ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 6 ojú ìwé 101-ojú ìwé 104 ìpínrọ̀ 4
  • Títẹnumọ́ Ọ̀rọ̀ Bó Ṣe Yẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Títẹnumọ́ Ọ̀rọ̀ Bó Ṣe Yẹ
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Ìtẹnumọ́ Yíyẹ Ka Ìwé Mímọ́
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
    Jí!—1998
  • Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn
    Jí!—2020
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 6 ojú ìwé 101-ojú ìwé 104 ìpínrọ̀ 4

Ẹ̀KỌ́ 6

Títẹnumọ́ Ọ̀rọ̀ Bó Ṣe Yẹ

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ àti àpólà ọ̀rọ̀ lọ́nà tí òye ohun tí ò ń ṣàlàyé á fi tètè yé àwọn olùgbọ́ rẹ.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ máa ń jẹ́ kí àwùjọ fọkàn sí ọ̀rọ̀ olùbánisọ̀rọ̀, yóò sì tún jẹ́ kí ó lè rọ̀ wọ́n tàbí kí ó sún wọn láti ṣiṣẹ́ lé ohun tí wọ́n gbọ́.

NÍGBÀ tí o bá ń sọ̀rọ̀ tàbí tí o bá ń kàwé sétígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn, yàtọ̀ sí pé ó ṣe pàtàkì pé kí o pe ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan bó ṣe tọ́, ó tún jẹ́ ohun yíyẹ pé kí o tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn pàtàkì tó jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò gbé èrò ibẹ̀ yọ kedere.

Títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́ kò mọ sórí pé kó o kàn tẹnu mọ́ ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ díẹ̀ tàbí kó o tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ púpọ̀ pàápàá. Ọ̀rọ̀ tó yẹ gan-an lo ní láti tẹnu mọ́. Bó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò yẹ lò ń tẹnu mọ́, òye ohun tí ò ń sọ lè má ṣe kedere sí àwọn olùgbọ́ rẹ, ìyẹn sì lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fọkàn ro àwọn nǹkan mìíràn. Bí ó ti wù kí ohun tí ò ń sọ wúlò tó, bí o kò bá tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, kò ní lè ta àwùjọ jí kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́.

Onírúurú ọ̀nà la tún lè gbà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ síwájú sí i, a sì sábà máa ń lo àwọn ọ̀nà yẹn pa pọ̀, àwọn nìwọ̀nyí: títúbọ̀ gbóhùn sókè, fífi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára hàn lọ́nà tó ṣe kedere, mímọ̀ọ́mọ̀ pe ọ̀rọ̀ ketekete lọ́kọ̀ọ̀kan, dídánudúró kó o tó sọ gbólóhùn kan tàbí lẹ́yìn tó o sọ ọ́ tán tàbí kí o tilẹ̀ ṣe méjèèjì pa pọ̀ àti nípa lílo ìfaraṣàpèjúwe àti ìrísí ojú. Nínú àwọn èdè kan, a tún lè tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ nípa rírẹ ohùn sílẹ̀ tàbí ká mú kí ohùn túbọ̀ rinlẹ̀. Ronú nípa irú ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ àti ibi tó o ti máa sọ ọ́, kí o wá yan ọ̀nà tó máa bá a mu jù lọ láti lò.

Nígbà tó o bá fẹ́ yan ọ̀rọ̀ tó o máa tẹnu mọ́, fi àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí sọ́kàn. (1) Nínú gbogbo gbólóhùn tó o bá ń kà, ohun tó máa ń fi ọ̀rọ̀ tó o máa tẹnu mọ́ hàn kì í ṣe gbólóhùn tí ọ̀rọ̀ yẹn wà nìkan, àlàyé ọ̀rọ̀ tí ìwé yẹn ń bá bọ̀ tún wà lára ohun tí yóò fi í hàn. (2) A lè lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ láti fi gbé ìbẹ̀rẹ̀ èrò tuntun kan yọ, yálà òun ni kókó ọ̀rọ̀ tàbí pé ó kàn tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí a gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀. Ó sì tún lè pàfiyèsí sí ìparí àlàyé ọ̀rọ̀. (3) Olùbánisọ̀rọ̀ lè lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ láti fi sọ bí ọ̀rọ̀ kan ṣe rí lára òun. (4) A tún lè lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ láti fi gbé àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ kan yọ.

