yin Ọlọ́run lógo fún àánú rẹ̀.” Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mẹ́rin, láti pe àfiyèsí sí àǹfààní táwọn orílẹ̀-èdè ní yẹn. Báwo ló ṣe yẹ kó o ka ọ̀rọ̀ tó fà yọ wọ̀nyẹn, kí o lè tẹnu mọ́ kókó tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Bó o bá ń sàmì sí àwọn gbólóhùn tó o fẹ́ tẹnu mọ́, o lè sàmì sí “àwọn orílẹ̀-èdè” Ró 15 ní ẹsẹ kẹsàn-án, “ẹ̀yin orílẹ̀-èdè” ní Ró 15 ẹsẹ kẹwàá, “gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè” àti “gbogbo àwọn ènìyàn” ní Ró 15 ẹsẹ kọkànlá, àti “àwọn orílẹ̀-èdè” ní Ró 15 ẹsẹ kejìlá. Wá gbìyànjú láti ka Róòmù 15:7-13, kó o sì tẹnu mọ́ gbólóhùn wọ̀nyẹn. Bó o ti ń kà á bẹ́ẹ̀, gbogbo àlàyé Pọ́ọ̀lù á wá ṣe kedere, á sì rọrùn láti lóye.

Onírúurú Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀. Oríṣiríṣi ọ̀nà lo lè gbà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tí ń gbé èrò yọ tó o fẹ́ kó dún ketekete. Ó yẹ kí ọ̀nà tó o fẹ́ lò wà níbàámu pẹ̀lú ẹsẹ náà àti bó o ṣe fẹ́ gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀. Àbá mélòó kan rèé.

Fífi ohùn gbé ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yọ. Ó wé mọ́ yíyí ohùn padà láti lè jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ tí ń gbé èrò yọ dún yàtọ̀ sí ìyókù gbólóhùn náà. A lè ṣe ìtẹnumọ́ yìí nípa gbígbóhùn sókè tàbí rírẹ ohùn sílẹ̀. Nínú ọ̀pọ̀ èdè, yíyí ìró ohùn padà máa ń gbé ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yọ. Àmọ́ nínú àwọn èdè kan, ìyẹn lè yí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ padà pátápátá. Fífẹ̀sọ̀ pe àwọn gbólóhùn pàtàkì máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ tẹ̀wọ̀n lọ́kàn olùgbọ́. Nínú àwọn èdè tí ìlò ohùn kì í ti í ṣiṣẹ́ fún títẹnumọ́ àwọn ọ̀rọ̀ kan, yóò pọn dandan láti lo ọ̀nà èyíkéyìí tí wọ́n bá ń lò nínú èdè yẹn láti fi tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀.

Dídánudúró. A lè ṣe èyí ṣáájú tàbí lẹ́yìn kíka apá pàtàkì nínú ẹsẹ Bíbélì kan, tàbí ká tiẹ̀ ṣe é nígbà méjèèjì. Dídánudúró ní kété ṣáájú kí o tó ka kókó pàtàkì kan ń mú káwọn èèyàn kẹ́ etí sílẹ̀; dídánudúró lẹ́yìn kíkà á ń jẹ́ kó túbọ̀ wọni lọ́kàn ṣinṣin. Àmọ́ bí ìdánudúró bá wá pọ̀ jù, nǹkan kan ò ní dún yàtọ̀ mọ́ o.

Àsọtúnsọ. O lè tẹnu mọ́ kókó kan pàtó nípa dídá ara rẹ padà sẹ́yìn, kí o sì tún ọ̀rọ̀ yẹn tàbí gbólóhùn yẹn kà. Ọ̀nà kan tó máa ń dára jù ni láti kọ́kọ́ ka ẹsẹ náà tán, kí o tó wá padà tún gbólóhùn pàtàkì náà kà.

Ìfaraṣàpèjúwe. Lílo ara àti ojú sábà máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn kan túbọ̀ fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára hàn.

Ìró ohùn. Nínú àwọn èdè kan, nígbà mìíràn a máa ń tipa ohùn tá a fi ka ọ̀rọ̀ kan fún un nítumọ̀ ọ̀tọ̀, kí á sì tipa bẹ́ẹ̀ pàfiyèsí sí i. Èyí pẹ̀lú gba ọgbọ́n, pàápàá bí a bá fẹ́ fi bẹnu àtẹ́ lu nǹkan kan.

Tó Bá Jẹ́ Ẹlòmíràn Ló Kà Á. Tó bá jẹ́ onílé ló ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́, ó lè tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tí kò yẹ kó tẹnu mọ́, tàbí kí ó má tiẹ̀ tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ kankan. Kí wá ni o lè ṣe? Ó sábà máa ń dára jù lọ láti mú kí ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe kedere nípa ṣíṣàlàyé ẹsẹ náà. Lẹ́yìn àlàyé rẹ, o lè wá pe àfiyèsí pàtàkì sí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbé èrò yọ nínú ẹsẹ Bíbélì náà.

BÍ O ṢE LÈ MỌ Ọ̀RỌ̀Ọ́ TẸNU MỌ́

  • Nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o múra sílẹ̀ láti kà, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Èrò tàbí ẹ̀mí wo ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí gbé yọ? Báwo ni mo ṣe lè gbé e yọ?’

  • Ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ tó o fẹ́ láti lò. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pé: ‘Kí ni ète tí ẹsẹ yìí yóò ṣiṣẹ́ fún? Àwọn ọ̀rọ̀ wo ló yẹ ní títẹnumọ́ láti lè gbé ète yẹn yọ?’

ÌDÁRANWÒ: (1) Ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Bíbélì kan tó o fẹ́ lò lóde ẹ̀rí. Kà á léraléra lọ́nà tó o máa gbà fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára hàn bó ṣe yẹ. Bó o ṣe ń ronú nípa bó o ṣe fẹ́ lo ẹsẹ náà, kà á sókè, kí o sì tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tó yẹ kó o tẹnu mọ́. (2) Nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́, yan ìpínrọ̀ kan tá a ti fa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yọ. Ṣàyẹ̀wò bá a ṣe lo àwọn ẹsẹ yẹn. Sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ń gbé èrò yọ. Ka gbogbo ìpínrọ̀ náà sókè, lọ́nà tí wàá fi lè tẹnu mọ́ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ nínú ìpínrọ̀ náà bó ṣe yẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́