Kí olùbánisọ̀rọ̀ tàbí ẹnì kan tí ń kàwé sétígbọ̀ọ́ àwùjọ tó lè lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ní àwọn ọ̀nà tí a sọ yìí, ọ̀rọ̀ tó ń sọ ní láti yé e yékéyéké, kí ó sì fẹ́ pé kí ọ̀rọ̀ ọ̀hún wọ àwọn olùgbọ́ òun lọ́kàn ṣinṣin. Nehemáyà 8:8 sọ̀rọ̀ nípa ìtọ́ni táwọn èèyàn gbà nígbà ayé Ẹ́sírà pé: “Wọ́n sì ń bá a lọ láti ka ìwé náà sókè, láti inú òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń làdí rẹ̀, wọ́n sì ń fi ìtumọ̀ sí i; wọ́n sì ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.” Ó hàn gbangba pé àwọn tó ka Òfin Ọlọ́run tí wọ́n sì ṣàlàyé rẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn ún, mọ bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti mú kí ìtumọ̀ ohun tí àwọn kà yé àwọn olùgbọ́ àwọn, kí wọ́n rántí, kí wọ́n sì fi í sílò.

Ohun Tó Lè Fa Ìṣòro. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló jẹ́ pé nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn ojoojúmọ́, wọ́n máa ń mú kí ohun tí àwọn ní lọ́kàn yéni kedere. Àmọ́ tí wọ́n bá ń ka ọ̀rọ̀ tí ẹlòmíràn kọ, á di ìṣòro fún wọn láti mọ ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kí wọ́n tẹnu mọ́. Ojútùú rẹ̀ ni pé kí èèyàn ti lóye ọ̀rọ̀ inú ìwé náà kedere. Ìyẹn gba fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ inú ìwé yẹn dáadáa. Nípa bẹ́ẹ̀, bí a bá yàn ọ́ láti ka ìwé ní ìpàdé ìjọ, ńṣe ni kí o múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa.

Àwọn kan máa ń ṣe ohun tí a lè pè ní “títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ lóòrèkóòrè” dípò títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ tó yẹ. Bí wọ́n bá ti kàwé lọ sàà, wọ́n á kàn tún wá ọ̀rọ̀ kan tẹnu mọ́, yálà ìtẹnumọ́ yẹn nítumọ̀ o tàbí kò ní. Àwọn mìíràn a kàn máa tẹnu mọ́ àwọn ìsọ̀ǹgbè ọ̀rọ̀ lọ ni ní tiwọn, bóyá kí wọ́n máa tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ atọ́kùn tàbí ọ̀rọ̀ aso-ọ̀rọ̀-pọ̀ lọ́nà tó pọ̀ jù. Bí títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ kò bá túbọ̀ mú kí ọ̀rọ̀ wa ṣe kedere sí i, kì í pẹ́ tí yóò fi dà bí àṣà lásán tí yóò sì máa gbàfiyèsí àwùjọ.

Gbígbìyànjú láti lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ máa ń mú kí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan máa túbọ̀ gbóhùn sókè débi tá fi mú kí àwùjọ rò pé ńṣe ni olùbánisọ̀rọ̀ ń jágbe mọ́ àwọn. Ká sòótọ́, ìyẹn náà kò fi bẹ́ẹ̀ dára. Bí ọ̀nà tí olùbánisọ̀rọ̀ gbà ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ kò bá bá ọ̀nà tó ń gbà sọ̀rọ̀ mu, yóò jẹ́ kó dà bíi pé kò ka àwọn olùgbọ́ rẹ̀ kún. Ohun tó ti dùn ni pé kéèyàn kàn fi ìfẹ́ rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ kí ó sì mú kí wọ́n rí i pé, yàtọ̀ sí pé ohun tí òun ń wí bá Ìwé Mímọ́ mu, ó tún bọ́gbọ́n mu pẹ̀lú!

Bí O Ṣe Lè Ṣàtúnṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tó níṣòro nínú títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ kì í mọ̀ pé òun ní in. Ẹlòmíràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá sọ fún un. Bó bá di pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe lórí èyí, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe é. Ẹ̀wẹ̀, má tijú láti sọ pé kí olùbánisọ̀rọ̀ mìíràn tó gbó ṣáṣá ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú. Ní kí ó fara balẹ̀ fetí sí bí o ṣe ń kàwé àti bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ kí ó sì wá dábàá àwọn ohun tí o lè ṣe láti tẹ̀ síwájú sí i.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ pàá, ẹni tó ń fún ọ nímọ̀ràn lè dábàá pé àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ ni kí o lò fún ìdánrawò. Ó dájú pé yóò sọ pé kí o ṣàyẹ̀wò gbólóhùn kọ̀ọ̀kan tó wà níbẹ̀ láti fi mọ ọ̀rọ̀ àti àpólà ọ̀rọ̀ tó yẹ kí o tẹnu mọ́ kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ibẹ̀ lè tètè yéni. Ó lè rán ọ létí pé kí o fún àwọn ọ̀rọ̀ kan tí a fi lẹ́tà wínníwínní kọ ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Rántí pé ńṣe lọ̀rọ̀ inú gbólóhùn máa ń so pọ̀ mọ́ra. Dípò kí á máa dá ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tẹnu mọ́ nínú gbólóhùn, ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ló sábà máa ń gba ìtẹnumọ́. Nínú èdè Yorùbá àti nínú àwọn èdè kan, a lè gba akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé kó kíyè sí àmì orí ọ̀rọ̀ àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀ dáadáa láti fi mọ ọ̀nà tó yẹ kó gbà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀.

Nínú ìgbésẹ̀ tó kàn, olùgbani-nímọ̀ràn lè sọ pé kí o gbé àlàyé ọ̀rọ̀ tó gùn ju gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo yẹ̀ wò láti lè mọ ọ̀rọ̀ tó yẹ ká tẹnu mọ́. Kókó pàtàkì wo ni ìpínrọ̀ yẹn lódindi dá lé lórí? Báwo ló ṣe yẹ kí ìyẹn nípa lórí ohun tó o máa tẹnu mọ́ nínú gbólóhùn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tó wà níbẹ̀? Wo ẹṣin ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ yẹn àti àkòrí ọ̀rọ̀ kékeré tó wà lókè ibi tí ò ń gbé yẹ̀ wò. Báwo ni ìwọ̀nyẹn ṣe kan àwọn gbólóhùn tí o yàn láti tẹnu mọ́? Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ kókó tó yẹ kó o gbé yẹ̀ wò. Ṣùgbọ́n gbìyànjú láti má ṣe fi agbára tẹnu mọ́ iye ọ̀rọ̀ tó pọ̀ jù.

Yálà o máa sọ̀rọ̀ fàlàlà láìgbáralé àkọsílẹ̀ ni o tàbí ìwé lo fẹ́ kà, ó ṣeé ṣe kí ẹni tó ń fún ọ nímọ̀ràn sọ fún ọ pé kó o jẹ́ kí àlàyé ọ̀rọ̀ tó o máa ṣe lórí ibi tó o fẹ́ kà nípa lórí ọ̀nà tó o máa gbà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀. Ó yẹ kí o mọ ibi tí àlàyé ọ̀rọ̀ kan ti parí tàbí ibi tí ọ̀rọ̀ ti kúrò lórí kókó pàtàkì kan bọ́ sórí òmíràn. Yóò dùn mọ́ àwùjọ tí o bá pe àfiyèsí wọn sí irú àwọn ibi bẹ́ẹ̀. A lè ṣe èyí nípa títẹnumọ́ àwọn ọ̀rọ̀ bíi lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà, paríparì ọ̀rọ̀ yìí ni pé, nípa báyìí àti ní tòótọ́.

Ẹni tó ń fún ọ nímọ̀ràn yóò tún pe àfiyèsí rẹ sí àwọn ibi tó yẹ kó o ti fi bí ọ̀rọ̀ ṣe káni lára sí hàn. Láti lè ṣe èyí o lè tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ bíi, gidigidi, gan-an, pátápátá, rárá, gbọ́dọ̀, ní pàtàkì àti léraléra. Bí o bá tẹnu mọ́ wọn bẹ́ẹ̀, yóò nípa lórí ìhà tí àwọn olùgbọ́ rẹ yóò kọ sí ohun tí ò ń bá wọn sọ. A óò túbọ̀ sọ̀rọ̀ nípa èyí nínú Ẹ̀kọ́ 11, “Ohùn Tó Tura àti Ohùn Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára.”

Láti mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ túbọ̀ dán mọ́rán, a óò tún gbà ọ́ níyànjú pé kí o jẹ́ kí àwọn kókó pàtàkì tó ò ń fẹ́ kí àwùjọ rántí ṣe kedere lọ́kàn rẹ. A óò máa fún èyí ní àfiyèsí síwájú sí i nígbà tí a bá dórí bí ànímọ́ yìí ṣe kan ìwé kíkà sétígbọ̀ọ́ àwùjọ nínú Ẹ̀kọ́ 7, “Títẹnumọ́ Àwọn Kókó Pàtàkì,” àti bí ó ṣe kan ọ̀rọ̀ sísọ nínú Ẹ̀kọ́ 37, “Mú Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere.”

Tó bá jẹ́ pé ńṣe lò ń gbìyànjú láti rí i pé o túbọ̀ ń ṣe dáadáa sí i lóde ẹ̀rí, ńṣe ni kí o fún ọ̀nà tó o gbà ń ka Ìwé Mímọ́ ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Jẹ́ kó mọ́ ọ lára láti máa bi ara rẹ léèrè pé, ‘Kí nìdí tí mo fi ń ka ẹsẹ yìí ná?’ Bí ẹni tó ń kọ́ni bá kàn ń pe ọ̀rọ̀ ibẹ̀ jáde lẹ́nu bó ṣe tọ́, ìyẹn nìkan kò tó. Kódà, bí ó bá ń fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára hàn nínú ìwé kíkà rẹ̀ pàápàá, ìyẹn lè máa tíì tó. Bí o bá ń dáhùn ìbéèrè ẹnì kan tàbí tí ò ń kọ́ni ní òtítọ́ pàtàkì kan, ó dára kí o tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ tó ti ohun tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lé lórí lẹ́yìn. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kókó ọ̀rọ̀ yẹn lè má hàn sí ẹni tí ò ń kàwé sí létí.

Níwọ̀n bí ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ti wé mọ́ kí èèyàn tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àti àpólà ọ̀rọ̀ kan, ẹni tí kò ì pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ lè wá bẹ̀rẹ̀ sí tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àti àpólà ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn jù. Yóò wá rí bí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bí a ṣe ń lo ohun èlò orin tó jẹ́ pé á kọ́kọ́ máa fi agbára tẹ̀ ẹ́. Àmọ́, bí ó ti ń fi dánra wò léraléra, “okùn orin” kọ̀ọ̀kan tó bá wá ń tẹ̀ á di apá kan “orin adùnyùngbà” tó ń gbé ìtumọ̀ tó wúni lórí yọ.

Bí o bá ti wá mọ àwọn kókó pàtàkì bíi mélòó kan, wàá lè jàǹfààní látinú ṣíṣàkíyèsí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tó ti pẹ́ lẹ́nu ọ̀rọ̀ sísọ. Kò ní pẹ́ tí wàá fi rí bí títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ní onírúurú ìwọ̀n tó yàtọ̀ síra ṣe wúlò gan-an. Wàá sì tún wá rí bí ó ṣe wúlò tó láti lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà láti fi mú kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ṣe kedere. Dídi ẹni tó mọ bí a ṣe ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ yóò tún mú kí bí o ṣe ń kàwé àti bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ túbọ̀ múná dóko.

Má ṣe fi kíkọ́ ìlò ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ mọ sí kìkì ìwọ̀nba ohun mélòó kan tó ṣáà ti ṣe pàtàkì. Láti lè sọ̀rọ̀ lọ́nà to mọ́yán lórí, máa bá a nìṣó láti ṣiṣẹ́ lé e lórí títí wàá fi mọ bí a ṣe ń lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ dáadáa, débi pé bí o ṣe ń lò ó á máa dùn mọ́ àwọn èèyàn létí.

BÍ O ṢE LÈ DI ẸNI TÓ MỌ̀ Ọ́N LÒ

  • Máa fi bí a ṣe ń dá ọ̀rọ̀ tàbí ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó nínú gbólóhùn mọ̀ kọ́ra. Fara balẹ̀ kíyè sí bí a ṣe ń fi àlàyé tí à ń bá bọ̀ dá àwọn ọ̀rọ̀ náà mọ̀.

  • Gbìyànjú láti lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ láti fi hàn pé (1) o ti kúrò lórí kókó kan bọ́ sórí kókó mìíràn àti (2) bí ohun tí ò ń sọ ṣe ká ọ lára sí.

  • Nígbà tó o bá ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́, jẹ́ kó mọ́ ọ lára láti máa tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tó ṣètìlẹ́yìn fún ìdí tó o fi ń ka ẹsẹ yẹn.

ÌDÁNRAWÒ: (1) Yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjì tó o máa ń lò dáadáa lóde ẹ̀rí. Yan ohun tí ò ń gbìyànjú láti fi ẹsẹ kọ̀ọ̀kan yẹn ṣàlàyé. Ka ẹsẹ wọ̀nyẹn sókè lọ́nà tí wàá fi tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tàbí ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ tó ti kókó wọ̀nyẹn lẹ́yìn. (2) Ṣàyẹ̀wò Hébérù 1:1-14, dáadáa. Kí nìdí tó fi yẹ láti tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ bí “àwọn wòlíì” (Héb 1 ẹsẹ 1), “Ọmọ” (Héb 1 ẹsẹ 2) àti “àwọn áńgẹ́lì” (Héb 1 ẹsẹ 4, 5) lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ láti lè gbé ohun tí orí yìí ń ṣàlàyé yọ lọ́nà tó ṣe kedere? Ṣe ìdánrawò nípa kíka orí yẹn sókè kí o sì lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ tí yóò gbé ohun tí ibẹ̀ ń ṣàlàyé jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́